Okùn Ìfẹ́ Yi!

Ìfẹ́ pọ́gbọ̀n, ó jọgbọ̀n
Ìfẹ̀ pégba, ó jugba 
Ìfẹ́ pérínwó, ó jurínwó

Ìfẹ́ẹ̀fẹ́ táyé fẹ́lá lóko
Kò ju kí wọ́n ríhun filá pa lẹ́nu
Ìfẹ́ẹ̀fẹ́ táyé fẹ́kàn lóko
Kò ju kí wọ́n ríhun fikàn jẹ létè

Ìfẹ́ tÓlú dá sáye
Ìfẹ́ tÉdùmàrè dá sí dúnníyàn
Àní ìfẹ́ tỌ́lọ́run fi sáàrin ọmọnìyàn
Kò kéré rárá, wàláì, kò wínrìn

Ìfẹ́ ńlá
Ìfẹ́ tó kàsíàrà
LOlú wò ṣùn-ùnṣùn
Tó fi sáàrin olùfẹ́ méjì bọ́mọọ̀yá
Adífá fún Wàhábù ọmọ Bákàrè
A bù fún Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín ọmọ Bákàrè 
Tí àwọ́n méjèèjì dì jọ ń ṣòwò ìfẹ́rìnpọ̀
Wàhábù ò fi Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín pa mìídìn
Ó ṣe tán láti fẹ́ ẹ láya
Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín náà sì rèé
Kò fìgbà kan jẹ́ Wàhábù ní ‘rárá’ 

Kò pẹ́
Kò jìnnà
Wàhábù gboko àdúrà lọ
Ni Wáídù bá ń fadùn sífẹ̀ẹ́ àwọn
Kò pẹ́ sí i
Kò jìnnà púpọ̀
Lòjò oyin bá ń sọlẹ̀ lẹ́ẹ̀dẹ̀ wọn
Ẹsẹ̀ tí wọ́n gbé, ijó ni wọ́n ń jó
Wọ́n ṣẹnu kótó mórin kọ
Ọpẹ́ yẹ wá Àláù a dúúpẹ́ 2x
Ẹni tí ò dúúpẹ́, ọwọ́ rẹ̀ ló wà
Ọpẹ́ yẹ wá Àláù a dúúpẹ́ 
Ṣèbí ohun a bá fẹ̀lẹ̀ mú ní í rọ̀! 
	Koko lohun afagbára mú ń le
	Orin ọpẹ́ ò ní wọ́n lẹ́ẹ̀kẹ́ àwa. 	
	
Òréré rẹ ló yẹjú, Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín
Ẹyẹlé ló yẹlé
Alábẹ̀kẹ́-Ọ̀kín tèmí yẹ mí láya
Aya bí iyèkan ẹni
Ìyàwó bí ọbàkan ẹni
Olólùfẹ́ bí olùkù ẹni
Aya ẹni ní í fIfá hanni
Bàbá ẹni kì í fIfá hanni
Ìyá ẹni kì í fIfá hanni
Ìyàwó nìkan ló lè fawo hànnìyàn
Ohun tí n bá ní
N óò máa bólólùfẹ́ mi jẹ…
Imú ló ni kóńbó
Àgbọ̀n ìsàlẹ̀ ló ni họ́ù-họ́ù
Èmí ló ní ọ́, Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín mi. 

Nípa Òǹkọ̀wé:

Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó,ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ tí love and culture, painting by Aurthor-Richard Iheanacho image: https://images.app.goo.gl/rPDqtyx73gQn2oui9

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *