Kò sẹ́ranko bí kìnnìún níjù.
Bó dolókìtì ẹni tí ó ṣe bí ọ̀bọ ò sí.
Ẹranko tí ó sọ pé kí ìkookò ó dákẹ́
Wọ́n bí ojú nínú igbó.
Kòkòrò tí ó rùn bí ìkanǹdù sọ̀wọ́n.
Adé orí ọ̀kín ò jọ tẹyẹkẹ́yẹ.
Ìran agbe ló laró.
Ìran àlùkò ló losùn.
Bó bá di ká ṣẹfun
Ìran lèkélèké ló nìyẹn nínú ẹyẹ.
Àròyé kúkú ni iṣẹ́ ìbákà.
Ìran aláǹtakùn ló lòwú.
Ìran ejò ló ni ká fàyà fà.
Ìran alákàn ló ní ká ṣepo.
À ní kò jọra wọn.
Òkúta ó ṣe jẹ bí ìrẹsì.
Iyọ̀ ó ṣe é là bí ṣúgà.
Òwu aláǹtakùn yàtọ̀ sókùn pátápátá.
Ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú òkùnkùn kì í ṣe sàwááwù.
Gédégédé niṣẹ́ òṣùpá fi yàtọ̀ sóòrùn.
Ìran aláró ló ní ká rẹṣọ.
Ìran onídìrí ló ni ká ṣaájò ẹwà.
Onígbàjámọ̀ là á pé borí bá kún.
Bó bá di ká wẹ̀ òmùwẹ̀ ló nìyẹn.
Ṣé a rí i pé kò jọra wọn?
Òkè Olúmọ ń bẹ nílùú Ẹ̀gbá.
Òkè Ìdàńrè ń bẹ l'Óǹdó.
Ìpínlẹ̀ Bọ̀rọ̀nu ni Kúmárí fìkàlẹ̀ sí
Òkè Ṣérè tí ń bẹ ní Ìpínlẹ̀ Piletú
Kò jọra pẹ̀lú Zeim ti Bauchi.
Alagbalúgbú omi ń bẹ l'Ékòó.
Òkun ò dúró rí, ọ̀sà sì dákẹ́ rọ́rọ́
Odò Ògùnpa yàtọ̀ sódò Ọ̀ṣun.
Odò Ògùn náà o jọra pẹ̀lú odò Ọ̀tìn.
Èkìtì lẹ ó ti ríbi omi gbígbona pẹ̀lú tútù ti ń ṣàn.
Àsìkò ooru yàtọ̀ sígbà òtútù
Àkókò òjò ò ṣe fi wégbà ọ̀dá.
Ìgbà à ń gbìnrè yàtọ̀ sígbà ìkórè.
Àkókò ọ̀dọ́ ò ṣe fi wégba ogbó
Ọ̀sán náà ò ṣe é fi wààjìn.
Bọ́ba mi òkè ṣe dákọ yàtọ̀ sábo sẹ́
Àwọ̀ èèyàn ò jọra pẹ̀lú ú tẹranko.
Bí kúkúrú ti ń bẹ ní dúníyàn
Náà ni gíga ò gbẹ́yìn.
A ní kò jọra wọn.
Ewúro ò jọ ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀ lẹ́nu
Òróǹbó ó ṣe fi wé òróǹbẹjẹ.
Ewé eeran ò jọ tí kókò
Akọ iṣu ò dàbí ànàmọ́ lẹ́nu
Ewùrà náà ò fara jọ èsúrú.
Àwámárídìí niṣẹ́ Olúwa
Gbogbo iṣẹ́ ẹ rẹ̀ kò lábùjẹǹjẹkù nínú
Káábíèsí ọba A-ṣèkan-má-kù.
Ta lẹni tó le ṣàlàyé kó wá wi
Tí gbogbo ohun tó dá ò fi jọra wọn?
Ó dá mi lójú bí àdá
Kò sónítọ̀hún to le e sọ
Ó kọjá òye ọmọ adáríhurun.
Mélòó là ó kà léyín Adépèlé
Lohun tolu dá tí ó jọra wọn.
Nípa Òǹkọ̀wé
Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Ònítẹ̀bọmi(Baptist) Bódè Ìjàyè,Abẹ́òkúta. Lẹ́yìn náà ni ó tún tẹ̀síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ Líṣàbí Grammar School. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Àgbà Òṣíẹ̀lẹ̀,Abẹ́òkúta àti Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde.Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó fẹ́ràn láti máa kọ ewì àti ìtan àròkọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Ìfẹ́ rẹ̀ sí àṣà àti ìṣe Yorùbá kí ó má lè dìmẹ́ẹ́rí kò láfiwé.
Àṣẹ lórí àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Òǹkọ̀wé.