Ìwé Le!

Túlẹ̀, ẹ sáré wá
Akẹ́kọ̀ọ́, ẹ wá gbọ́ nàsíà
Òkun kì í hó ruru
Ká wà á ruru, àwé!

Ìwé le lorin tí wọ́n ń kọ
Akẹ́kọ̀ọ́ fìwé wójú ẹja
Wọn ò forúnkún tẹ̀pá ìrònú
Wọ́n ń fìwé àwọn dápọ̀ṣìn

Túlẹ̀ sọ Olú-ẹ̀kọ́ àwọn dọ̀tá àìjírí
Wọ́n sọmíi Tíṣà dọ̀tá ojú láàtàn
Wọ́n ò pe làákàyè rán níṣẹ́ rí
Kí wọ́n lè fìwé náà gba Kúdí inú àpò

“Ìwé le” lakẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ ń kọ lórin
“Ìwé le” lakẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ ń fọ̀ lóhùn
Mebí ẹ tilẹ̀ rọ́gọ̀ọ̀rọ̀ tó tibi ẹ̀kọ́ ìwé dỌ̀mọ̀wé? 
Àbí ẹ ò rómilẹgbẹ Kòfẹ́sọ̀ láṣùwàdà náà?

Ẹni ó bá kàwé lákàyé láìṣe iyè méjì
Irú wọn ní í ráwo ìwé jinlẹ̀ 
Bí túlẹ̀ bá sọ̀wé kíkà daṣọ ìbora 
Tí wọ́n fi í bora àwọn nígbàdéègbà
Wọn á máa fẹran ẹ̀kọ́ ìwé jẹ̀kọ lákọ̀tun

Akẹ́kọ̀ọ́ ò fẹ́ṣẹ́ẹ́ ṣe mọ́
Túlẹ̀ ò fẹ́wèé kà
Owó ni kóówá wọn ń lé kiri ní pópó
Ọ̀nà àtilà lóòjọ́ ni wọ́n ń tọ̀ nírònà
ÀìfÓlùkọ́ wọn dénú jindò
Tún fàdí kíwèé ọ̀ún le bí ojú ẹja

Ẹ kàwé lákàlà pẹ̀lú akitiyan
Ẹ gbájú mẹ́kọ̀ọ́ ìwé, kò kúkú le
Ẹ fetí sẹ́kọ̀ọ́, ó rọ̀ ju ẹ̀kọ
Ẹ nífẹ̀ẹ́ sÓlùkọ́, olú ìmọ̀ ni wọ́n
Pẹ̀lẹ́kùtù ni kí ẹ fi bá àwọn lò
Igbá pẹ̀lẹ́ kì í kúkú fọ́
Àwo pẹ̀lẹ́ kì í fàya pẹrẹngẹdẹ.

Nípa Òǹkọ̀wé:

Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó, ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ tí The Guardian Conscience:https://guardian.ng/guardian-woman/help-your-child-form-the-reading-habit/

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *