Inú títa ló jí mi. Mo tilẹ̀ kọ́kọ́ rò pé àlá tí mo lá ni ó fà á ni – èèyàn ò gbọdọ̀ jẹ ata rodo tútù kí nǹkan má ṣe ni. Sùgbọ́n irọ́ ni o, ńṣe ni inú náà túbọ̀ ń le síi. Ó wá ń gbóná láti oókan àyà mi dé inú ikùn. Níbi tí mo ti ń gbìyànjú oríṣiríṣi nǹkan ni mo ti ṣàkíyèsí pé bí mo ṣe ń mumi, gbogbo ibi tí omi náà bá kàn ń tù mí. Mo bẹ̀rẹ̀ síi mumi ṣùgbọ́n omi àmù mélòó ni mo fẹ́ mu? Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ díẹ̀ ní mo rán alábàágbé mi ní òògùn ní ilé kẹta.
Lóòótọ́, inú rírun ò sàjèji sí mi—mo ti ní ọgbẹ́ inú láti bíi ọdún márùn-ún sẹ́yìn—ṣùgbọ́n kò le tó báyìí rí. Èmi ni mo sì fà á.
Ní bíi oṣù méjì sẹ́yìn ni mo lọ sí ilé ìwòsàn kan lágbègbè mi. Inú náà ni mo bá lọ. Lẹ́yìn àyẹ̀wò, dókítà ka àwọn nǹkan tí mi ò gbọdọ̀ jẹ mọ́. Ó ní kí n yẹra fún nǹkan díndín, mílíìkì, ọtí ẹlẹ́rìndòdò, ọsàn, nǹkan tútù (èyí tí a gbé sínú ẹ̀rọ amúǹkantutù), nǹkan gbígbóná àti nǹkan aláta. Kò sí èyí tí ó mú mi kọ hà bíi ti méjì ìkẹyìn. Ṣé oúnjẹ tútù tí kò ta ni kí n máa wá jẹ ni? Kí ọkàn máa rìn mí?
“Oúnjẹ wo ni ẹ fẹ́ràn jù?” ni dókítà tún bèèrè.
“Dòdò àti ẹ̀wà ni.”
“Ṣé ẹ mọ̀ pé dòdò wà lára nǹkan díndín tí mo sọ? Tí ẹ bá máa jẹ̀wà náà, ẹ má fi epo síi.”. Nibi ni mo ti sọ lọ́kàn mi pé ara ń dun dókítà. Lóòótọ́ mo dúró gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ, ṣùgbọ́n ọkàn mi ti kúrò níbẹ. Nígbà tí wọ́n ṣetán, mo lọ sí ilé òògùn láti gba àwọn òògùn tí wọ́n kọ fún mi, mo sì gba ilé lọ.
Alẹ́ àná ni mo se ẹ̀wà kan tí ó fọ́ dáadáa, mo sì dín atarodo tí àlùbọ́sà já orí rẹ̀ síi pẹ̀lú epo; ó ń ta sánsán. Dòdò náà ò gbẹ́yìn. Ǹjẹ́ irú ẹ̀wà yìí ṣeé jẹ ní tútù bí mo bá ti ẹ̀ rántí ìkìlọ dókítà? Mo jókòó sí orí rọ́ọ̀gì, mo wá wọ́ oúnjẹ náà mọ́dọ̀. Nígbà tí mo jẹ ẹ́ tán, mo tún pọ́n abọ́ lá. Lẹ́yìn náà ni mo fẹ̀gbẹ́ lelẹ̀ tí mo nawọ́ gán ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi lórí tábìlì. Orí eré oníṣe tí mò ń wò ni orun ti gbé mi lọ..
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, mo pinnu lọ́kàn ara mi pé n ó máa dín oúnjẹ gbígbóná àti aláta kú. Iná èsìsì kìí jóni lẹ́ẹ̀mejì. Ṣùgbọ́n kí n tó ṣe bẹ́ẹ̀, mo gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi ata tí ó kù jẹ́ èkuru ìyá Bíọ́dún—ó ti ń wù mí jẹ tipẹ́.
Nípa Òǹkọ̀wé
Khadijah Ọlájùmọ̀kẹ́ Kọ́lápọ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí a ti ń kọ́ nípa ilé kíkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fáfitì Ìbàdàn. Ìlú Ìsẹ́yìn ni ó dàgbà sí, èyí sì kún ara nǹkan tí ó jẹ́ kí ìfẹ́ àṣà Yorùbá rinlẹ̀ ní ọkàn rẹ̀. Ó máa ń kọ ìtàn ní èdè Yorùbá àti èdè gẹ̀ẹ́sì. Ó sì fẹ́ràn láti máa jẹ dòdò.
Àṣẹ lóri àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Sarah Khan.