Nígbà mo wà lọ́mọ ọwọ́
Mo gbájú métè ìyáà mi korokoro
Nígbà mo wà pẹ̀lú bàbá èmi
Mo wòye ìsọ̀rọ̀sí rẹ̀
Mo wẹnu àwọn tí wọ́n gbé mi ṣiré
Mo wètè àwọn tí a jọ gbé pọ̀ láṣùwàdà
Mo kédè, mèdè, fèdè fọ̀
Bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ kẹ́rẹ́
N óò gbé e sọ́pọlọ
Bí wọ́n bá sì ń fèdèé wírọ̀ —
Òfófó òun irọ́— léjìdà-léjìdà
Tèmi ò ju kí n ti fetí sí bí wọ́n ti ń fèdèé sọ̀rọ̀

Kọ̀ pẹ́ títí
Kò jìnnà púpọ̀
Mo tẹ́ni tí í pe baba ni baba
Mo tẹ́ni tí í pèyé léyèé láìfọ̀tá-pè
Díẹ̀díẹ̀, ọ̀rọ̀ ń jábọ́ lẹ́nu èmi lákọlákọ
Kò sóókọ́ táyé ò sọ mí tán
Kò sí súná tí aṣùwàdà ò pè mí 
Wọ́n pé “ọmọ ńlá” ni Wàhábù
Wọ́n sì tún pe Èjìrẹ́ “lájẹ̀ẹ́” tí mi ò jẹ́ tẹ́lẹ̀
Lórí pé mò ń wírọ̀ bí tàwọn àgbà ìṣáájú
Mò ń fọ̀ létè bí ẹni ó ti tọ́mọ ẹgbẹ̀rún ọdún
Wàràwàrà lèdè ń dún lẹ́nu èmi bi òjò àsùbáà

Èdè lèdè tóbìí bí mi mọ́
Ogún ìní mi lèdè mi! 
Òun lèdè tí mo gbọ́njú bá
Òun lèdè tí mo fi kọ́rọ̀ fífọ̀
Bébi ń nà mí ní pọ̀pá
N óò móókọ́ mọ̀mọ́ mi lénu
Bí mo bá fẹ́ rẹ̀ǹgbẹ náà pẹ̀lú
Orúkọ èyé mi náà ni n ó fi bọnu
Èdè nìkan ló lè mẹ́ni ṣèyí nírọ̀rùn o jàre
Èdè mi ni ogún ìní mi!
Èdè Yorùbá ò ní kú!!
Ọmọ Odùduwà, ẹ̀ bá jí gírí sédè ẹ̀yin

Níjọ́ mo dé ilẹ̀ Árábù níjọ́sí
Ẹnu wọn ni mo fi í ṣèran wò
Ní bí wọ́n ti í sọ Lárúbáwá lédè
Níjọ́ mo dé Mìnà lọ́dọ̀ ọmọ Dzukogi
Haúsá tí ó ń fọ̀ lédè ò wínrìn
Ṣé ọjọ́ mo lọ wo ọmọ Adamu Manarakis
Ní Nupé lọ́hùn-ún, ni mo fẹ́ sọ ni? 
Àbí èdè tí Yínmínrín olùkù mi dà bolẹ̀ ní Dẹ́tà ni mo fẹ́ fọ̀?
Àwọn wọ̀nyí ò fèdè bàbá wọn pa mìídìn
Bí ó bá sì ṣe Gẹ̀ẹ́sì náà ni wọ́n fẹ́ fọ̀
Ọ̀gá ni Múdà wọn, ẹ gbà bẹ́ẹ̀

Ọmọ Yorùbá, ẹ ronú!
Ọmọ Yorùbá, ẹ kédè ẹ̀yin
Ẹ ò mèdè í sọ, ọmọ yín náà ò tún mọ̀
Kín ni ìgbẹ̀yìn èdè yìí yóò jẹ́, ẹ wá rò fún mi
Èmi Akéúgbadé ò ní jẹ́ sun tẹtẹrẹ
Kógún ìní mi dogún àwọn ọmọ àtọ̀húnrìnwá
Torí ohun onígbá bá pegbá rẹ̀
Layé í bá a pè é
Èdè mi ni ìdánimọ̀ mi!
Èdè mi ni ogún ìní mi!!

Nípa Òǹkọ̀wé

Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó, ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yorùbá.

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *