Kò sí ẹnì kankan tí kò mọ Ìyá àgbà ní abàá Alẹ́mọ́, kìí sọ ìtàn kan ní ẹ̀ẹ̀mejì. Àgbà òpìtàn sì ni pẹ̀lú. Kò fẹ́ ẹ sí ẹnì kan tí ó mọ ìtàn tóo nínú abá Alẹ́mọ́ jí ìgbà yìí. Bí ó bá ti dí alẹ́, gbogbo ènìyàn yíò kó jọ sí gbàgede ìyá àgbà láti gbọ́ ìtàn tuntun.

Gbogbo ará àbá tí ń retí ìyá gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ fún eré òṣùpá, bẹ́ẹ̀ ni t’ọmọdé-t’àgbà ti pé sí gbàgede láti wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹnu ìyá Ajírọtútù. Ìyá ti bọ́ sí  itá, ó sì jókòó. Ń lo bá bẹ̀rẹ̀.

Ìyá Àgbà: Ẹyin ọmọ mi ẹ mọ̀n kaalẹ́ ó.

Gbogbo ará ìlú: Ẹ kalẹ ìyá àgbà.

Ìyá Àgbà: A kú eré òṣùpá òní ó.

Gbogbo ará ìlú: ooo.

Ìyá Àgbà: Mo fẹ́ sọ ìtàn ńlá kan fúnyin loni, ṣé ẹ ṣe tán?

Gbogbo ará ìlú: bẹẹni, àti ṣe tán.

Ìyá Àgbà: Ìtàn mi dá lé orí ọmọkùnrin kan tí ń jẹ́ Inúlayẹ́wà ọkọ Mọnbe. Inúlayẹ́wà jẹ́ ọmọ gbajúmọ̀. Bàbá rẹ̀ ní owó tí àgbàná kò lé wọ̀. Ó ní oko bi ilẹ̀ bí ẹní. Àwọn ìwọ̀fà oko rẹ kò ní òǹkà. Bákan náà, Inúlayéwà náà sì gbajúmọ̀. Ó ní oko ó ní ìwọ̀fà pẹ̀lú . Àmọ́ ọmùtí paraku ni ọmọkùnrin tí a ń wí yìí. Kii mú omi àfi ọtí. Kódà kìí wẹ̀ bíò ta ọtí sí omi ìwẹ̀. Ní kúkúrú èdè, kìí se nkankan lai fi ‘tọti ṣe. Aṣọ aláràmbarà tí ó bá wọ̀ lọ́jọ́ kan kọ́ ni yóò wọ̀ lọ́jọ́ kejì, nítorípé ọtí yóò tí mù ún dódó, alámu-dàsára ní. Nítorípé òun ni àkọ́bí kùnrin bàbá rẹ̀, ó fi ọkàn sí ogún bàbá rẹ̀ púpọ̀ to bẹ́ẹ̀ gẹ̀ẹ́ tí ó fi sọ ní gbàgede fàájì pé ‘ọjọ́ tí bàbá mi bá ṣí’pò, n ó ta gbogbo oko mi mú ọtí ni ọjọ́ náà. Kìí sìi sọ̀rọ̀ kó má ṣe bẹ́ẹ̀.

Ní ọjọ́ kan, bàbá rẹ̀ pè é sí ìyẹ̀wù, láti bá a sọ ọ̀rọ̀. Bàbá kọ́kọ́ pèé ni ẹ̀ẹ̀mẹ́tá. Ó sì dáhùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọtí fàájì tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sì ń rùn lẹ́nu rẹ.

‘Ṣé ó mọ̀ pé ìwọ ni dáodù ẹbí mi? Ojú ń tìmí fún gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ tí mo ń gbọ́ ní ìgboro. Bí iná kú á kú eérú, bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá sì re ìwàlẹ̀àsà, a fi ọmọ rọ́’pò.  Ó sì mọ pé ìwọ ni yóò kù bí mo bá lọ tán. Ogún ti mo ní ìwọ àti àwọn yókù rẹ ń lẹ ni. Mo ti gbọ́ gbogbo àrà tí ó ń dá ní inú ìlú. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé, bí iṣu ẹni bá ta, a ó dà ọwọ bò ó jẹ́ ni. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí wọn ń kì ọ́ ni mẹsan-mẹwa ni wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ tí ó bá dá wai. Fi ayé ọtí mímú silẹ kí ó sì gbá ojú mọ oko àti òwò tí mo kọ́ ọ. Ogún mi kìí ṣé tìrẹ nì kan.’

Mo ṣe bí, ààbọ̀ ọ̀rọ̀ tí ọmọlúwàbí ní nínú ni yóò kún àbọ̀ míràn tíi fií d’odidi. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí bàbá rẹ̀ sọ àfi bi pé ó ń yín àgbàdo sí ẹyin igbá ni. Ẹyin etí Inúlayéwa ni ó ń bọ sí.

Laipe láìjìnnà, bàbá rẹ̀ fánrú. Kàkà kí Inúlayéwà ó sé ìdárò bàbá rẹ̀, níí ṣe ló wọ ilé mú aṣọ, ló bá ré ìdí ẹmu. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá bíi ni ọ̀rọ̀ pe;’ kini ọ ṣe loni tí bàbá rẹ kú? Kàkà ki o fọ èsì nise ló gba ìhà ẹmu méjì, ó mú tán ó sì fi owó ra ikùn ló bá sọ̀rọ̀ pé `kini mo ṣe ń ná?’ wọn dáa lóhùn pé ó mu ẹmu. ‘ṣe ẹri, ìhà méjì tí mo mú ń, akèrègbè méjì-méjì ló túmò sí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ mẹ́rìndínlógún tí ń ó sìnku baba mi’.

Ṣe lóòótọ́, ohun a bá mọ laa polówó, ohun Inúlayẹ́wà mọ ló sọ fún mùtúmùwà, àtipé ọ̀rọ̀ rẹ kò gbọ́dọ̀ yẹ̀. Ó béèrè pé taani òní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ti o le fi ra oko òun. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tí ó ní irú owó bẹ́ẹ̀ rárá nínú àwọn tí wọn ń bẹ ní ibẹ̀.

Àmọ́, kàkà kí eku má jẹ́ ṣèsé, a ó fi ṣa ẹ̀wà ẹ dànu ni. Ní ṣe ló bá ní kí ìyá ẹlẹ́mù ó máa ta ẹmu fún àwọn ènìyàn. Òsì ṣe àdéhùn pé kí oko ohun ó jẹ ti Ẹlẹmu tí tí ìgbà tí ohun yio fi tú àpò owó bàbà ohun. Ọ̀rọ̀ yìí ti tán ká gbogbo abà àti ìlú yíká. Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ si mú ẹmu lọ́ fẹ́ lófò.

Ọjọ́ pé, Inúlayéwà ọkọ Mọmbé sìnkú bàbá rẹ̀ gọ́ńgọ́ sọ́, kutupu sì hú, ìlú ya, bàtà já kódà ilẹ̀kẹ̀ ré fún ijó jíjó. Gbogbo abá àti àgbègbè ń lo mọ pé Inúlayéwà sin bàbá rẹ̀. Òfò sì ṣe owó ni ọjọ́ náà. Àwọn tálákà fi ìka há ẹnu, àwọn olówò ẹgbẹ́ bàbá rẹ̀ kan sáárá pẹ̀lú.

Mo ṣe bí, ń tíì tán lọdún eégún. Inúlayéwà tí se ayẹyẹ tán, ó kú bí yio se san owó kí ó lè sí kà àdéhùn, kí ó sì gba oko rẹ̀ padà lọ́wọ́ ìyá Ẹlẹmu. Ó wọ ìyẹ̀wù bàbá rẹ̀ lọ, ó lọ ìdí  posi owó, ó sì tú terin toyàyà, ṣùgbọ́n akèrègbè, aṣọ àti ìwé pélébé ń ni ó bá ní ibè. Èyí jẹ́ ìyàlẹ́nu. Ó tú ìwé ọ̀hún, ó sì kà á pe;

‘Abamọ̀ ló jẹ́ pé mo sọ ọ́ lórúkọ, àmọ́ ó kò mú lò. Inúlayéwà túmọ̀ sí; ọgbọ́n ni a fí ń lo ayé. Èrò rẹ ni ohun tí yóò là ọ́ láyé, òhun ní yóò sọ ọ́ di ènìyàn àtàtà. Àmọ́ sá, mo tí ta gbogbo dúkìá mi. Àwọn àbúrò rẹ tí gba ìpín tí wọn. Ìpín tí rẹ ni lẹ́tà yìí. Kí ó má dà bí ẹnipe ń kò fí ńkan kalẹ̀ ni mo fi ra akèrègbè ẹmu yìí fún ọ, bóyá bí o bá ń mu-ún, ó ronú ohun tí ó fi oko rẹ ṣe.’

Báyìí ni Inúlayéwà fi idi jalẹ̀, ó sì kú fín-ín fín-ín. Àwọn àgbà bọ̀ wọn ní ‘bí ayé ń yẹ ọ́ kio rọra ṣe’. Inúlayéwà ọkọ Mọmbé ni agbójúlógún tí ó fi ara rẹ̀ fóṣì ta. Oko rẹ̀ dí tí Ẹlẹmu leyin ikú rẹ̀. Àwọn ọrẹ rẹ kò sí fí ìdí ẹmu sílẹ̀ lẹyin ikú rẹ ni igba kọ̀ọ̀kan. Wọ́n a kàn máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe àríkọ́gbọ́n láàrin ara wọn ní tí wọn ba ń mu ọtí.

Ni’ hìn ni mo rí mọ fún ìtàn tòní. Àmọ́ bo ba jẹ́ pé irọ́ ni mo pa pẹ̀lú ìtàn yìí, kí àbọ̀ ẹnu mi ó má ròó ‘tó’ lẹẹ̀mẹta. Ìyá sì ta àbọ̀ ẹnu rẹ, ó ro ‘tó tó tó.’

Gbogbo ẹ̀kọ́ tí ẹ kọ́ loni, ewé-ìran yóò jẹ́ kí ẹ rántí ó.

Tẹ̀tẹ̀ loni ko tẹ̀ mọ yín lọ́kàn

Bí akùkọ́-dìye bá gbọn ìyẹ́ rẹ pìpì, á rántí kíni rẹ àná.

Ologin-nin gín-nín ẹyẹ ayé ò ní sá lọ́kàn yín o.

Gbogbo àwọn ènìyàn: àṣẹ ooo.

Báyìí ni ìyá juwọ́ tí ó sì wọlé lọ. Ó tún di òṣùpá miran kí wọn ó to pàdé. Gbogbo ará aba gba ilé wọn lọ.

Lanase Hussein jẹ́ ọmọ bibi ilẹ̀ Ìbàdàn, ní agbègbè Aremọ Ọ́ja’agbo. Ó k’ẹ́kọ̀́ èdè gẹ̀ẹ́sì ni ilé ẹ̀kọ́ Fáfitì Ìbàdàn. Ó jẹ́ Òǹkọ̀wé, akéwì àti olùkọ́ni ní gẹ̀ẹ́sì àti lítírésọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ni ilé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì.

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *