Àyàjọ́ Falẹ!

À ń gbòròmọdiẹ lọ́wọ́ ikú
Tonídìí ní í dà nígbẹ̀yìn bídìí bàjẹ́

Ó tún ti ṣẹ̀ bó ti ń sẹ̀
Ó tún ti bọ̀ bí ìṣe rẹ̀
Emi la fẹ́ sọ fádití ikún ọmọ
Péwọ̀n là á jẹ lọ́gẹ̀dẹ̀ tó pọ́n? 
Kín ló kan lèmọ́mù níbi ajá tó síwín kú?

Falẹ!
Àlejò tí í wọ̀lú nígbàkan lọ́dún
Kó tó dé layé ti ń gbòǹgbẹ rẹ̀
Bó wọ̀lú, á ṣèlú yìndìnyindin
Gbogbo aráyé a yófẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn
Ọmọ ọ̀ràn tí ń kó póńpó lùyá
Falẹ tí ń múnú akọ dùn sábo
Gẹ́rẹ́ tó bá wọ̀lú, ìlú á dùn
Bó bá kẹ́rù, tó lọ tán
Ìlú á bẹ̀rẹ̀ ìrònú tí ò wínrìn
Ǹjẹ́ kín ló pàdí ìrònú?
Kín ló mómilẹgbẹ ọ̀dọ́bìnrin ń ronú? 
Èéṣe tádélébọ̀ fi í ṣẹ́tọ́ lẹ́nu bí ìgbín?
Akọ ń ronú lórí ohun tí ò ṣe é fọ̀

Falẹ!
Àyájọ́ tákọ ń fabẹ́rẹ́ gẹ́lẹ̀
Ọjọ́ tábo ń tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ fákọ́ tẹ̀
Álọ́ọ́mù tán nílé òǹtà
Wọ́n fọjú-òpó tó pẹ́ tó ti ṣítè kalẹ̀
Wọn á wá ṣeré délé akọ́ aláìgbọ́n
Ìyàwó ń bẹ nílé tó ń sunkún òtútù
Ọkọ ń bẹ lọ́ọ̀dẹ̀ tó ń ṣòjòjò àìrígùn
Aya yún tán, ó ń sún mọ́kọ
Ó fẹ́ gbọ́mọ Ọbà fỌ́ṣun kọ́un?

Ẹ ṣọ́ra!
Ẹ wòye ohun falẹtáìn kó sínú wọ̀lú
Kẹ tó ṣàrìnkò àlejò gogoro
Tí n donílé sírònú bó jáde nílùú.

Nípa Òǹkọ̀wé:

Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó, ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá.

Àwòràn ojú ìwé yìí jẹ́ ti Guardians image:https://cdn.vanguardngr.com/wp-content/uploads/2011/07/sex.jpg

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *