Oore Ló Pé

Oore ló pé
Ẹ jẹ́ á ṣoore
Ìkà ò pé
Gbogbo Mùtúnmùwà!
Bó o bá ṣe é ree
Wà á kẹ́san
À’tore à’tìkà
Méjèèjì l’ẹ̀sán ń bẹ fún
Dúró ná ọ̀rẹ́, 
Emi la fẹ́ sọ nípa à rẹ bóo bá lọ tán?
Ṣèrántí wí pé aríṣe laríkà, 
Aríkà ni baba ìrègún. 
Ìwọ ò gbọdọ̀ jùmí, 
Èmi ò gbọdọ̀ jù ọ́, 
Ọ̀rẹ́minú rẹ o yà á ní wèrè. 
Ìyá tó jìyà tó jìṣẹ́, 
Ẹ fi ṣẹ́gi ọlà, 
Ìkà á ko níkà bó bá yá, 
Ọlọ́run àtijọ́ níí pẹ́ ko tó mú ni. 
Ṣore ṣore!
Ìwọ ṣá màa ṣore lọ
Ènìyàn le è ṣoore gan
k'íbi ó foni dá
Oore ló pé
Ìkà ò sunwọ̀n
Ẹní bá ṣe rere a rí ire mú, 
Ẹní bá sì ṣ'ebi náà kò ní sàì ríbi bó pẹ́ bó yá. 
Màá dáa dúró, kò ní le gòkè, 
Màá b’ògo ayé e rẹ̀ jẹ́,
Kí lo fẹ́ gbà níbẹ̀ gan?
Rántí pé àtunbọ̀tán ìkà ò da
Ìgbẹ̀yìn olubi kìí ṣunwọ̀n rárá. 
Ẹ̀ bá jía gbé ìwà ore ṣíṣe wọ̀ bí ẹ̀wù. 
Oore lópé, 
Ìkà ò dára. 

Ọ̀rọ̀ Nípa Òǹkọ̀wé:

Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a bí ní ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.

Àwòrán Ojú ìwé yìí jẹ́ ti Economic times image https://m.economictimes.com/wealth/plan/four-ways-you-can-help-poor-people-around-you-with-financial-planning/articleshow/69278206.cms

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *