Òru là ń ṣèkà ẹni tó ṣe lọ́sàn-án kò fara rere lọ. Ilẹ̀ ti ta sí i ti àwọn ọmọ wòlìbísà tí ń ja àwọn abilékọ àti ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ọlọ́mọgé lólè ara. Àìmọye ìgbà ni láálà ti lù, tí akutupu sì ti hu. Kò fẹ́rẹ̀ sí ìdílé tí kòì lu páńpẹ́ àwọn amòòkùnṣìkà yìí. Gbogbo akitiyan àwọn alákóso ìlú láti ṣàwárí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láabi yìí lo ń forí lu ìgànná. Baálẹ̀ ti pe gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ àti àwòròṣàṣà láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ogun àìmọ̀dí tó ń bá wọn fínra yìí. Síbẹ̀, ibi pẹlẹbẹ ni abẹ̀bẹ̀ wọn ń fi lélẹ̀.

Bí ó bá ti pẹ́ tí a ti ń da obì yóò yàn lọ́jọ́ kan. Alága ìlú Akétantan dábàá pé kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn agbófinró létí. Ó ní, “ìjì tó ń jà tó ń ká aṣọ oríṣiríṣi lórí ìkọ́, kí ẹni tí ó wọ tirẹ̀ sọ́rùn má sun àsùnpara ni o” Baálẹ̀ gbé òṣùbà ràbàǹdẹ̀ fún Alàgbà Kòkúmọ́ fún àbá rẹ̀ yìí. Ó bèèrè pé, lásìkò tí nǹkan ti dàrú bí ẹsẹ̀ télọ̀ yìí, ṣé àwọn náà kò ní gbẹ̀yìn bẹbọ jẹ́ nítorí pé oríṣiríṣi ìròyìn là ń gbọ́ nípa àwọn agbófinró ìlú wa yìí? Fáníran tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn májẹ̀-ó-bàjẹ́ náà kín ọkọ ìlú lẹ́yìn. Ó ní, “lọ́jọ́ òní yìí tí ọwọ́ pálábá gbọ́mọgbọ́mọ kan ségí, àlọ la rí, a ò rábọ̀”.

Èrò alàgbà Yọríọlá tí í ṣe igbákejì alága yàtọ̀ gédégédé. Ó ní gbogbo ohun tí àwọn èèyàn ti sọ dára lóòótọ́ àmọ́ okùnfà ohun tó ń fa ìfipábánilò nílùú ló yẹ ká wá ìyanjú sí kìí ṣe fífi tó àwọn agbófinró létí nìkan. Láyé àtijọ́, a kò lè gbọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àmọ́ esuru ti pàdí dà ó ti ń lé ajá báyìí. Ọkàn wa kò balẹ̀ mọ́. Ọmọ obìnrin kò ṣe é rán níṣẹ́ àyàfi kí ọ̀kan òbí ó wà lókè láìjẹ gbèsè. Kò sí ààbò nínú ilé àti ìta. Mẹ́wàá ń ṣẹlẹ̀!

Bàbá Ọdẹ́gbayì ti ó jẹ́ alẹ́nulọ́rọ̀ lára àwọn ayálégbé ní ìlú Akétantan tí ó wà níbi ìpàdé náà kò ṣàì dá sí ọ̀rọ̀ tó ń ràn bí iná ọyẹ́ yìí. Ó ní bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ń pẹ́ sí i náà ni nǹkan ń bàjẹ́ sí i. Lópin ìgbà tí wọ́n ti forí jálé agbọ́n, ó di dandan kí wọ́n rí ìjà agbọ́n. Ó ní kí wọ́n má fòyà mọ́. Kí wọn fi àgbọn sílẹ̀ fún oníkọ́. Bí ó ti sọ̀rọ̀ tán ni baálẹ̀ fèsì pé ìgbà wo ni àwọn yóò tún fí káwọ bọtan dà? Bí ọ̀rọ̀ bá sì ṣe ń pẹ́ ni yóò ma gbọ́n sí i. Bàbá Ọdẹ́gbayì sọ pé bí ẹrù bá kọ òkè, tí ó sì tún kọ ilẹ̀ ó ní ibi tí a ń gbé e sí. Wọ́n kò fẹnu ọ̀rọ̀ jóná kí wọ́n tó túká lọ́jọ́ yìí.

Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí wọn ti sọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ baálẹ̀ ọkọ ìlú ni àwọn atiláawí yìí tún ṣe ọmọbìnrin kan ṣíkaṣìka. Wọn fi ipá gba aṣọ oge lara rẹ̀. Ọ̀sẹ̀ méjì ni ọmọ náà lò nílé ìwòsàn. Àmọ́ tí Jọpé tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ yìí ni ó ká àwọn ọ̀dọ́ lára jù. Ikú tó ń pa ojúgbà ẹni òwe ló ń pa fún ni. Ìdí nìyí tí wọ́n fi pinnu pé àwọn kò ní dá ìjà náà dá àwọn àgbàlagbà nìkan. Wọ́n yan àwọn kan kí wọn máa fimú fínlẹ̀ láti ṣe àwárí àwọn amòòkùnṣìkà wọ̀nyí.

Ọmọọmọ Bàbá Ọdẹ́gbayì ni wọn rán níṣẹ́ ni ìrọ̀lẹ̀ ọjọ́ kan, kò tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí ọmọ náà lọ ni láálà tún lù. Ṣàdéédé ni arákùnrin kan ń pariwo:
“Ẹ fún mi lómi!. Mo fẹ́ mumi!
Ara rẹ̀ kò lélẹ̀ mọ́ bí i ti olókè ilẹ̀. Ariwo yìí ló ta àwọn ènìyàn lólobó. Ká tó ṣẹ́jú èrò ti pé ṣíbáṣíbá lé e lórí. Ìgbà yìí ni wọ́n tó mọ̀ pé Lárìndé ló wà nìdí apẹ̀rẹ̀ tó fi di àléèba. Ọ̀kan lára àwọn ayálégbé ní í ṣe. Ojú rẹ̀ jọ ojú ọmọlúwàbí àmọ́ wòlìbísá ẹ̀dá ni.

Àwọn ọ̀dọ́ kò tilẹ̀ wo ariwo tó ń pa kí wọn tó ṣíná ìyà bolẹ̀ fún un. Àwọn kan ni ẹ sọ taya si lọ́rùn kí a dáná sun alákọrí. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan ni, ẹ jẹ ká mú un lọ sí àgọ ọlọ́pàá kí ó lọ fojú wina òfin. Ibi tí wọ́n tí ń sọ̀rọ̀ yìí ni baálẹ̀ ti bá wọn níbẹ̀, tí ó sì pàrọwà fún wọn pé kí wọ́n má ṣe torí dídùn ifọ̀n họra kan eegun,kí wọ́n jẹ́ kí àwọn fà á lé ìjọba lọ́wọ́. Kíá ni wọ́n tí alákọrí sínú ọkọ̀ ó di àgọ ọlọ́pàá. Wọ́n ṣàlàyé ìwà pálapàla tí Lárìndé tì hù láti ẹ̀yìn wá fún wọn. Àwọn ọlọ́pàá kò bèṣùbẹ̀gbà kí wọ́n tó fi sí àtìmọ́lé lẹ́yìn tí òun fúnra rẹ ti jẹ́wọ́ àwọn ìwà láabi tó ti hù. Báyìí ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣe kú tí isó sì pin ní ìlú Akétantan.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Lanto Azasime.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *