À ṣé àwọn tí wọn ń pé Àlàmú l’Ájá kò sọ àsọrégè rárá. Bí ó tí lẹ̀ jẹ́ pé àbísọ rẹ̀ ni nítorípé àbíkú ni. Àlàmú jẹ́ ọmọ kan tí gbogbo abà má ń bẹ̀rù láti kò lọ́nà ní ibikíbi tí ko báà wù kó jẹ nínú ìlú. Bí ènìyàn bá kòó lọ́nà ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, a fi kí óluwa rẹ̀ ó tún oorun òwúrọ̀ ọjọ́ náà sún, kódà àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì kò rí bíi ọmọ-ìdùnnú rárá. Bó tilẹ ̀jẹ́pé oun ni dáódù ilé Alárèré, pàápàá jù lọ ọ̀kánlàwọ́n ilé náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni gbogbo ilé yio ti r’oko r’odò kí ó tó ji. Ìyá rẹ̀ kii fẹ́ kí ọwọ kàn-án, tàbí kí ẹnu kùn-ún rárá. Ẹni tí ó bá dá irú rẹ̀ láṣà, yio gbọ́ torí rẹ̀ lọ́jọ́ náà. Kìí kúkú ṣe pé Àyìnkẹ́ ìyá rẹ̀ náà bí kan tán ó pàdímọ́, elédùmarè ni kò fi òmíràn jínkii rẹ̀.

Ayé tí mọ̀ pé kìí kú r’oko kìí yẹ̀nà, kò k’ewu kò k’àwé,  àyàfi ki ó jí kó jẹun kó sì wọ abá lọ́ láti fín iná ọ̀ràn wá ilé fún àwọn òbí rẹ. Kò ní oníbàwí kankan bí ó tilẹ̀ wù kí ó mọ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó ti ṣe jàmbá fún àwọn ará ìlú, tí ìyá rẹ̀ yio fárígá pé ọmọ òun kọ́. Bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá rẹ̀ tí dọ̀bálẹ̀ ni Ilé-baálẹ̀. Ṣùgbọ́n, kàkà kí ewé agbọ́n rẹ̀ ó dẹ̀, ó tún ń le si ni.

Kò l’ọ́rẹ́. Kànnàkànnà-atọwọ́dá rẹ̀ ní wọ́n jijọ máa ń rìn. Ajá rẹ̀ kii sìí lọ kí kolokolo rẹ̀ ó gbélẹ̀. Ìyá rẹ tíi máa gbè lẹyìn rẹ náà f’ara káàṣà kànnàkànnà yìí lọ́jọ́ tí ìyá rẹ báa wí tí kò sì fún ní oúnjẹ. Ní ṣe ló ta á ní òkò kí ó tó o sá kúrò ní ilé lọ́jọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ gẹlẹ ló ṣe fún bàbá rẹ̀ ní ìgbà tí Bàbá báawí fún tí àlùmọ́gàjí rẹ tí Àlàmú jùnù ni ìyálẹ̀ta ọjọ́ kan. Kànnàkànnà yìí Káná-àn ló kóo sì yọú-yọú lọ́jọ́ kan náà. Ẹni tí a kò bá pè l’ọrẹ rẹ̀ kan ṣoṣo ló fi òkò fọ́ lori nibi ti wọn ti jọ ń ju òkò mọ́ àgbálùmọ́.

Àkàndé lórúkọ ọrẹ́ rẹ̀ yìí ǹjẹ́. Ọwọ́ Akande sì sùn púpò, laì lo kànnàkànnà, a sì máa ja àjàrà àgbálùmọ́ bọ́. Ní ọjọ́ tí a ń wí yìí, Àlàmú tí gbìyànjú láti ré èso àgbálùmọ́ pẹ̀lú òkò o rẹ̀ ṣùgbọ́n kò rí nǹkan ré. Níbi tí ọkàn rẹ̀ tí ń pòpọ̀ ni àgbálùmọ́ tí ja lé e lórí, òkò Akande tún ja òmíràn! Àlàmú bá bẹ̀rẹ̀ láti kó ó, ṣùgbọ́n Akande sáré sí. ‘Àgbálùmọ́ mi nio, òkò mi lo ja á bọ́’. Ó sì súre kó nkan rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà bí Àlàmú nínú púpọ̀ tí ó fi fi ìbínú ta Akande ni òkò lórí ní ibi tí ó bẹ̀rẹ̀ sí. Akande kí’gbe ‘oróóóò!’ Ó ń yí ni ilẹ̀ bí àgbádú tí ọta ọlọ́dẹ bá, tí ó ń jà fita-fita pẹ̀lú ikú. Bẹ́ẹ̀ l’Àlàmú fi ẹsẹ̀ fẹ́, láláì bìkítà, ipò tí ó fi Akande sí.

Ọ̀rọ̀ tí awí yìí jọ òwè, lóba ń láàáró nínú fún Àlàmú. Ọ̀rọ̀ dé ọ̀dọ̀ ọ baálẹ̀. Kété ń ni onísẹ́ tí kán bàbá Àlàmú lára ní ilé. Bí bàbá Àlàmú ṣe rí onísẹ́ baálẹ̀, ló ti mọ̀ pé Àlàmú tún ti wọ gàù, ó ti ru igi oyin. Kò wulẹ̀ jẹ́ kí oníṣẹ́ ó làágùn jìnà. ‘Se Àlàmú tún ti daràn ni? Ẹ wo ó, àrà tó bá wù yín ní ki ẹ fi dá. Ẹ sọ fún baálẹ̀ pé mo ní nkan ti wọn ba fẹ́ fí ró ni kí wọn ó fi ró, mo ti kọ̀ ọ́ lọ́mọ.’ Iyá Àlàmú súré bóóde tẹ̀lé onísẹ́ baálẹ̀ jànnà jànnà, ṣùgbọ́n kete Àlàmú ti jìn sí ọ̀fìn púpọ̀ jù.

Wọn ò kú ṣẹ̀ṣẹ̀ máà dá sẹríà fún-un, àmọ́ tí ọ̀tẹ̀ yìí fẹ́ pelemọ. Ní ṣe ni wọ́n kọ́kọ́ bó ó ní igi ni ìta baálẹ̀ kí ó tó di jua nínú túúbú. Ní ojoojúmọ́ ni yio lọ roko ni oko baálẹ̀ tohun tí pankẹ́rẹ́ lọ́wọ́ àwọn èṣọ́ pẹ̀lú fífín ní àlọ àti àbọ̀. A sé ìyà kò jẹ ọmọ lo ní ohun ti gbọ́n, taani olùkọ́ tí ó kọ́ ọ? Nígbà ti Àlàmú ó jáde lẹ́yìn oṣù méjì, ó ti rù kan egungun, kò fẹ́ ẹ̀ jọ ènìyàn mọ́. Gbogbo ojú rẹ̀ ti dúdú bí nàná àmùrè, àfi bíi abari tí kánhún tí já. Bí ìyá rẹ̀ ṣé rí í ló kán sí ẹkún. Ara rẹ̀ bù mọ́ aṣọ. Ó sáré sì ìyá rẹ, ó bú gbà á si ẹkún. Bàbá rẹ̀ náà o leè rọju rárá, ẹkún wá di àtagbà. Ìwà ajá dìgbòlugi ti fi í sílẹ̀ Pátápátá. Ó ti di àtúnbí.

NÍPA ÒǸKỌ̀WÉ

Lánasẹ̀ Hussein jẹ́ ọmọ bibi ilẹ̀ Ìbàdàn, ní agbègbè Aremọ Ọ́ja’agbo. Ó k’ẹ́kọ̀́ èdè gẹ̀ẹ́sì ni ilé ẹ̀kọ́ Fáfitì Ìbàdàn. Ó jẹ́ Òǹkọ̀wé, akéwì àti olùkọ́ni ní lítírésọ̀ àti èdè gẹ̀ẹ́sì ni ilé ẹ̀kọ́ girama.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *