Aáyan  ògbufọ̀ iṣẹ́ “Àbíkú” láti ọwọ́ Wọlé Ṣóyínká

 
Asán, òfúútù fẹ́ẹ̀tẹ̀, aásà tí kò ní kán-ún
ni gbogbo ìlẹ̀kẹ̀ tí ẹ fi dèmí m'áyé
Èmi Àbíkú, ìrìn-àjò àkọ́kọ́ mi rè é
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni, mò ń padà bọ̀ ní'gbà igba
 
Ṣé dandan ni kí n sunkún fún ewúrẹ́ àbí owó ẹyọ,
Àbí epo pupa àti eérú gbígbóná?
Iṣu kìí f'ògùn ṣebùgbé
Láti fi rí ẹsẹ̀ Àbíkú
 
Bí ẹ bá jó ìgbín nínú ìkarahun rẹ̀
Kí ẹ fi ẹ̀yẹ iná dárà sí mi lára
Dá àpá sórí ọmú mi. Ó yẹ kí ẹ lè mọ̀
Nígbà tí Àbíkú bá padà dé
 
Èmi eyín ọ̀kẹ́rẹ́ 
Èmi àdìtú ọ̀pẹ.
Ẹ rántí èyí bí ẹ bá ń rìmí mọ́ ilẹ̀
Tí ń ṣe ẹsẹ̀ òrìṣà
 
Fún ìgbà àkọ́kọ́ àti òmíràn, mo di àrọ̀gìdìgbà tí kò lè kú
Mo di aníkúlápò tí ń f'ikú ṣeré
Bí mo bá bì nígbà tí ẹ bá rọ mí yó pẹ̀lú ètùtù,
Kí ẹ tọ́ka ọ̀nà tí mo gbà wá ilé ayé ràn mí
 
Kí ilẹ̀ p'òṣìkà, kí ó sunkún
Kí yìnyín p'ẹyẹ igúnugún
Ìrọ̀lẹ́ yóò ṣọ̀rẹ́ aláǹtakùn níbi tí ó ti ń ṣọde
Páńpẹ́ ìtàkùn fún esinsin
 
B'álẹ́ b'álẹ́, bí Àbíkú bá wà epo ikú mú,
Ìyá, mo di
Ojòlá tí ń ká sójú ọ̀nà ẹni
Ọ̀rọ̀ yín di ọ̀rọ̀ igbe ẹkún 
 
Èso tó dùn ń retí ikú
Níbi mo kákò sí, ìgbóná wọlé
Àbíkú ń retí ìrìn àjò àrèmabọ̀,
Àrèpadà nígbà igba

Nípa Òǹkọ̀wé

Sùmọ́nù Ajíbọ́lá Adéjùmọ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ni ilé ẹ̀kọ́ fásitì ti ìlú Ìbàdàn, níbi tí ó ti kọ́ ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀gbẹ́ni Adéjùmọ̀ jẹ́ onkọ̀wé eré orí ìtàgé, ewì àti ìtàn kéékèèké. Ó fẹ́ràn láti máa gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá lárugẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *