ÀTẸ́LẸWỌ́ jẹ́ ẹgbẹ́ tí a gbé kalẹ̀ láti fi ìmúṣẹ ba àwọn àfojúsùn wọ̀n yìí:

  • Láti pèṣè ibi tí àwọn akẹ́kọ̀ ati ọ̀dọ́ leé máa kopa pẹlú oríṣiríṣi ẹya aṣa àti ìṣe Yorùbá látàrí ìdíje, ẹ ̀kọ́, ìfọ̀rọ̀jomítoro ọ̀rọ̀ ati ṣi ṣe ìpàdé déédé.
  • Láti ṣe àgbékalẹ̀ ibi tí a ti má ṣe àkọsílẹ̀ ati ìpamọ òye àṣà Yorùbá ìgbà àtẹ̀yìnwá àti láti máá lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè àṣà wa.
  • Tí ta àwọn èyàn jí sí ìfẹ́ lítíreṣọ̀ Yorùbá latàrí ṣiṣe ètò ìwé kíkà, jíjẹ kí ìwé lítíreṣọ̀ Yorùbá wà nlẹ̀ fún tità àti ṣíṣe àtẹ̀jade àwọn oǹkọ̀wé titun ní èdè Yorùbá.

Ní pàápàá jù lọ lórí àfojúsùn kẹta yìí ni a ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ètò Ẹgbé Òǹkàwé Yorùbá nibi tí a tí n yá àwọn èèyàn ní ìwé ti a sì ti máa ń ṣe àpérò lóri àwọn ìwé lítírésọ̀ Yorùbá.

Ìgbà tí ààrùn kó-nílé-gbé-lé Kòrónà (Covid-19) gbà ‘lú kan ni a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ètò ìwé kíkà náà ni orí afẹ́fẹ́ (Zoom). A bẹ̀rẹ̀ ni Oṣù Kárùn-ún ọdun 2020. Tí ẹ bá wo Ìsàlẹ̀, ẹ ó rí àwọn ìwé tí a ti kà àti àwọn ti a ó kà. Ni Oṣù kẹwàá ọdun 2021 ni a gbe èto náà lọ sí orí TWITTER SPACE.

Ètò náà wáyé ni ẹ̀mejì l’ọ́sẹ̀: Ọjọ́ Ẹtì (agogo márùn-ún ìrọ̀lẹ́) àti Ọjọ Ìsinmi ( agogo márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ) lórí Twitter – https://www.twitter.com/egbeatelewo.

Tí ẹ bá ní ìbèérè, tàbí ìránnilétí, ẹ kàn sí egbeatelewo@gmail.com tàbí kí ẹ ké sí wa lóri ẹ̀rọ WhatsApp

ÀTÚPALẸ̀ ÌWÉ TÍ A TI KÀ ÀTI ÀWỌN TÍ A YÓÒ KA

Oṣù Ìwé
Ẹ̀bìbí (May)   Ìrìnkèrindò Nínú Igbó Elégbèje (D.O Fagunwa)
Ẹ̀bìbí (May)  Àgbákò Ni’le Tẹ́tẹ́ (Kọ́lá Akinlàdé)
Okúdù (June)  Ó le kú (Akínwùmí Ìṣọ̀lá)
Okúdù (June)  Ìrèké Oníbùdó (D.O Fagunwa)
Agẹmọ (July)  Ṣaworoidẹ (Akinwumi Isola)
Agẹmọ (July)  Eégún Aláré (Láwuyi Ògúnniran)
Ògún (August)  Àja Ló Lẹrù (Oladejo Okediji)
Ògún (August)  Ẹni Ọlọ́run Ò pa (Olu Owolabi)
Ọ̀wẹ̀wẹ́ (September)  Ogún Ọmọdé (Akinwumi Isola)
Ọ̀wàrà (October)  Àtàrí Àjànàkú (Lawuyi Ogunniran)
Bélú (November)  Báyọ̀ Ajọ́mọgbé (J. Akin Ọmọ́yájowó)
Ọ̀pẹ́ (December)  Ọ̀rẹ́ Méjì (Afolabi Olabimtan)
Ṣẹẹrẹ (January) 2021  Fàbú (Akínwùmí Ìṣọ̀lá)
Èrèlé (February) 2021  Ẹfúnṣetán Aníwúrà (Akinwumi Isola)
Erénà (March) 2021  Ta L’olè Ajọ́mọgbé (Kola Akinlade)
Igbe (April) 2021  Líṣàbi Agbòǹgbò-Àkàlà (E.O Owolabi)
Ẹ̀bìbí (May) 2021  Alòsì Ọlọ̀gọ (Kọ́lá Akínlàdé)
Okúdù (June) 2021  Olówólayémọ̀ (Fẹ́mi Jẹ́bọdà)
Agẹmọ (July) 2021  Olówólayémọ̀ (Fẹ́mi Jẹ́bọdà)
Ògún (August) 2021    Ogun Àwítẹ́lẹ̀ (Adebayo Faleti)
Ọ̀wẹ̀wẹ́ (September) 2021  Ogbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀ (D.O Fagunwa)
Ọ̀wàrà (October) 2021 Ó le kú (Akínwùmí Ìṣọ̀lá)
Bélú (November) 2021  Ibú Olókun (J.O. Ogundele)
Ọ̀pẹ́ (December) 2021  Baṣọ̀run Gáà (Adebayo Faleti)

̀