Ẹnìkan Ò Layé

Ẹni ayé ńṣe maràba fún ó sọ́ra fẹ́nu aráyé
Ẹ wí fún gbogbo molegòkè-molesọ̀ pé mo ní kí wọ́n rọra
Gbogbo ẹni tí ń pàkùrọ́ lójúgun ó ṣe pẹ̀lẹ́.
Ẹ wí fún wọn p'ọ́mọ aráyé le.
Bí wọ́n ṣèkà tán,
wọ́n á tún fìdárò bọnu.

E wí fún gbogbo bí ò sí èmi,
ọ̀rọ̀ ó rọ̀.
E wí fún gbogbo sọ̀yàsọ̀yà,
Ẹ wípé mo ní tán-n-an lópin
Ẹ wípé lọ́jọ́ ọjọ́ pé,
fúnra Fẹlá gan-an lóyọ ikú ẹ̀ lápò.

Ẹ wí fún àgbà òjẹ̀ nínú àwọn òṣìkà,
Ẹ wí fún náwónáwó tó da òṣìṣẹ́ ẹ̀ sóòrùn,
tí kò fún àwọn òsìsẹ́ lówó ọ̀yà wọn,
Ẹ wípé mo ní ìyà rẹ̀ ńbẹ lásùnara.

Ṣèbí ẹ mọ abírí?
Àbí ẹ mọ abìrì?
Àti abírí àti abìrì,
gbogbo wọn ló ti fi ayé pìtàn…
Wọ́n ti ń gbé ọ̀hún sọ̀hún.

Nítorí náà
Bí owó lo bání
Ilé ńlá ńlá lobá kọ́,
Ọkọ̀ loní lọ́pọ̀ tóbẹ̀,
ìmọ̀ ni àdáni wáyé fi jíìkí rẹ,
Ohun gbogbo tí o bá ní,
Rántí wípé tìrẹ nìkan
kọ́ ni gbogbo ayé jẹ́

Sùúrù Àti Ìrètí

Ìwọ ọ̀rẹ́ mi
"ṣebí tèmi" ìjà nídálẹ̀
Bí o bá fẹ́ sáré o sáré
Bí ó wù ẹ́ k'ofà,
yáa máa fi ẹ̀lẹ̀ fà
Má ṣe wo ago ẹlòmíràn ṣiṣẹ́
"Ẹgbẹ́ mi ń só, màá só"
olùwarẹ̀ ó sẹ̀gbọ̀nsẹ̀ ára
Ṣọ́ra!
Eré ṣíṣá léwu!

Ẹ ní mo wípé kí àgàn máṣe ronú mọ́
Ẹni ebi ńpa ó fiyè dénú.
Ẹni ègún ńlé ó máa rọ́jú
Bí ó ṣe ń rẹ ará ayé ló ń rẹ ará ọ̀run.
Ọmọ ńbọ̀ fẹ́ni ńwóyún
Ayọ̀ ńbọ̀ fẹ́ni ebi ńpa
Lẹ́yìn ìpọ́njú pẹ̀lú ìkorò,
ìdùnnú òun ayọ̀ ni yíò tẹ̀le

Ọládẹ̀jọ Hammed Ọ́. jẹ́ ọmọ bíbí Ifọ́n Ọ̀sun, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Fáṣitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀.

Àṣẹ lóri àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti HENRY J. DREWAL.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *