Láyíwọlá ò sẹ̀sẹ̀ máa f’ẹ́wọ́. Ògbóntarìgì olè ni. Kìí ṣe ọlọ́sà rárá o. Tó bá ti kọjáa àfọwọ́rá, kìí bá wọn gbèro rẹ̀. Fún Láyíwọlá olè jíjà jẹ́ bíi ìpè, àfi bíi ẹni pé a fi rán-án ni. Ó máa ń yàá lẹ́nu bí wọ́n bá ń wí pé olè jíjà ò dára. Ṣé t’àwọ̀n ṣénítọ̀ tín kó owó mì bíi kàlòkàlò tí ayé ṣì tún kan sáárá sí ni kó sọ ni àbí àwọn olórí ẹ̀sìn tín fi owóo Ọlọ́run se fáàárí kiri ayé. Túnbọ̀ ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀ri ọkàn ò yé Láyíwọlá rárá o. Ó gbìyànjú láti bèèrè lọwọ àlàgbà kan báyìí, oníyẹn ṣọ pé Láyí nílòo ètò àdúà pàtàkì nítorípé ẹní bá gbé èṣù mì nìkan níí sọ pé òun kò ní ẹ̀rí ọkàn. Ibi tí oníyẹn tín fèdèfọ̀ ni jagunlabí ti gba oko bòmíràn lọ.

Kìí kúkú ṣe Láyíwọlá ni àbísọ rẹ̀. Sàídì Àmùdá ni wọ́n kọ soríi ìwé ẹ̀rí ìbí rẹ̀. Sùgbón kìí fira rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ ganan. Kí sì ni èrèdi rẹ̀? Nítorí ọjọ́ ọ̀la. Láyí fún ara rẹ̀ mọ̀ wí pé nínúu ẹgbàá ọjọ́ọ tí gbéwìrì ní, ọ̀kan á padà jẹ́ ti olóhun. Kò sì sí ìgbà tí Ọlọrun o ní jẹ́ tí kò ní padà jẹ́. Òmùgọ ọ̀daràn níí ròpé won ò lè mú òhun. Lóòótọ́ Láyí lọ́pọlọ púpọ̀ o sì ṣáápù sùgbón ó ní ìkóra-ẹni-níjánu. Nítorí náà, ọjọ́ tí pálábáa rẹ̀ bá ṣégi tí ọwọ bá tẹ̀ẹ́ tí wọn sèèsì ka orúkọ rẹ̀ nínúu ìròyìn, tí pépà sí gbée, kò ní tàbùkù asọ àlà orúkọ rẹ̀. Kìí se pé o nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀, sùgbọ́n òun ló wà lóríi ìwé ẹ̀rí ìbí rẹ̀. Tó bá sì fẹ́ lọ sí òkè òkun, orúkọ tí yóò lò nùnun. Láyí mọ̀ pé òhun ò le jalè títí ayé òhun. Ó sì gbọdọ̀ palẹ̀mọ́ fún ọjọ́ ọ̀la rẹ̀. Àmọ́ sá kìí ṣe ní ìlú yìí àbí tani kò sàìmọ̀ pé jápá ló ṣúọ̀ jù báyìí.

Láyí fẹ́yìntì ó ń gbádùn olórin tùǹgbá bẹ́ẹ̀ ní afẹ́fẹ́ tútù ń fẹ́ síi lágbárí. Ibí ayẹyẹ ìgbéyàwó ló ti wá sọsẹ́ lónìí. Àwọn òmìrán bíi méfà lówà l’ẹ́nu ọ̀nà tí ó wọ inúu gbọ̀ngàn. Wọn ò fura sí Láyí rárá, kìí sáà se pé ó kọ olè s’ójú. Tààrà ni Láyí wọlé láì sí ìdádúró. Kò pẹ́ tí jagunlabí ti jókòó sí oríi tábìlì tí wọ́n kọ ‘ọ̀rẹ ọkọ’ sí. Láyí ò dá ọkọ-ìyàwó mọ̀ o. Ṣùgbón láìpẹ́, àwọn tó làyè gan dé. Wọn ò ro alayé lẹ́jọ́ kankan. Ojúu rẹ̀ kò kúkú jọ t’olè kò sì hu ìwà ìbàjẹ́ láàrin yẹn rárá. Ojúu agbo ló ti lọ sá sẹ́. Nígbà tí wọ́n o fi jó tán, isẹ́ ti dáùn. Láyí kìí jí ẹrù rádaràda. A máa farabalẹ̀ tú pọ́ọ̀ọ̀sì asì tún dáa padà tó bá ti mú òun tó jọjú níbẹ̀ kúrò. Kìí sábà mú fóònù. Kí ló fẹ́ fi se? Àmọ́ sá, Láyi máa ń mú ẹ̀sọ́ a sì máa ń sọ́ àwọn tí yóò ṣe ìjànbá rẹ̀ dáadáa kó tó súnmọ́ wọn.

Bó ṣe parí iṣẹ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ronú bí yó ṣe jáde bí yó sì ṣe rìn ìrìnàjò tó fi jẹ́ pé tó bá dalẹ́ tóbá wọlé, yó ti sọ gbogbo ẹrù rẹ̀ di owó. Lọ́gán ni Láyí súnmọ́ àwọn olórin, ó ti kíyèsi pé ọ̀nà kán wà tó súnmọ́ wọn tó le gbà jáde.

Ó yọ́ bóró jáde ó wá yípo gbọ̀gàn náà kó tó wá dá kórópe kan dúró lójúu títì, ọkọ̀ náà tuntun díẹ̀. Layí bẹ́ sínuúu ọkọ̀, léèsì aláwọ̀ ewé rẹ̀ sìn fẹ́ lẹ́lẹ́. Nígbàtí yó bá fi délé, ohun ìní rẹ̀ yóò ti fi bíi igba ẹgbẹ̀rún náírà.

Àwọn tó gbọ́n nínú àwọn tó ṣe lọ́sẹ́ á ti fura, wọ́n á sì ti máa fi èpè ránṣẹ síi. Àmọ́ bó wù wọ́n kọ́n gbébọn yìn jẹ, Láyí ti dàràbà, ó ti dìgí ńlá. Ọ̀rọ̀ ti di àlọ lámilámi, kò sì sí babánlákú baba ẹnì tí yó rí àbọ rẹ̀.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọláyínká Opanike jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga LAUTECH, Ògbómọ̀ṣọ́ ó sì fẹràn láti máa kọ ìtàn kúkúrú.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Cook And Becker.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *