Ìwọ̀n ẹni là á mọ̀,
A kì í mọ tẹni ẹlẹ́ni.
Bí a ò bá ronú àti bùkèlè,
Ó ṣe é ṣe ká jẹwọ móúnjẹ́.


Bí ìrònú ò bá jẹ́ kí àgbà ó sùn,
Tí igbe oúnjẹ ò jẹ́ kọ́mọdé ó sinmi ariwo,
Ń ṣe lọ yẹ ká ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ náà.
Bádé bá adé nílé kó tó di aládé,
Bọ̀rọ̀kìní bọ́rọ̀ nílẹ̀ kó tó dọlọ́rọ̀,
Oyèrọ̀gbà bá iyùn ní yẹ̀wù kó tó dolóyè ọba,
Ipò kúkú làgbà nílẹ̀ yìí,
Tọlá towó tiyì làbúrò,
Ẹni a fipò dán wò tó gbàgbé àtẹ̀yìnwá,
Ó dépò tán, ó wá ń sayé ṣìbáṣìbo,
Òní gbàgbé àná,
Kò rántí pé òun ó dìtàn,
Ilẹ̀ mọ́ tán,
Òní wá ń bẹ̀rù àtiwọ̀ oòrùn.


Ọlọ́lá tí ò rántí ìgbà tí ò ní,
Olówó tó gbàgbé àti máa ṣe bọ̀,
Bọ̀rọ̀kìní tí ò rántí ìgbà tí ò jẹ́ nǹkan kan,
Wọ́n dépò tán, wón ń sayé bí wón ṣe fẹ́,
Wọ́n kúkú ti gbàgbé wí pé,
Gbogbo ẹni ayé ń yẹ ní kó máa ṣọ́ra,
Gbogbo ẹni ìgbà dẹ̀ fún ní kó ṣe pẹ̀lẹ́,
Gbogbo ẹni tóní ni kó rántí ènìyàn tí ò ní,
Gbogbo ẹni tó ń dunnú ni kó rántí ẹni ọ̀rọ̀ ń dùn,
Gbogbo asíwájú ni kó rántí ọmọ ẹ̀yìn in wọn,
Nítorí ẹni ayé ń yẹ, kó máa ṣọ́ra,
Ẹni ọ̀rọ̀ ń dùn, kó ṣe mẹ̀dọ̀,
Ohun ayé ilé ayé ló mọ.


Bówó tì lè wù kó káyé tó,
Aláìní ò ní saláì má wà.
Bí afẹ́fẹ́ àlàáfíà tí wù kó fẹ́ tó,
Kò dí ìjì búburú lọ́wọ́ kó má fẹ́ sọ́dọ àwọn kan
Kò sì sí bí ayé ṣe lè dẹrùn tó,
Ó di dandan kó le lọ́dọ̀ àwọn kan.
Àtunbọ̀tán ni ká rò, nítorí ẹ̀yìn ọlá.
Eni ayé ń yẹ…


Azeez Ọláìyá Yusuff  jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá àti Ẹdukésàn ni ilé-ìwé Ọ̀báfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Unifásítì Ilé-Ifẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ sí kíkọ ewì ní èdè Yorùbá, ó sì ti kọ oríṣiríṣi ewì ṣùgbọ́n tí  kò tíì ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ fún ìdí kan tàbí òmíràn.  Ọkàn lára ewì rẹ̀ ni Ẹni Ayé Ń Yẹ.

Àwòrán ojú-ìwé láti ọwọ́ Babajídé Ọlátúnjí

Comments

  1. Òdodo ọrọ. Ẹni aye n yẹ ko maa sora ni o, borokinni aná dà? Ku lakaaye, Azeez Olaitan Yusuff.
    Ekare, ẹgbẹ atelewo, website yin dun kà. Beautiful layout! 👏👏

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *