ÀT́LẂ: ÌṢÍ’ṢO L’ÓJÚ EÉGÚN

Ní oṣù tí o kọjá, mo gbe àtẹ̀jáde kan sí orí abala Fésìbúùkù mi níbi, nípa bí o ṣe yẹ láti polongo èdè Yorùbá gẹ́gẹ́ bi àkójọpọ̀ aṣa ati iṣe olówó iyebíye láàrin àwọn Yorùbá. Yàtọ̀ sí ti àwọn àgbàlagbà, a fẹ́ kọjú sí àwọn ti o ṣẹ́ṣẹ̀ ń dìde, àwọn ti o n bọ̀ lẹ́yìn, àwọn akẹ́kọ́, àwọn ọmọ wa ti o ṣòro fún láti ka oríkì wọn, àwọn ọmọ wa tí o ṣe pe típa tì kúùkù ni wọ́n fi ń sọ èdè abínibí wọn, àwọn ọmọ wa ti wọn kò mọ ìtan ìlú wọ́n bi wọn sí, àwọn ọmọ wa tí wọn kò ni akitiyan òun agbára láti ka ìtàn àròkọ́, àwọn ọmọ wa ti wọn ń jà fita-fita lati gbe aṣọ Yorùbá larugẹ ní ibi tí o jẹ́ pé aṣọ àwọn alawọ̀ funfun (suit) ni o gbàlẹ̀ kàn-àn, àwọn ọmọ wa ti ìtìjú bò nipa ijákulẹ̀ wọn nínú dí’dagá n jia láti mọ̀ si nipa èdè wọn.

Mo ránti pe àtẹ̀jáde mi gba ọrọ ìwúnilori láti ọdọ àwọn olùkáràmáisìkí Yorùbá ni’le l’oko àti lẹyìn odi. Wayi, iṣẹ́ ti wa bẹrẹ̀, tábìlì náà ti wà ní títúntò. Èmi àti àwọn olùfilekàn/olùfẹràn aṣíwajú èdè Yorùbá pàdé láti f’ọ̀rọ̀jomítoro ọ̀rọ̀ nipa àwọn nǹkan ti o ni ṣe bi a ó ṣe mú iṣẹ́ yìí wá sí ìmúṣẹ, bí a o ṣe tan ìyìnrere àwọn ìṣe àti àṣà wa ré kọjá àwọn oun ìdinà, kọjá ojúde èdè àwọn aláwọ̀ òyìnbó akónilẹ́rú.

Lẹyìn ìpàdé lọ́pọ̀lọpọ̀ ati ìfọrọwérọ̀, à gbà lati gbe ÀTẸ́LẸWỌ́ síta, yío si maa jẹ́ ẹgbẹ́ tí ò wà láti gbé Yorùbá dìde àti láti tún iṣẹ́ Yorùbá tò.

A tún f’ẹnukò pé àwọn ohún a fẹ́ ṣe nìwònyí:

  • Láti pèṣè ibi tí àwn aḱk̀ ati ̀d́ leé máa kopa plú oríṣiríṣi ya aṣa àti ìṣe Yorùbá látàrí ìdíje, ̀ḱ, ìf̀r̀jomítoro ̀r̀ ati ṣi ṣe ìpàdé déédé.

 

  • Láti ṣe àgbékal̀ ibi tí a ti má ṣe àksíl̀ ati ìpam òye àṣà Yorùbá ìgbà àt̀yìnwá àti láti máá lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè àṣà wa.

 

  • Tí ta àwn èyàn jí sí ìf́ lítíreṣ̀ Yorùbá latàrí ṣiṣe ètò ìwé kíkà, jíj kí ìwé lítíreṣ̀ Yorùbá wà nl̀ fún tità àti ṣíṣe àt̀jade àwn oǹk̀wé titun ní èdè Yorùbá.

A mọ̀ pe iṣẹ́ yìí, iṣẹ́ takuntakun ni. Ṣùgbọ́n a ti ṣetán lati gbìyànjú ẹ̀ wo pẹ̀lu agbára wa. Gẹ́gẹ́ bi awọn Yorùbá ṣe má ń sọ pé bí a ò bá lọ, a kìí de, àtipe dan wò l’o bi ìyá Ọ̀kẹrẹ́. Níbayii, atiṣetán láti ṣe ojúṣe wa fún àṣà a wa.

Ṣùgbọ́n o hàn dajú pe awa nìkan kòle da’ṣe, àtipe ìdí nìyí tí a ó fi maa gbọ́nkànle ìrànlọwọ yín. Lápapọ̀, a rí ìdánilójú pé à lè gbé Yorùbá dide àti pe a lè tún ogún wa tò.

Ẹ má gbàgbè lati tẹ̀le wa ni ori gbàgede ayárabíàsá ti Facebook – www.fb.me/egbeatelewo àti Twitter – @egbeatelweo

Ẹ fi ojú s’ọ́nà bi a ṣe n mú ẹyẹ bọ̀ la pò.

Adúpẹ.

Rasaq Malik Gbọ́láhàn,

Ìbàdàn.