Aáyan ògbufọ̀  Sùúrù (Orin Démíanù ọmọ Málì àti Ọba Náàsì)      Patience (ft. Nas)Damian Marley                 

Ẹsẹ̀ Kiní                                        

Àwọn kan nínú àwọn òpònú tó jáfáfá

Ò kúkú le ka èdè àwọn Mùmíyà Íjíbítì

Wọ́n gbéra pá o di’nú òṣùpá

Àmọ́ wọn ò le rí oúnjẹ fún inú t’ebi npa.

Wọn kò náání àwọn ọ̀dọ́

Ṣùgbọ́n wọn n ṣe’tọ́jú àwọn ẹranko inú súù

Tori pe Ìjímèrè ló ń p’owó tabua wọ’lé

Bí àwọn oníròyìn ṣe ń jà wá l’ólè rèé o,

Àwọn ara oko l’ábúlé ni wọ́n fi ń hàn wá lorí tẹlifísàn

Bẹẹni, àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ò kúkú le ṣàlàyé àwọn òkò Ijíbítì.

Àjíhìnrere ń rí ounjẹ òjọ́ọ rẹ látara fídíò egungun àwọn ọmọdé ti’yà n jẹ

Ṣèbí èyí sì ni àwòrán náà – òjé àwòrán ti wọn fi ń jẹ wa.

Wọ́n ra ṣòkòtò kakí

Wọ́n sọ ar’awọn di Indiana Jónsì lójijì

Bi wọ́n ṣe ń jí wúrà, pẹ̀lú àwọn ìwé, bẹẹ ni wọn n jí àwọn egungun tí a ti sín pẹ̀lú.

Àwọn wèrè paparásì tí mo ti rí àti àwọn tí mo mò

Wọn a gbé àwòrán ti kò suwọ̀n jù kí aráye ba lè ri,

Àwòrán tí ò suwọ̀n yìí sini wọn yío ma fihàn

Kí àwọn ti o wà ní ìwọ̀-oòrùn ma le lo si ìlà-oòrùn

Kí ọ̀kàn wọn sì balẹ̀.

Ẹranko náà n lo òjé fun wọn

Àmọ́ ibo ni wọn yío salọ nígbà ti èèmọ̀ bá dàgbà?

Àwọn ìran Sólómọ́nì ti wọn ò le ṣẹ́gún tí wọn kò le ṣẹ̀dá

Ohun ìṣẹ̀dá ẹ̀mi mi ti ma fí ayérayé ní, Olúwa.


Kórọ́ọ̀sì

Sabali, Sabali, Sabali, yonkontê

Sabali, Sabali, Sabali, kagni

Ni kêra môgô x2 (Èdè Bàmbàrà)


Ẹsẹ̀ Kejì

Ṣé wọ́n bi wa l’áláìmọ̀kan ni, àbí wọn bi wa taati m’àmọ̀n tán

Ṣe à ń dàgbà si ni, àbí a kàn ń gùn bí àkùkọ Sáúdí

Ṣé ẹyin le m’èrò ọ̀kàn? Ṣẹ’le wo àtẹ́lẹwọ́?

Ṣé ẹ le sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ bó d’ọ̀la? Ṣẹ’le r’íjì, b’ó ń bọ̀?

Wọ́n ní ayé tẹ́ lọ, pé bẹ’rìn títí, ẹ ó d’ópin ẹ̀

Nísinsìnyìí wọn l’áyé ti rí rogodo bi bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá

Tí ṣéepù rẹ̀ bá tún yipadà l’ọ́la, gbogbo èèyàn a tún bú s’ẹ́rin.

Ọmọ ènìyàn ò le fì’dí ǹkan tó yàn lati maa sọ múlẹ̀

Bẹẹ sì ni, kò tún ni ṣe ìwádí láti fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀.

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n fáfitì l’áwọn gbọn, wọn l’áwọn m’òye

Ṣùgbọ́n ẹ sọ fún wọn kí wọ́n wa ògùn sínsín

Ìgbà yẹn ni wọ́n a maa y’ọkun ní mú.

Àwọ́n olówo a màá rán ‘rawọn papọ̀ bi wọn bá ṣè’ṣe

Bẹẹni, àwọn kan ti ń fi àmọ̀ lásán làsàn wo eegun tó ti kán l’ábúlé.

Ṣẹ́ le r’íran? Ṣẹ ẹ le wò’ràwọ̀?

Ṣẹ́ le jẹ k’aláafià jọba? Ṣẹ le jagun?

Ṣẹ́ lè fún wàrà mààlú, bótilẹ̀jẹ́pe ẹ n wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́?

Nísinsìnyìí, ṣẹ le jà’jàbọ́? Ní gbogbo ọ̀nà?


Kórọ́ọ̀sì

Sabali, Sabali, Sabali, yonkontê

Sabali, Sabali, Sabali, kagni

Ni kêra môgô x2 (Èdè Bàmbàrà)


Ẹsẹ̀ Kẹ́ta

Ta ló kọ Bíbélì? Ta ló kọ Kùránì?

Àti pé, ṣe ìjì àrá lo bí ayé ni?

Tí a wá bí àwọn dáínosọ̀?

Ta ló kọ́ gbọ́n’gbọ́n ọ̀rọ̀? Ta ló kó òǹkà jọ?

Àti pé irú ẹ̀fún wo gan an ló ń di ọmọ ènìyàn?

Gbogbo ǹkan tó ń bẹ l’áye là ń pamọ sínú angolo, sínú máikirowéèfù

Ṣèbí, kò sí b’oṣelè rí kó’rí a da.

Kíni ènìyàn? Kíni ènìyàn a bìdí yàn àn yán? Kíni ọmọ adárí-hurun?

Gbogbo ohun tó wà l’órilẹ̀ la ń jẹ l’ajẹrun, là ń dìlítì.

Ba a fẹ ṣe bébà,

A gbọdọ̀ ni ilẹ̀, a gbọdọ̀ ní ìsàrè oko tó pọ̀.

Ṣè bi ìyẹn ló múmi jòkó fẹhìntì bi Jáàkì Níkólósìn

Tí mò n wò wọ́n bí wọ́n ṣe ń t’ayò bi àwọn Lékàsì.

Ní ayé tó kún fún àwọn asọ̀rọ̀ maṣebẹ́,

Àwọn awòràwọ̀, àwọn abókúsọ́rọ̀ àti àwọn àyájọ́ tó dájú.

Ǹjẹ́ ìwọ́ gbàgbọ́ nínú àwọn agbára àìrí? M’úyọ̀ ki o dàá kọjá èjìká rẹ sẹ́yìn

Ko wá wúre fún ọjọ náà.

Bẹẹ l’ẹnìkan mú ère fún mi

Ló n ki abẹ́rẹ́ bọ̀ mí l’ọ́kàn

Ṣùgbọ́n èèwọ̀, kò le è wọlé

Lẹ́ẹ̀kọ̀kan, a ma dàbí ìgbà tó ba ń wọlé, ṣùgbọ́n ẹ̀mí mi yi

Ẹ̀rù ò bàmí o…ẹ̀rù ò b’odò.

 Má ṣe rò pé o le gbá ẹ̀mí mi mú

Nítorí o dà bi jagun jagun ni láti ọmọ ọdún méje.

Emi tí mo ti gbá àwọn òkú ènìyàn mú pẹ̀lú ọwọ mi

Ti mo mọ bó ṣe tútù to, àbí

Kílodé tí wọn ti ẹ̀ fi bí wa gan an naa

Nígbà tó ṣe pé, gbogbo wa làá padà wá d’ìlẹ̀pa?


Kórọ́ọ̀sì

Sabali, Sabali, Sabali, yonkontê

Sabali, Sabali, Sabali, kagni

Ni kêra môgô x2 (Èdè Bàmbàrà)


Eléyìí jẹ́ àyọkà láti inú ìwé Àtẹ́lẹwọ́ Pelebe, ẹ le rí kọ́pì yín rà lóri Okada Books.


Ọ̀rẹ́dọlá Ibrahim Àjàtóntìrìàjàbalẹ̀ jẹ́ akẹ́kọ́ gboyè ìmọ̀ òfin láti ilé ẹ̀kọ́ gíga fáfitì Ìbàdàn. O jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Òmù-Àrán ní ìpínlẹ Kwara nibi tí o ti ni àǹfàní láti kọ́ púpọ̀ nípa iṣe àti àṣà Yorùbá l’ọ́dọ̀ ìyá bàbá rẹ̀ – Alhaja Mọ́ríamọ̀ Ayélàágbe Ọ̀rẹ́dọlá. Ìlú yìí nàá ni o ti lọ ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama níbi tí ó tún ti ní àǹfàní àti kọ́ nípa ẹ̀kọ́ Yorùbá láti ọ̀dọ̀ àwọn òlùkọni tó dágánjíá tí wọ́n sì tún múnádoko pẹ̀lú. Ó k’ẹ́kọ́ jádé ní ilé ẹ̀kọ́ girama Government Secondary School Òmù-Àrán gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ́ tó yege jù lọ ní èdè Yorùbá. Fún ìgbà dìè, Ibrahim ti ṣe ìwọ̀nba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Oníṣòwò kékeré, o sì tún jẹ́ Akéwì, Òǹkọ̀wé, Oníròyìn àti Òṣèré Akẹ́kọ́ ní èdè gẹ̀ẹ̀sì àti ní èdè Yorùbá. Ibrahim jẹ́ ara àwọn òlùdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́, ilé iṣẹ́ SkillNG àti ìwé ìròyìn orí afẹ́fẹ́ ThePageNg. Ìwé lítírésọ̀ Yoruba tí ó fẹ́ràn jùlọ ni Eégún Aláré láti ọwọ́ Láwuyì Ògúnníran. Ibrahim jẹ́ olùkáràmáisìkí ìmọ̀ àti orúkọ rere, o sì tún gbàgbọ́ pé owónikókó. Ẹ lè kàn si ni ibrahimoredola@gmail.com tàbi lóri 07061282516.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *