Ọ̀rọ̀ Nípa Ikú / On Death

Ọ̀rọ̀ Nípa Ikú
I.
Ǹjẹ́ ikú le è jẹ́ orun bí, kí ayé sì jẹ́ àlá?
Kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayọ̀ náà kọja lọ bí ẹ̀mí tó dòkú?
Àwọn ìgbádùn ìgbà díẹ̀ fẹ́rẹ̀ dàbí ìran.
Síbẹ̀síbẹ̀ a rò pé ìrora ńlá jùlọ ni láti kú

II.
Ìyàlẹ́nu ni èyí jẹ́ bí ènìyàn orílẹ̀-ayé ṣe ní láti máa rìn kiri, 
Tí ó sì gbé ìgbé ayé ìbánújẹ́, ṣùgbọ́n tí kò káàárẹ̀
Ipa ọ̀nà rẹ̀ yìí ṣòro, bẹ́ẹ̀ kò le nìkàn rìǹ-ín. 
Ọjọ́ ọ wájú rẹ̀ ti kú ṣùgbọ́n tí ó yẹ kí ó wà láàyè.

On Death

On Death
I.
Can death be sleep, when life is but a dream,
And scenes of bliss pass as a phantom by? 
The transient pleasures as a vision seem, 
And yet we think the greatest pain's to die. 

II.
How strange it is that man on earth should roam,
And lead a life of woe, but not forsake 
His rugged path; nor dare he view alone 
His future doom which is but to awake.

~John Keats (short peom)

Nípa Olùtúmọ̀:

Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a bí ní ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Nigeria Culture art image https://www.google.com/search?q=Nigeria+Culture+image+on+death&client=ms-opera-mini-android&channel=new&sxsrf=ALiCzsbo2wW2zpOUIAb9VWWsMqOmSJJz2w:1671801987171&source=lnms&tbm=isch&sa=X&ved=0ahUKEwjyxdHc64_8AhX2i_0HHaVVCnQQ_AUIBigB&biw=412&bih=658#imgrc=xEbr40oqrifKqM

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *