Agbẹ́kẹ̀lé Ènìyàn
Mo gbọ́ pé ayé wà Mo múra èrò ìjìnlẹ̀ Mo rí i pẹ́dàá ń ráyé lò Mo múra, ó di dúnníyàn Mo wá dáyé ọ̀ún tán Kàyéfì ló jẹ́ fún Akéwì Gbogbo ì-gbé-ọkàn-lé ẹ̀dá láyé Gbogbo ìfìmùlẹ̀ báni lò Ojú ló wà Inúu kálukú kanró kẹnkẹ Àgbẹ́kẹ̀lé téwúrẹ́ ní Ló jẹ́ ó dẹran ìjẹ lọ́wọ́ adáríhurun Àgbẹ́kẹ̀lé tágùntàn bọ̀lọ̀jọ̀ ní Ló jẹ́ ó padà ṣe ṣìnkín lẹ́ẹ̀kẹ́ Bẹ́ẹ̀ sì rèé Èrò ‘ká gbàtọ́jú’ tó péye Ni wọ́n fi gbẹ́kẹ̀lé olówó àwọn Ifá Ẹlẹ́rìíìpín Ọ̀rúnmìlà bàra Àgbọn-tí-ò-nírègún Ifá ní ká sarí ká yé saàgùn Ó ní ká saàgùn ká má sarí Oògùn ló lọjọ́ kan ìpọ́njú Orí ẹni ló lọjọ́ gbogbo Gbẹ́ ọkàn lórí Múra síṣẹ́, má ṣọ̀lẹ N ó ṣe bí ìyá ò lè dà bí ìyá ènìyàn Màá ṣe bí baba kò lè dà bí ẹni ó bíni Má fọkàn tẹ ọ̀rẹ́ mọ́ Ọ̀rẹ́minú ò sí mọ́ Ẹni a lè rí bá rìn dọ́nà ló kù Ìgbẹ́kẹ̀lé ẹ̀dá sẹ́dàá láyé Asán ni Òfò ni Àdánù ni Gbẹ́ ọkàn lórí Fọkàn tẹ Ọba Wáídù Òun lògbìgbà tí í gbaláìlẹ́nìkan Ìbà Ọlọ́run Ìbà Eníyán Ìbà Èèyàn Ìbà àwọn Olùkọ́ èmi Ìbà Orí-Àrán Ẹ̀ṣọ́ ọmọ Ọlọ́tà Odò Ìbà gbogbo Akéwì-Akọ̀wé lókè erùpẹ̀.
Nípa Òǹkọ̀wé:
Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó,ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá.
Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Nigeria Traditional Art and culture image:https://images.app.goo.gl/Df9m5CztisbXPHEA7