Àlàmú Olókùn

Ọ̀kan lára awọn ẹranko tí ó kéré jùlọ ni Aláǹtakùn (a-lá-rìn-ta-okùn-mọ́lẹ̀), bí ó bá ń rìn, yóò máa ta okùn mọ́lẹ̀, ìdí nìyí tí wọń fi ń pè é ní Olókùn.

Àlàmú Olókùn ni àwọn tí ó bá mọ̀ọ́ délé ń pèé. Bóyá n’torí Àlàmú rẹ̀ ṣènìyàn sí wọn ni wọ́n tún fi n sàá bẹ́ẹ̀. Bí ó bá sá fẹ́rẹ́ fún Olókùn ni ó ma ń gbé inú okùn rẹ̀ lókè àjà, èyí ló fà á tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ẹ̀fọn fi ń pè é ní “ọ̀rẹ́ ẹ̀ mi olókè àjà”.

Ilé tí Olókùn ń gbé pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní káàkiri àgbáyé. Bí ó ti ń gbé lóko ló ń gbé  ní ìlú-ńlá,  pàápàá jùlọ ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà. Kò ní ilé kan pàtó tó ń gbé. Ibi tó bá rí ààyè ta okùn sí ló ń sùn àti pé ilé t’áwọn èèyàn bá kọ́ di tirẹ̀ lọ́nàkọnà láì fónílé ní kọ́bọ̀. Kìí ṣe ayálégbé,  bẹ́ẹ̀ a kò lè sọ pé onílé ni.

Bí ó ti kéré tó yìí, bùrọ̀dá ni àwọn ẹranko bíi Ìdun, Eèrà, àti àwọn báwọ̀nyìí ń pè é. Kìí ṣe pé ó jù wọ́n lọ tààrà, wọ́n kàn ń fọ̀wọ̀ tirẹ̀ wọ̀ọ́ ni, kékeré labẹ́rẹ́ kéré, kìí ṣe mímì f’Ádìyẹ!

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló maá ń sọ ìtàn Àlàmú Olókùn f’ọ́ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀, ọmọ àti ọmọ-ọmọ láti ìgbà-dé- ìgbà tókìkǐ rẹ̀ sì ń kàn.

Bó bá d’àṣalẹ́, ìtàn Olókùn l’àwọn ọmọdé maá ń jẹ lẹ́nu bí ẹni jẹran lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n bá kóra jọ. Lẹ́yìn èyí, oníkálùkù á gbọ̀nà ilé rẹ̀ lọ. Bó bá d’ọjọ́ kejì tí wọ́n fojú gáání Aláǹtakùn, wọ́n mọ̀ pé Àlàmú Olókùn ni. Wọ́n á fi sílẹ̀ sáàyè tirẹ̀ àmọ́ àwọn tí kò fẹ́ràn rẹ̀ á ma fi ìgbálẹ̀ dá sèríà fún-un.

ÌJÀ LÓDÉ. . .

Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Ẹkùn, Olókùn àti Ọ̀bọ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Wọ́n jọ ń ṣohun gbogbo pọ̀, àárín wọn sì gún régé. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dáwó ra ilẹ̀ sí ìsàlẹ̀ odò ìlú láti fi lè dáko. Ní àrààárọ̀ àti kété tí wọ́n bá ti jí, wọ́n á ma dẹ́rìn-ín pẹ̀ẹ̀kẹ́ lura wọn lọ́nà títí wọn yóò fi débẹ̀  láti ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olókùn ló kéré jù nínú wọn, síbẹ̀, bí wọ́n bá ń lọ, òun ni ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́, òun náà ló maá ń ru àpótí oúnjẹ tí wọn yóò jẹ lọ́sàn-án ọjọ́ náà. Kìí ṣe pé ó kéré jù ló fi ń gbe, bíkòṣepé ó mú oúnjẹ lọ́kùkúdùn àti pé àlùwàlá ológbò rẹ̀, ọgbọ́n àti kẹ́ran jẹ ni.

Wọ́n dé oko wọn, iṣẹ́ yá! Bíṣẹ́ ò bá pẹ́ni, ẹnìkan í kúkú pẹ́ṣẹ́. Olúkúlùkù ti ń múṣẹ́ ṣe. Ẹkùn àt’Ọ̀bọ ló jọ ń ṣiṣẹ́ síra. Olókùn ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣùgbọ́n kò ṣiṣẹ́ tó àwọn tó kù, ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré ló lò. Ìdí abẹ́ igi Máńgòrò ló lọ lúgọ̌ sí tí ń kọrin ‘mi ò lè wá kú, mi ò lè parà mi’. Ó ní òun á ma ṣọ́ àpótí oúnjẹ kí Àǹtí Ajá mâ ba gbe panu.

Ẹ̀kùn àti Ọ̀bọ ṣíwọ́ iṣẹ́, ó ti rẹ̀ wọ́n dé góńgó, ó hàn lójú wọn púpọ̀. Dídán lojú Olókùn ń dán ní tirẹ̀ bíi dígí, òun ló tún jẹun jù. Ó ní ṣèbí wọń mọ̀ pé Dókíkà ti ní kí òun máa jẹun dáadáa. Bí wọ́n ti jẹun tán, wọ́n gbọ̀nà ilé lọ.

Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà ni wọ́n ń takùrọ̀sọ lóri iṣẹ́ ọ̀la. Wọ́n pinnu láti gbin àgbàdo Faransé sórí oko wọn. Kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú ni wọ́n ti lọ rà á lọ́jà Akùlù.

Lọ́jọ́ kejì, wọ́n lọ gbin àgbàdo náà gẹ́gẹ́ bí ìpinnu wọn. Àrààárọ̀ ni wọ́n lọ maá ń wo bí ohun ọ̀gbìn wọn yìí ti ń dàgbà. Kí wọ́n tó ṣẹ́jú pẹ́, àkókò ìkórè de!

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ wo àgbàdo kí kòkòrò ajẹnirun má ti bòó. Lọ́gán tí wọ́n dé’bẹ̀ ni Olókùn kígbe pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí àkíyèsí kan. Ó ní “ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ ọ̀ ri pé ẹnìkan ti wá ń ṣẹ́ àgbàdo wa lẹ́yìn ni?”.

Òtítọ́ lọ̀rọ̀ náà, olè a-lọ-kólóhun-kígbe kan ti ṣẹ́ apá kan àgbàdo lọ. Inú bí wọn, ọmọ àlè ni yóò rínú tí kò ní bi. Olókùn ló bínú jù, ó fẹ́rẹ̀ lè máa sunkún débi pé Ọ̀bọ funra sí Olókùn lórí ọ̀rọ̀ náà. A kìí nígi lóko ká má mèso orí rẹ̀, mo mọ̀wà ará ilé mi, kìí sèébú lọ̀rọ̀ ọ̀ún rí. Ọ̀bọ bá ara rẹ̀ sọ̀rọ̀ pé ṣé ó lè jẹ́ Olókùn ló p’olè wá jà tó tún p’olóko wá mu?

Ọ̀bọ sọ ohun tó rò lọ́kàn wúyẹ́wúyẹ́ f’Ẹ́kùn, Ẹkùn ṣe bí òun rántí nǹkan, ọ̀rọ̀ náà ti ye nìyẹn. Àwọn méjèèjì pinnu láti ṣọ́ Olókùn lọ́sàn-án lórù-u láti fi ìdí òtítọ́ mulẹ̀

Nígbà tó di aago méjìlá òru, wọ́n kọrí sóko. Kò kúkú sọ́lọ́dẹ tá á mú wọn. Ọ̀bọ gun igi Máńgòrò lórí ẹ̀ka kan, Ẹkùn ní tirẹ̀ ká sẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri lápa òsì. Òṣùpá yọọ gbòò, nitorí na, kedere ni ohun tó bá fẹ́ ṣẹlẹ yóò sí han.

Wákàtí méjì kọjá, ǹnkan kan ò ṣẹlẹ̀, Ẹkùn ti fẹ́ ní kí wọ́n padà sílé n’torí oorun ti kún ojú rẹ̀. Ibi gbogbo dákẹ́ rọ́rọ́ bí ibojì. Bí ó ti di ọwọ́ aago mẹ́ta àbọ̀ ni wọ́n gbọ́ ohun tí ń sọ kúlúkúlú lábẹ́ àgbàdo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri lápá ọ̀tún. Wọ́n fẹ́ ní atẹ́gùn lásán ni ṣùgbọ́n wọ́n tún wòye pé ó háà lè ṣe bí ènìyàn bí?.

Ọ̀bọ wo’bẹ̀ lọ́ọ̀kán, ó hàn kedere p’ọmọ ènìyàn ló wà nídìí orò tí orò fi ń ké. Wọ́n sọ̀kalẹ̀ jẹ́ẹ́ kí ọwọ́ wọ́n lè tẹ olè náà.   Lôtítọ́, ọ̀bọ rọra kúrò lórí igi náà, bí kìí bá ṣe ewé gbígbẹ tó fò sí, wẹ́rẹ́ ni kò bá kó si lọ́wọ́. Olókùn gbúròó ẹsẹ̀, ó fẹsẹ̀ fẹ! Ẹkùn àti Ọ̀bọ gbá yáá tẹ̀le e.

Wọ́n mú fìlà rẹ̀ tó jábọ́. Ó ti wá hàn gbangba gbàǹgbà sí wọn pé Olókùn ni olè ajágbàdo. Kí ni Àlàmú Olókùn rí lọ́bẹ̀ tó fi gààrù ọwọ́?

Bí ó ti kù díẹ̀ kọ́wọ́ Ẹkùn bà á ló dédé pòórá mọ́ wọn lójú. Wọn kò mọ̀ pé ó ti fò sókè, Olókùn bẹ Eṣinṣin kí ó gba òun lọ́wọ́ ikú òjijì. Ó gbe sápá ọ̀tún rẹ̀ ṣùgbọ́n kò pẹ́ rárá tó fi ja lulẹ̀. Ìdí ni pé apá òsì ń dùn-ún, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ dé góńgó.

Bí Ẹkùn àti Ọ̀bọ ti tún rí Olókùn ní ọ̀ọ́kán, wọ́n tún gba tẹ̀le. Ẹkùn ṣèlérí àti pa á bí òun bá lè ri mú fún ìwà ọ̀kánjúà tó hù yí. Ó ti rẹ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún eré àsápajúdé tí wọ́n ń sá.

Olókùn rí Ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ́náà, ó kíi, ó parọ́ fun pé Ẹkùn àti Ọ̀bọ kan fẹ́ rán òun lọ sórun àrèmabọ̀ ni. Nítorí ìdí èyí, àánú ṣe Ọ̀gẹ̀dẹ̀, ó gbà láti da aṣọ àṣírí bo Ẹkùn. Ó fi sínú ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ tó wà lókè téńté, níbi ojú ọlọ́mọ kò ti lè to. Ẹlẹ́yà ni Àlàmú Olókùn ń fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe nínú ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó gbé wà bí ó ti rí wọn tí wọ́n ń sá kíjokíjo kiri bí ìgbà tí Àṣá bá ń lé Adìyẹ.

Bí wọ́n ti ní kí wọ́n yíjú padà ni Ayékòótọ́ kọrin sí wọn létí pé:

     “Inú ọ̀gẹ̀dẹ̀ ló mà wà,

        Inú ọ̀gẹ̀dẹ̀ ló mà wà,

       Ẹ máà tún sáré jìnnà mọ́,

       Inú ọ̀gẹ̀dẹ̀ ló mà wà”.

Ní wàràǹsèsà ni wọ́n gbéra, wọ́n bá Ọ̀gẹ̀dẹ̀ níbi ó ń gb́é ṣeré pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí Olókùn ń sùn fọnfọn ní tirẹ̀.

Ẹkùn ní ‘ìwọ Ọ̀gẹ̀dẹ̀, à ṣé aláìda ni ẹ́, n bí o pé o ò rí Olókùn sójú ni’? Ọ̀gẹ̀dẹ̀ fún Ẹkùn lèsì pẹ̀lú ìbínú, ó ní ‘hẹn, ṣe o wá ri níbí ni, àbí èwo l’ọ̀bọ tó fi ń lọ̀ mí yìí?

Ọ̀bọ sọ̀rọ̀ kúlúkúlú s’Ẹ́kùn létí, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n na tinú-tòde Ọ̀gẹ̀dẹ̀ tòun taṣọ lọ́rùn tó fi fàya. Wọ̀n dè é lókùn kó má baà dí wọn lọ́wọ́ Wọ́n tú ẹ̀ka rẹ̀ yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Ìgbà tó dórí ìparí ni wọ́n tó rí Olókùn he.

Bí wọ́n ti ní kí wọ́n ma yayọ̀ ìṣẹ́gun, kọ́tọ́ ni Olókùn tọ sílẹ̀ tó fẹsẹ̀ fẹ bí olè ajọ́mọgbé. Eré tó ń sá kò tilẹ̀ dà bíi ti tẹ́lẹ̀  nítorí ebi níkùn, àwọn tó fẹ́ mu tún ń le lọ.

Olókùn rí Labalábá lọ́nà. Ó ní ‘háà, ọ̀rẹ́ ẹ̀ mi leléyìí. Gbogbo ènìyàn lọ̀rẹ́ tirẹ̀.  Bí ó ti ń sọ èyí ló ń pe èrò inú àti ọ̀dọ̀fin rẹ̀ pé bí òun bá pe Labalábá láti ràn-án lọ́wọ́, àwọn ará ibí lè rí òun mú.

Tinú tòde Olókùn, ọgbọ́n ni, ó so okùn mọ́ra bi aṣọ ìbora títí tó fi di róbótó. Kò sẹ́ni mọ ‘bi tó ti dédé ri he. Ó ti mọ̀ pé láì pẹ́, láì jìnnà, ọwọ́ pálábá òun á ségi. Nítorí náà, kọ́tọ́ ló kó wọ inú okùn yìí.

Nítorí ìdí èyí ni Olókùn tí a mọ̀ sí Aláǹtakùn fi ń gbé nínú okùn títí di oní kí Ẹkùn àti Ọbọ ma ba pá. Inú okùn ni ò ti ń sẹ ohunkohun tó bá fẹ́ ṣe. Nínà tí wọ́n na Ọ̀gẹ̀dẹ̀ mú kí ó di alákìsísà, yíya laṣọ ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń ya títí di òní kò sì sí aránṣọ tó lè bá a ran.

Ìjà tódé láàrín Olókùn, Ọ̀bọ àti Ẹkùn ló fà á tí Olókùn fi wà nínú okùn títí dòní tó sì fi dá yàtọ̀ sí àwọn ẹranko tó kù. Ọ̀bọ ní tirẹ̀ ní òun yóò máa gbérí igi kí ojú òun ba lè tó ìrìnsí Olókùn títí di òní.

Nípà Òǹkọ̀wé:

Ọláyàtọ Ọláolúwa jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Natural History Museum image.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *