ỌJÀ LAYÉ

ỌJÀ LAYÉ
Ọjà layé ọ̀rẹ́ mìi, 
Ọjà layé ará. 
Gbogbo ọmọ adáríhunrun pátá lówá nájà láyé, 
Dandan sì ni ká padà s'ílé e kóówa wa. 
Àkókò tàbí ìgbà tí a lò lọ́jà kọ́ni kókó, 
Bí kò ṣe wípé ohun tí a óò múbọ̀ ló ṣe pàtàkì. 
Gbogbo alágbára ayé è oooo, 
Ò báá rọra ṣe, 
Gbogbo aláṣe patá ò bá sorá fún àsìlò ipò. 
Gbogbo sìkàsìkà ayé, ìbá dára kí ẹ rántí ọjọ̀atìsùn!
Ọ̀tafà s'ókè tó y'ídóborí,
B'ọ́ba ayé ò rí ọ t’ọ̀run-ún wò ọ́!
Ẹní gbébù ìkà láyé 
tọmọtìran rẹ̀ ni yóò jẹ níbẹ̀. 
Ẹní tajà erùpẹ̀ láyé
 Dandan ni yóó gbowó òkúta!
Ọjà layé ọ̀rẹ́ mìi
Dandan ni kí á darí wálé. 
B’ọ́kọ̀ róòkun tó r’ọ̀sà,
Á forí félèbúté.
Ọmọ ènìyàn, ọmọ ádámọ̀
Ẹ bà jíá rántí ọjọ́ àtisùn!
Ẹ bà jíá rántí iṣẹ́ tí ń fọhùn lẹ́yìn ikú. 
Ọmọ ènìyàn, ò bá ṣe pẹ̀lẹ́, 
Ọmọ ádámọ̀, ò bá simẹ̀dọ̀
Nítorí ádà-ádà ayé yìí ò da ǹkankan. 
Ọjà layé ọ̀rẹ́ mìi, 
Ọjà layé ará. 
Ọ̀run nilé e gbogbo mùtúmùwà. 

ỌJỌ́

ỌJỌ́
Onírurú ọjọ́ ní ń bẹ ọ̀rẹ́, 
Onírurú ìgbà ní ń bẹ nínú ọjọ́. 
Ọjọ́ òní, 
Ọjọ́ ọ̀la, 
Ọjọ́ ọ wájú. 
Ṣebí gbogbo ènìyàn
Ní má ń gbàdúrà wipe
K’ọ́jọ́ òní wa ó dára
K’ọ́jọ́ alẹ́ wa ó suwọ̀n. 
Ọ̀tọ̀ lọjọ́ ayọ̀ òun ìdùnnú, 
Tí gbogbo ẹ̀dá a máa nífẹ̀síí bí èkùrọ́ ti ń gbádùn ẹ̀wà. 
Ọ̀tọ̀ lọjọ́ ibi òun ìbànújẹ́, 
Tí a kìí fẹ́ láti rí tàbí mọ̀. 
Ọ̀tọ lọjọ́ a bíni sayé, 
Tí gbogbo ẹ̀dá adáríhurun a máa
Kí òbí ẹni kú oríire. 
Ọ̀tọ̀ lọjọ́ ikú, 
Ọjọ́ tí kò mọ ènìyàn kúkurú
Ọjọ́ tí kò mọ ènìyàn gígùn
Kò mọ olówó bẹ́ẹ̀ni kò mọ tálákà
Gbogbo wa la dágbádá ikú
Ọjọ́ a gbekọ́rùn la ò mọ̀!
Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, 
Ìgbà ń gorí ìgbà. 
Bí gbogbo ẹ̀dá ti ń gbèrò àti ṣerere láyé, 
Bẹ́ẹ̀, éníyán àti ajoogun ń pòsi lójojúmọ́
Ọjọ́ wo gangan-an!
Lọmọ ẹ̀dá yóò bọ́, 
lọwọ́ àwòn éníyán àti ajoogun wọ̀nyí?
Àfi káyaa képe elédùà, 
Ọba tó ni gbogbo ọjọ́ lọ́dọ̀
Ọba ńlá tí gbogbo àkóso ọjọ́ ń bẹ ní ìkáwọ́ ọ rẹ̀. 
Kójẹ́ a r’áyé gbé
Kójẹ́ á r'ígbà lò
Kọ́jọ́ ayé wa ó suwọ̀n. 

Nípa Òǹkọ̀wé:

Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a bí ní ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Nigeria art culture image:https://jiji-blog.com/2018/01/nigerian-art-culture-nations-heritage/

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *