Agbẹ́kẹ̀lé Ènìyàn

Mo gbọ́ pé ayé wà
Mo múra èrò ìjìnlẹ̀
Mo rí i pẹ́dàá ń ráyé lò
Mo múra, ó di dúnníyàn
Mo wá dáyé ọ̀ún tán
Kàyéfì ló jẹ́ fún Akéwì

Gbogbo ì-gbé-ọkàn-lé ẹ̀dá láyé
Gbogbo ìfìmùlẹ̀ báni lò
Ojú ló wà
Inúu kálukú kanró kẹnkẹ

Àgbẹ́kẹ̀lé téwúrẹ́ ní
Ló jẹ́ ó dẹran ìjẹ lọ́wọ́ adáríhurun
Àgbẹ́kẹ̀lé tágùntàn bọ̀lọ̀jọ̀ ní
Ló jẹ́ ó padà ṣe ṣìnkín lẹ́ẹ̀kẹ́
Bẹ́ẹ̀ sì rèé
Èrò ‘ká gbàtọ́jú’ tó péye
Ni wọ́n fi gbẹ́kẹ̀lé olówó àwọn

Ifá Ẹlẹ́rìíìpín
Ọ̀rúnmìlà bàra Àgbọn-tí-ò-nírègún
Ifá ní ká sarí ká yé saàgùn
Ó ní ká saàgùn ká má sarí
Oògùn ló lọjọ́ kan ìpọ́njú
Orí ẹni ló lọjọ́ gbogbo
Gbẹ́ ọkàn lórí
Múra síṣẹ́, má ṣọ̀lẹ
N ó ṣe bí ìyá ò lè dà bí ìyá ènìyàn 
Màá ṣe bí baba kò lè dà bí ẹni ó bíni 
Má fọkàn tẹ ọ̀rẹ́ mọ́
Ọ̀rẹ́minú ò sí mọ́
Ẹni a lè rí bá rìn dọ́nà ló kù

Ìgbẹ́kẹ̀lé ẹ̀dá sẹ́dàá láyé
Asán ni
Òfò ni
Àdánù ni
Gbẹ́ ọkàn lórí
Fọkàn tẹ Ọba Wáídù
Òun lògbìgbà tí í gbaláìlẹ́nìkan

Ìbà Ọlọ́run
Ìbà Eníyán
Ìbà Èèyàn
Ìbà àwọn Olùkọ́ èmi 
Ìbà Orí-Àrán
Ẹ̀ṣọ́ ọmọ Ọlọ́tà Odò
Ìbà gbogbo Akéwì-Akọ̀wé lókè erùpẹ̀. 

Nípa Òǹkọ̀wé:

Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó,ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Nigeria Traditional Art and culture image:https://images.app.goo.gl/Df9m5CztisbXPHEA7

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *