Ọ̀nà tí ó yá jù láti dá'ná sun ara ẹni
Ni nípa fifi iná sí ilé ẹni.
Òlùkọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì mi ló sọ wípé,
Kí o tó kọ́ èdè òyìnbó tó lọ geere,
Ronú bíipé o ti di ọ̀kan.

Zakiyya n j'ókòó si fàréndà ilé rẹ̀ l'ójoojúmọ́,
Tí ó sì ń fọ àwọn èdè àìmọ̀,
Ó mú lẹ́tà bàbá rẹ wá sí pénpé imú rẹ̀,
Láti gbóòórùn ilé kúrò l'ara rẹ̀.

Ti ìṣáájú tí bàbá rẹ kọ, ó ń bií
keifa asbahti*
Ojúmọ́ kan, wàhálà kan,
Lọ́ ahọ́n rẹ báyìí, díẹ̀,
Jẹ́ kí irun rẹ gùn síi,
Bí wọ́n ti ń ṣe níbí nìyẹn.

Ọ̀kùnrin géndé mẹ́ta wọnú ìyẹ̀wù ní alẹ́ ọjọ́kan,
Ọjọ́kiní ànà, kò le sọ̀rọ̀ láti dá àwọn ọkùnrin géndé mẹ́ta yìí dúró,
Èdè yìí lọ́ọ l'áhọ́n,
Gẹ́gẹ́ bí ìfipábánilòpọ̀ wọn ṣe múu gbàgbé orúkọ rẹ̀.

Ojúmọ́ kan, wàhálà kan,
Eléyìí ni ìṣe gbogbo ẹni tí ń bá
Wá ilé
L’ájò.


* Oò jíirebí?

Nípa Òngbifọ̀

A bí Ọ̀gbẹ́ni Adépọ̀jù Isaiah Gbénga ni ọdún 2003 ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó wà lára àwọn òǹkọ̀wé tó kópa ninu idije Africa Writers’ Award ti odun 2020. Ó jẹ́ olóòtú ní Writers Global Movement.

Nípa Òǹkọ̀wé

A bí Ọlájùwọ́n Abdullah Adédòkun ní ọdún 2004, olùgbé ìlú Èkó. Ó fẹ́ràn láti máa kọ nípa ọkàn tí ìdí kan tàbí òmíràn ti túpalẹ̀ pátápátá, tàbí àwoọn tí ilé wọn ti farasin sí ìbòjí wọn. Arákùnrin yìí ló gbé igbá orókè ti ìdíje Rusted Radishes Beirut Arts And Journal láti ilú Lebanon. Àwon ewì àti ìtàn rẹ̀ ti farahàn ní oríṣiríṣi àtẹ̀jáde ìwé ìròyìn àti àwọn àtẹ̀jáde tí ó máa ń gba iṣẹ́ lítírésọ̀.

Finding Home In Loneliness | Olajuwon Abdullah Adedokun

the fastest way to set yourself on fire
is by lighting your home.
my english teacher says,
before you learn british accent, imagine you're one.

zakiyya sits on her veranda every day,
munching strange languages,
she brings her father's letters to her nose,
to smell home off it

In the last one he had written
keifa asbahti*
every day begins with a new war,
twist your tongue this way, a little bit,
your hair should be longer,
they do that here.

three men walk into her room in one night,
the other day, she does not know enough words
to tell them to stop, this language hurts her
tongue the way their thrusts bury her name

every day begins with a new war,
It's the way of those who
find home
away from home

*How did you wake up?

[anchor_episodes]

Àwòran ojú ìwé yìí jẹ́ ti Asim Abu Shakra

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *