ỌMỌ ÒRUKÀN

Ikọ́ wíwú ológìnní kìí ṣàfiṣe
Ìran baba wọn níí wúkọ́ fee.
Gbígbó ajá kì í kúkú pajá.
Ìran wọn ló ní gbígbó.
A ti mọ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́.

Bẹ́yẹ akéwì bá ń ké lórùlé
Kìí ṣe pé ó ń ṣàdédé pàátó
Ó lóhun tó fẹ́ káyé ó gbọ́ ní.
Ìbí kò jù bí alára mo ní
Bí a ṣe bẹ́rú ń là bọ́mọ.

Ìwọ tó o lọ́mọ tí wọn ní kó mójú tó
Nítorí òbí i rẹ̀ tí ò sí mọ́
Kò kúkú dùn mẹ́ni tó fọmọ rẹ̀ sílẹ̀.
Rántí ìlérí tó o ṣe fún gbogbo ẹbí
Pé kí wọ́n ó má ṣèyọnu.

Pé jíjẹ mímú rẹ̀ kò ní nira
Lílọ sílé ẹ̀kọ́ àbí ibi iṣẹ́ rẹ̀ ó ní posé.
Kí ló wá dé tọ́rọ̀ wá dolóbírìpo
Tí ẹ ò ṣohun ẹ fọ̀ létè?
Ẹ fitọ́ dúdú sínú,ẹ ń tú funfun síta.

Ohun ojú ọmọ òrukàn ń rí gọntíọ!
Ìrírí ọmọ òrukàn lékenkà!
Ẹ rántí pébi òbí wọn lọ́
Kò ṣẹ́ni tí ò ní re'bẹ̀ bo ba yá.
Ǹ jẹ́ irú oúnjẹ tiyín ló ń jẹ?

Ṣe irú aṣọ tọ́mọ yín ń wọ̀ ni ń wọ?
Ikú tó pàlàpà ló sọ ọ́ dàmúgùn féwúrẹ́.
Ebi ojoojúmọ́ tí ẹ fi ń pa á
Ló sọ ọ́ dẹni tí ń fẹ́wọ́.
Ẹ ní torí ó ń fẹ́wọ́ ẹ fọ̀bẹ gbóná jó ó lára.

Ẹ ní torí ò ṣohun tí ẹ ní kó ṣe
N lẹ ṣe domi gbígbóná sí i lára
Ẹ sọ di ṣàkì àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Bó bá jọ́mọ tó o bi o ha le gbà bẹ́ẹ̀?

Ọmọ ọlọ́mọ lẹ̀yin fi ń kẹ́ tiyín.
Ó dà mí lójú ọjọ́ ìdájọ́ kù sí dẹ̀dẹ̀.
Ẹ̀ bá tètè jáwọ́ kí ẹ túúbá
Nítorí bíjọba bá mú un yín
Ẹ ó mọ̀ pé ẹ ti forí jalè agbọ́n.

Ẹ jẹ́ ká ṣe rere sáwọn tí ń bẹ lábẹ́ wa
Akéwì ń fewì í ṣe ìkìlọ̀ ẹ tẹ́tí
Tó o bá fárí ga tó o jáwọ́
Gọ̀gọ̀ tí ń kábì tí ń káwùsá
Ọjọ́ kan ni yóò ya.

Ìwọ tó o jẹ́ alágbàtọ́ ṣe mẹ̀dọ̀
Má rán ọmọ ọlọ́mọ níṣẹ́ dé tòrutòru.
Ọmọ tí ẹ fojú tẹ́ńbẹ́lú
Pé kò lè rọ́wọ́ họrí ni dúníyàn
Kúkú le dirú digba.

Má foró yaró ìwọ ìyá
Má sọ pé ó fẹ́ gbẹ̀san.
Ìwà tí wọn hu sí ọ ní màjẹ̀sín.
Tó bá jẹ́ sábábi rè é
Tí ó fi di Ẹfúnṣetán Aníwúrà.

Tó bá jẹ́ èrèdí rè é
Tí ó fi dàgékù ejò ìwọ bàbá.
Ọjọ́ ó bá dọ́kọ délé dánímọ́
Lo ó mọ̀ pé o ti wọ gàù.
Pé ó ti kan roro nírù.

Gbogbo ẹni ba lọmọ òrukàn lọ́dọ̀
Ká ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn ló dára
Kí wọ́n ba lè kọrin ire kì wá
Bi wọn bá yọrí lọ́jọ́ iwájú.
Èdùmàrè jẹ́ ká dàgbà ká dògbó.

Káwọn ọmọ wa má dọmọ ọlọ́mọ.
Ṣóhun làwá ń bẹ̀bẹ̀.

Ẹ JẸ́ KÍ N WÍ

Ẹ jẹ́ kí n wí 
Wíwí ni tẹyẹ òwìwí
Ẹnìkan kìí pohùn mówìwí lẹ́nu
Wọn láwọn ó ṣèlú
Wọ́n jẹ ẹ́ lájẹ dálu.

Ẹ jẹ́ kí n wí
Wíwí ni tẹyẹ àwòkò
Ọ̀rọ̀ kò ní gbénú mi rà bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀
Wọn láwọn ó tòlú gẹ́gẹ́
Ṣe nìlú dorí kodò bí àdán.

Ẹ jẹ́ kí n wí
Ìbákà ló làròyé
Ẹnìkan kìí torí àròyé pẹyẹ
Wọ́n láwọn ó pàdí òkòtó dà
Ṣe ni wọ́n fọ́díí òkòtó yányán.

Ẹ jẹ́ kí n wí
Kíkan là mọ̀ mágbò
Kíkan ó lè pàgbò láé
Wọ́n láwọn ó pèsè iṣẹ́
Ìṣẹ́ ni wọn taari sọ́pọ̀.

Ẹ jẹ́ kí n wí
Wíwí ni tẹyẹ ẹ̀gà
Ẹnìkan ò lè pohùn mẹ́gà lẹ́nu
Wọ́n láwọn ó pèsè ààbò
A sùn,a ò le è hanrun.

Ẹ jẹ́ kí n wí
Ọba kìí m'Ákọrin
Àfìgbà tí wọ́n sún wa pa
Adìẹ ọlọ́mọ lọmọ ilẹ̀ yìí dà
Mùtúmùwà doníkanran poo!

Ẹ jẹ́ kí n wí
Wíwí ni tẹyẹ èlúlùú
Ìgbà wo là ó bẹ̀rẹ̀ ìgbádùn?
Tà o ni ṣiṣẹ́ erin

Máa wá jẹ̀jẹ èlírí mọ́?

Nípa Òǹkọ̀wé

Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Baptist Primary School, Bódè Ìjàyè,Abẹ́òkúta.Lẹ́yìn náà ni ó tún tẹ̀síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ Líṣàbí Grammar School,Ìdí Aba. 
Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Èdè Yorùbá àti Haúsá ní ilé ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Àgbà Federal College of Education,Òṣíẹ̀lẹ̀,Abẹ́òkúta. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín,Ìjagun,Ìjẹ̀bú Òde .Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ilé ẹ̀kọ́ girama ni. Ó fẹ́ràn láti máa kọ ewì àti ìtan àròkọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Ìfẹ́ rẹ̀ sí àṣà àti ìṣe Yorùbá kí ó má lè dìmẹ́ẹ́rí kò láfiwé. 

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Fleance Forkuo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *