Ìlú kan gógó, 
Ilu òf'ara rọ
Àwọn ará ìlú gaan ò rẹ́ẹ̀rín. 

Àṣe k'árówóná òdàbí k'álówó nílé
k'álówó nílé gan-an òdàbí k’álówó lápò
k’álówó lápò gan-an yàtọ̀sí ká lówó lọ́wọ́. 


Ìlú kan gógó, 
Ilu òf'ara rọ
Àwọn ilé ìfowópamọ́ kọ̀ọ̀ wọn ò gb’ówó jáde
Ara ń ni àwọn ọmọ Naijiria. 

Wọ́ní orúkọ ọmọ ló ń r'ọmọ 
Wípé orúkọ sìni ìjánu ọmọ
Àbí orúkọ ló ń rùn lára wani
Nítoríwípé ojoojúmọ́ ni à ń jírííyà? 

Ọdún tókọjá, ìpè la ò rípè. 
Àwọn oní iléeṣẹ́ síìmù 
Yarí gbégi dínà ìpè e wa; 
Wọ́ní kátún ètò síìmù waa ṣe, 
K'ápadà sí ẹṣẹ àárọ̀. 

Ajínigbé ti báwa fínra rí (wọ́n sì ń báwa fínra) 
Bẹ́ẹ̀ sìni awọn jàǹdùkú ti báwa lògbà ríí (wọn ò tíìdẹ́kun)
Ìjọba ti fi ìgbàkan ń paa àwọn ará ìlúu rẹ̀ rí 
Bí adì'ẹ  sàárà
Nítoríwípé wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn 
Pé kí wọ́n fi òpin sí ẹgbẹ́ Sáàsì.

Èwo la ò tíì rírí? 
Aburú wo la ò tíì làkọjárí ní Orílèdè yìí? 
Ṣùgbọ́n tọ̀tẹ̀yí kàsíàrà…
Owó la ò ríná! 

Éèpà! 

Wọ́n ní káṣiṣẹ́, aṣiṣẹ́, 
Wọ́n ní káwówó, awówó
Èwo tún là’í r'ówógbà ní báǹkì? 

Ní ọjọ́ tí mo lọ sí ilé ìfowópamọ́ kan tó sún mọ́ mi, 
Ẹ̀rúbàmí nígbà tí mo rí èrò tótò lọ bí omi. 

Títì ò tó fífà, fífà ò tó títì 
Ẹwá wo érò lọ́ọ̀tún lóòsì 
Bí wọ́n ṣe ń ja ìjà àjàkú akátá 
Láti wọlé lọ gba owó tí wọ́n ṣiṣẹ́fún. 

Ẹẹ́gbọ̀ọ́, ìlú ń ṣẹ̀jẹ̀
Agara owó ń dá àwọn ọmọ Naijiria 

Ǹjẹ́ èto káṣílẹ́sí pọlisì yìí maa ṣiṣẹ́ ṣá? 

Ọlọ́jà òr'ọ́jàtà
Olùrajà o r'ówó ná
Olúkálukú w'ara ro ni. 

Kàkà kí óṣàn lára ọmọ àjẹ́ Naijiria 
Ń ṣe ló ń fi gbogbo ọmọ bí obìnrin; 
Kàkà kí ódẹ̀ fún wa, ń ṣe ló ń fi ojoojúmọ́ le 
Koko bi ojú ẹja. 

Abẹ ìjọba wa kí wọ́n báwa dẹ̀ẹ́ díẹ̀
Ń torí okùn èmí waa ti fẹ jáá. 

Ẹṣàánú àwa ọmọ mẹ̀kúnù, 
Ìyà yí pọ̀ọ̀, ó pọ̀! 

Nípa Ònkọ̀wé

Akíntọ́lá Ismail jẹ́ ọmọ bíbí ìlú ifón ní ìpínlè Òṣun.Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ède Gẹ̀ẹ́sì ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Ìbàdàn ti ìlú Ìbàdàn. Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *