Ẹ Fèyí Kọ́gbọ́n Mo délé Alárá N ò gbọ́ poroporo odó Mo délé Ajerò N ò gbọ́ kọ̀ǹkọ̀ṣọ̀ ajọ̀ Mo délé Ọwárọ̀gún-àga Bákan náà lọmọọ́ tún ṣorí Ayé le! Kín lẹ̀dá fẹ́ ṣayé yìí sí ná? Ẹ̀dá ọmọ Ádámọ̀ ń yé síra wọn lára! Bẹ́ni bá ní, wọn á bínú Bẹ́ni bá ń pòbììkòlò nínú ùyà Wọn á wọ̀yẹ̀wù rínni nírìn-ín ẹ̀gàn létè Adíá fún Jálurà tí í ṣọ̀kanmùní ‘Fẹ̀tọ̀ṣe A bù fún Bínúrà tí í ṣọmọ ‘Fáṣọlá Bí Jálurà ti í kọ́lé mọ́lé Tí í rọkọ̀ mọ́kọ̀ Bẹ́ẹ̀ ní í kààsẹ̀ máàsẹ̀ Bẹ́ẹ̀ sì rèé Iṣẹ́ agbẹ́lẹ̀ lọmọ ‘Fẹ̀tọ̀ṣe í ṣe Ọmọ ‘Fáṣọlá móṣùká rìkíṣí òun tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ní í gbówò ẹ̀gàn ọmọ ‘Fẹ̀tọ̀ṣe lérí Láti gan ẹni tájé ti ń bugbá jẹ fún Kò pẹ́ réré Kò jìnnà púpọ̀ Jálurà ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ Ó bá gboko aláwo lọ Babaláwo rẹ̀ bá dÍfá fún un Ó ní: Èké ti dáyé, ọjọ́ pẹ́ Tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun wàdúgbò, ọ̀ná jìn Òfófó dórílẹ̀, ayé rújú pọo Sùúrù ló pé Ìkà ò sunwọ̀n… Inú bíbí, n ò fiṣẹ́ mi rán ọ Ẹ̀dọ̀ fùfù, n ò bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀ Orí Adéètú Abìwàpẹ̀lẹ́ ni mo fiṣẹ́ mi bẹ̀ Jálurà gbọ́ gbogbo ohun táwo rẹ̀ sọ Ó múyìn yìn fún Babaláwo Awó náà ń yinFá kíkankíkan Jálurà fi sùúrù ṣe Ó gbà pégi Ọlọ́run lọ́ lòun Tọ́mọ aráyé ò leè fà tu Ọ̀nà ò jìn títí Bínúrà gbé kèéta rẹ̀ hànde Ó bùṣe gàdà Ó bùṣe gèdé Ó lọ́mọ ‘Fẹ̀tọ̀ṣe múṣẹ́ mọ́ṣẹ́ ni Ló fi là bẹ́ni Èdùà ṣẹ́gi ọlà fún Ṣé bẹ́ni bá kúkú ń ṣe ‘fàyàwọ́’ Ó yẹ kábínú-ẹni lè ṣe ‘fẹ̀yìnwọ́’ Ọ̀ràn yìí ò falẹ̀ lọ títí Bínúrà sáré ẹ̀gàn títí Ó toko ìròkò dóko ìrókòto Alákọrí bínú orí ralákeji Wọ́n wẹ́ni tí yóò gbẹ́lẹ̀ títí Kí wọ́n gbọ́mọ ‘Fáṣọlá hánu Álímì Tí í ṣọmọ Àtẹ̀pẹ́… Ẹ fèyí kọ́gbọ́n, kí ẹ yé bínú orí Ẹ fèyí kọ́gbọ́n, kí ẹ yé bínúu kádàrá Dé kádàrá ládé, kí ó má baà dádée kodoro Torí igi tỌ́lọ́run bá ti lọ́ Kò ṣeé fà tu fádáríhurun.
Ọ̀rọ̀ Nípa Òǹkọ̀wé:
Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó,ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá.
Àwòrán Ojú ìwé yìí jẹ́ ti The Guardian Nigeria Image https://guardian.ng/life/a-journey-into-the-world-of-nigerian-art/