Ẹ kú u dédé àsìkò yìí o ẹ̀yin òǹkàwé wa, a sì kú ọdún tuntun. Ọdún ayọ̀ ni yóò jẹ́ fún wa, ọ̀pọ̀ ọdún la ó sì ṣe láyé o. Èyí ni láti jẹ́ kí ẹ mọ àwọn iṣẹ́ tí a gbé jáde fún oṣù tí ó gbẹ̀yìn ọdún tó kọjá.

Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ náà ni Ó Di Pẹ́ Ǹ Túká láti ọwọ́ Ọláyàtọ̀ Ọláolúwa, ìtàn-àròsọ ni iṣẹ́ yìí, pàtàkì iṣẹ́ yìí àti ohun tí òǹkọ̀wé kọ sí ọmọ aráyé ni pé ilẹ̀ dídà a mọ́ọ pa iná ìfẹ́ tí ń jò láàárin ọ̀rẹ́, ará àti ẹbí. Gẹ́gẹ́ bí Moss ṣe dalẹ̀ Moss tí í ṣe ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀.

A tún gbé iṣẹ́ eléyìí náà jáde, Àlàmú Olókùn láti ọwọ́ Ọláyàtọ̀ Ọláolúwa, ìtàn-àhesọ tí ó rọ̀mọ́ ohun tó ṣ’okùnfa ibùgbé tí àwọn ẹranko bíi alátànkùn, ọ̀bọ àti ẹkùn ń gbé lónìí. Àkàgbádùn ni ìtàn náà, ó sì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́.

Bákan náà ni a tún gbé iṣẹ́ ògbufọ̀ kan jáde; On Death ti John Keats, tí Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé Lawrence túmọ̀ láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí Ọ̀rọ̀ Nípa Ikú.

Iṣẹ́ mìíràn tí a tún gbé jáde ni ewì àpilẹ̀kọ Ẹ Fẹ̀yí Kọ́gbọ́n Láti ọwọ́ Bákàrè Táíwò. Akéwì akọ̀wé ń kọ sí wa kí á má ṣe bínú orí, àtunbọ̀tán abínú-ẹni kìí dára, ẹ̀ bá jíá ronú ká simẹ̀dọ̀.

A tún gbé iṣẹ́ ògbufọ̀ mìíràn jáde; On Grasshopper and Cricket ti John Keats, tí Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé Lawrence túmọ̀ láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí Tata àti Ìrẹ̀: Ẹranko Olóhùn Tó Bá Ìgbà Mu.

Iṣẹ́ àpilẹ̀kọ mìíràn tí ó jẹmọ́ ewì tí a  tún gbé jáde ni Oore Ló Pé láti ọwọ́ Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé Lawrence, akéwì ń kọ sí àwùjọ nípa ìhà àti ojú tí ó fi wo Oore gẹ́gẹ́ bí ìṣe tí ó yẹ gbogbo mùtúnmùwà.

Ìwọ náà mú gègé è rẹ kí o ṣiṣẹ́ àtinúdá láti kọ oyún ọ̀rọ̀ tí o ní síkùn jáde fáráyé kà, láti jẹ ìgbádùn iṣẹ́ àtinúdá náà,  kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti kọ́gbọ́n nínú u rẹ̀. Àwọn irúfẹ́ iṣẹ́ tí à ń gbà wọlé ni: ewì, eré-onítàn, ìtàn-àròsọ, aáyan ògbufọ̀, iṣẹ́ ìwádìí, àwòrán. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, ẹ le kàn sí www.atelewo.org/igbawole

Fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bá fẹ́ fi iṣẹ́ yín ṣowọ́ sí Àtẹ́lẹwọ́, ẹ fi iṣẹ́ yín ránṣẹ́ sí méélì wa ní atelewo.org.@gmail.com

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *