Ẹni tó bá mọ àlùmúńtù 
Ẹ bá mi wá a lọ, a ní gbólóhùn 
Ẹni tó bá mọ abà tí ikú ń gbé 
Ẹ bá mi ké sí i pé ìpàdé ń bẹ 
Ẹni tó bá mọ ọ̀nà tí ikú ń tọ̀ 
Ẹ sọ fún un pé kò dúró ní ìrònà 
Ọ̀rọ̀ wà tí a fẹ́ dìjọ yànnànà. 

Bí ẹ bá ń jáyà láti jíṣẹ́ 
Kò burú ẹ jẹ́ ń fohùn ránṣẹ́ 
Sí oníṣe Olódùmarè tó ń 
Fojoojúmọ́ pa ni lẹ́kún 
Ẹ jẹ́ ń pàrokò sí àkàndá ẹ̀dá 
Tí ń fìgbà gbogbo kọ́ mọ́ adáríhunrun 
nií pápá mọ́ra. 

Tí ó fọwọ́ lẹ́rán kéèyàn ó ṣebẹ̀ tó dùn létè 
Tí ó sì yọwọ́ èèyàn nínú oúnjẹ lójijì 
Lásìkò tó yẹ kó máa jẹ̀gbádùn ọbẹ̀ ọ̀hún. 

Tí ń dènà dè wọn lọ́nà oko 
Tí ń dẹ́bùrú ọmọ Ádámọ̀ lọ́nà 
Tí ń sọmọ aráyé dọmọ òrukàn 
Tí ń sọ aya di opó láìròtẹ́lẹ̀. 

A sọ onílé dẹni tí ń sùn ní gbàgede 
A sì sọ ẹni tó ń sùn lórí tìmùtìmù 
Dẹni ń sùn nínú erùpẹ̀ 
A sọ onílé di ọlọ́dẹ àpàpàǹdodo. 

Ẹ bá mi bèèrè lọ́wọ́ Àlùmúńtù 
Pé kí ló dé tíkú kìí gbàyọ̀ǹda
Kò tó wọlé wá báni lálejò 
Àlejò tí ò ṣe é lé dànù
Àńbèlètè a ń sá á fún. 

Àlùmúńtù tí já èrò tí kò pè sọ́kọ̀ sílẹ̀. 

Ẹ bá mi wí fún un pé kó rọra 
Iṣẹ́ tó ń jẹ́ ó padà wá kàn án bó pẹ́ 
Ọba mi Yarabi ó gbẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ kan 
Tí gbogbo wa ó di sàwáwù. 

Ìgbà yìí lòun náà ó mọ̀ 
Bí iná tó fi ń jóni ṣe ń rí lára. 

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.

Àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé jẹ́ ti Cleveland Art

Comments

  1. Ikú pin, ó pin
    Ikú pin, ó dẹtì
    Bíkú bá ń ṣa ẹgbẹ́ mi pa
    Ọ̀tọ̀ lọ̀yẹ̀kú yóò máa ṣà mí sí….

    Ẹ kú àrògún sà. Ẹ sì kú ohùn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *