Ọjọ́ tí mo ti ń fi àwo òyìnbó jẹun kò fọ́ mọ́ mi lọ́wọ́ rí. Ohun tí ènìyàn kúkú ń ṣe nìyí náà ní ń ṣe tẹ́. Èmi nìkan ni mo sì dàgbà nínú ilé e wa. Tí ìyá mi bá ti lọ sí ọjà, èmi ni mo máa ń bójú tó àwọn àbúrò mi mẹ́ta yòókù. Ìyá mi yóò ti jí láti nǹkan bí i aago mẹ́rin ìdajì kí wọn lé bá wa se oúnjẹ tí a ó gbé lọ sílé ẹ̀kọ́, kí a bá máa pẹ́ lẹ́yìn. Ilé ẹ̀kọ́ girama ọlọ́dún kẹta àkọ́kọ́ ni mo wá nígbà náà.
Gbọmọgbọmọ là á rọ́fá adití, ṣé ń kìí ṣe adití nìkan. Tí ìyà mi bá ti ń lọ sọ́jà ni ó máa ń kọrin rẹ̀ sí mi létí pé n kò gbọ́dọ̀ gbàgbé kọ́kọ́rọ́ sí àpò lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Sábàbí méjì sì kọ́, kọ́kọ́rọ́ tí bàbá mi lò ṣẹ́nu ilẹ̀kùn ilé wa kì í ṣe èyí tí ó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ta. Àwọn tó bá gbáfẹ́ ló máa ń lo irú kọ́kọ́rọ́ náà. Tẹnu kọ, lásìkò tí bàbá mi kọ́ ilé wa, àwọn ohun ìgbàlódé ni wọ́n lò. Nítorí náà, a kò lè kù gìrì lọ rà á tí ó bá sọnù.
Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, ibi tí mo ti ń sáré kí n tètè máa lọ sílé ẹ̀kọ́, ṣé ìgbàgbé kò lóògùn, mo gbàgbé kọ́kọ́rọ́ ìyára wa sápò ń kò sì mọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe è mí, mo fẹ́ràn láti máa gbá bọ́ọ̀lù. Mo lọ sórí pápá. Ibi tí mo ti ń gbá bọ́ọ̀lù ni kọ́kọ́rọ́ tí sọnù. Ìgbà tí mo délé n kò fura. Bí màmá mi ṣe bèèrè nígbà tí a dé ilé lálẹ́, òòyẹ̀ ni mo mú irọ́ tí mo pa. Kíá ni mo sọ pé ibi tí a ń fi sí náà ni mo fi sí ní àárọ̀ kí a tó lọ sílé ẹ̀kọ́. Ìyá mi bèèrè pé, “Ta ni ó wá mú un? Jẹ̀bẹ̀tẹ̀ gbọ́mọ lé mi lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ọ̀rọ̀ di wò-mí-ń-wò-ọ́. Ẹsẹ̀ mi ti ń gbọ̀n bí ẹni tí òtútù ń mú.
Bùrọ̀dá Ìdòwú kan tí ó jẹ́ ayálégbé wa ni ó sọ fún ìyá mi pé kí ó jẹ́ kí òun lọ tẹ̀ mí nínú. Ṣé èmi pẹ̀lú bùrọ̀dá Ìdòwú dìjọ mọwọ́ ara wa tẹ́lẹ̀. Òkú mi kò fara pamọ́ fún ẹni tí yóò wẹ̀ ẹ́ rárá. Mo jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni mo gbàgbé sápò mo sì ti délé ẹ̀kọ́ tán kí n tó rí i bóyá ìgbà tí mo ń gbá bọ́ọ̀lù ni ó ti jábọ́. Wọn pàrọwà fún ìyá mi pé à ó dìjọ lọ wá a ní orí pápá lọ́la. Kọ́kọ́rọ́ tí ó wà lọ́wọ́ bàbá mi ni a fi ṣí ilẹ̀kùn lọ́jọ́ yìí.
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí bùrọ̀dá Ìdòwú tí ṣe àdéhùn, wọn tẹ̀lé mi láti lọ wá kọ́kọ́rọ́ náà. A kò tilẹ̀ ṣe wàhálà jìnnà kí Ọlọ́run tó fún wa rí. Bí ènìyàn bá gun ẹṣin nínú mi kò lè kọsẹ̀. Mo lérò pé ọ̀rọ̀ tí bùṣe, à ṣé wí pé ẹgba irọ́ tí mo pa ṣì ń dúró dè mí. Ìyá mi sọ fún mi pé purọ́ n níyì, ẹ̀tẹ́ lọ́ ń mú wá. Wọ́n ní ọmọlúwàbí kì í parọ́, bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí ló yẹ kí n máa sọ.
Nípa Òǹkọ̀wé
Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Baptist Primary School, Bódè Ìjàyè, Abẹ́òkúta. Lẹ́yìn náà ni ó tún tẹ̀síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ Líṣàbí Grammar School,Ìdí Aba. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Èdè Yorùbá àti Haúsá ní ilé ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Àgbà Federal College of Education,Òṣíẹ̀lẹ̀, Abẹ́òkúta. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ilé ẹ̀kọ́ girama ni. Ó fẹ́ràn láti máa kọ ewì àti ìtan àròkọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Ìfẹ́ rẹ̀ sí àṣà àti ìṣe Yorùbá kí ó má lè dìmẹ́ẹ́rí kò láfiwé.