Ẹ̀yin Ònkàwé,
Ẹ kú u dédé àsìkò yìí o ẹ̀yin òǹkàwé wa, a sì kú ìpalẹ̀mọ́ pọ̀pọ̀ṣìnṣìn odún tuntun tó ń bọ̀ lọ́nà. Èyí ni láti jẹ́ kí ẹ mọ àwọn iṣẹ́ tí a gbé jáde lẹ́nu lọ́lọ́ yìí.
Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ náà ni Ọmọ kàyéfì láti ọwọ́ Sheriffden Adeola Ogundipe, pàtàkì iṣẹ́ yìí àti ohun tí òǹkọ̀wé ń kọ sí ọmọ aráyé ni pé àṣesílẹ̀ ni àbọ̀wábá bẹ́ẹ̀ sì ní ìṣẹ́ kìí dédé ṣẹ́.
A tún gbé iṣẹ́ eléyìí jáde, Ọjà Layé àti ewì mìíràn láti ọwọ́ Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé Lawrence. Pàtàki iṣẹ́ náà ni pé, òǹkọ̀wé ń ṣi wa létí láti p’erawa sí àjọ tó ní ìrònú, pé gbogbo ohun tí a bá ṣe láyé kí á máa rántí àtunbọ̀tán àti ẹ̀san. Kí á máa to rí Ẹdẹ b’ẹ̀dẹ̀ jẹ́, ká máa t’orí ohun tí a fẹ́ jẹ́ tàbí jẹ láyé ba ohun tó dára jẹ́, torípé gbogbo wa la ó ò kú lọ́jọ́ kan, bẹ́ẹ̀ gbogbo ohun tí a bá gbeléayé ṣe lónìí ọ̀rọ̀ itàn ni lẹ́yìnwá ọ̀la.
Iṣẹ́ mìíràn tí a tún gbé jáde ni Okùn Ìfẹ́ Yi! Láti ọwọ́ Bákàrè Táíwò. Òǹkọ̀wé fi pàtàkì ìfẹ́ tòótọ́ hàn, ewà àti ayọ̀ tí ń bẹ nínú ìfẹ́ tóòtọ́ láàárín olólùfẹ́ méjì. Bákan náà, nínú àwọn iṣẹ́ mìíran tí a gbé jáde tí ó jẹ́ ti òǹkọwé yìí ni: “Àgbẹ́kẹ̀lé Ènìyàn” akéwì akọ̀wé ń kọ sí wa pé ìgbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lé jàsí asán, ó lè jásí òfo. Ọba elédùà nìkan lótó láti fi ìgbẹkẹ̀lé wa sínú u rẹ̀. “Ìwé Le!” ni tirẹ̀ ni orin ti gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tí kò fẹ́kàn-án ṣe mú bọnu, bẹ́ẹ̀ ìkòkò tó bá máa jata ìdí i rẹ̀ á kọ́kọ́ gbóná. Iṣẹ́ mìíràn tí ó jẹ́ ti Bákàrè Wahab Táíwò ti a tún gbé jáde ni “Àyájọ́ Falẹ!”.
A tún gbé iṣẹ́ àpilẹ̀kọ kan jáde, Òtítọ́ Lérè láti ọwọ́ Ọláyàtọ̀ Ọláolúwa. Pàtàkì iṣẹ́ ti òǹkọ̀wé ń rán sí àwùjọ ni láti máa ṣe òtítọ́ nínú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe láyé. Bámgbọ́pàá tí ó jẹ́ olú-ẹ̀dá ìtàn náà fí òtítọ́ kún ọ̀rọ ọ rẹ̀ èyí sí ì mú kó ṣàṣeyọrí láààrin àwọn ọmọ ìyá a rẹ̀.
Bákan náà ni a tún gbé iṣẹ́ ògbufọ̀ kan jáde; The Child’s Play ti Charles Dickens, eléyìí tí Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé Lawrence túmọ̀ láti ède Gẹ̀ẹ́sì sí Ìtan Arìnrìn-Àjò Kan. Ìtàn yìí jẹ ìtan ìgbésí-ayé okùnrin arìnrìn-àjò kan, láti ìgbà èwe títí di ọjọ́ ogbó. Lówelówe ni ọ̀rọ ìtàn náà. Nínú ìrìn-àjò náà; okùnrin arìnrìn-àjò yìí ṣeré, k’ẹ́kọ̀ọ́, ní ẹbí, ṣiṣẹ́, ó sì ní ọkàn láti farada ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan; pàápàá jùlo àkókò tàbí àwọn ìgbà tí ó pàdánù àwọn olólùfẹ́ ẹ rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ẹ tún le nífẹ̀ẹ́ sí ni Ọdún Ọlọ́jọ́ láti ọwọ́ ọ Olúwáfẹ́mi Ƙẹ́hìndé Lawrence àti Ọlọ́jọ́ Ti Dé eléyìí tí Dunni Adénúgà kọ.
Ìwọ náà mú gègé è rẹ kí o ṣiṣẹ́ àtinúdá láti kọ oyún ọ̀rọ̀ tí o ní síkùn jáde fáráyé kà, láti jẹ ìgbádùn iṣẹ́ àtinúdá náà, kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti kọ́gbọ́n nínú u rẹ̀. Àwọn irúfẹ́ iṣẹ́ tí à ń gbà wọlé ni: ewì, eré-onítàn, ìtàn-àròsọ, aáyan ògbufọ̀, iṣẹ́ ìwádìí, àwòrán. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, ẹ le kàn sí www.atelewo.org/igbawole Fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bá fẹ́ fi iṣẹ́ yín ṣowọ́ sí Àtẹ́lẹwọ́, ẹ fi iṣẹ́ yín ránṣẹ́ sí méélì wa.
Tiyín ní tòótọ́