Ẹ̀rù àwọn ará ibí bà mí jọjọ.
Ẹrù àìbìkítà wọn a máa ṣe mí bí ọyẹ́ ti ń ṣe ọmọ ìkókó.
À ṣé ọdẹ tí a fi sọ́ ilé ni olórí àwọn gbéwirí

A pe Jòhánù kó wá jẹun ló bá kó mámugaàri sí'ni lọ́wọ́.
Ṣe bí ọlọ́bẹ̀ ló yẹ ká mú ẹ̀kọ tọ̀ lọ ni a fi ṣe
Àti ọbẹ̀, àti ẹ̀kọ, ló bá di wọ̀mùwọ̀mù ní kọ̀rọ̀ ẹ̀kẹ́ wọ̀nbílíkí.

Ṣèbí wọ́n ni Ilésanmí dùn joyè lọ?
Bí àlùjànú àjẹrun bá fi ọpọlọ yín ṣe ibùgbé,
ẹ dákun ẹ sìì lọ rọ́kún nílé
Ẹ má ṣe dà bí olónìgí tí ó jẹun lójúbọ èṣù,
tó fẹnu gbé iná wọlé.

Ìbéèrè

Tẹ́'tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ kí o dáhùn ìbéèrè tí ń ró kì kì ni ìsàlẹ̀ ikùn mi. 
Àsìkò ti tó láti tú pẹpẹ ọ̀rọ̀ sílẹ̀.
Ewì ìbéèrè rèé, kí oníkálukú wá mọ́ọ f'etí kọ ní kọngbẹ kọngbẹ.
Ẹ gbọ́ náá tani agẹṣinkólé?
Ta ni ń da ìlú ṣìbáṣìbo?
Ta ni n gbe inú òkùnkùn kó wa lẹ́rù lọ?
À ní sẹ́ ta ni eeku ajẹun lójú onílé?
Agbọ́n ń sẹ, olóólà ijú pa lọ́lọ́, bẹ́ẹ̀ si ni àpá fi gbogbo ara ọdẹ ṣe ìyẹ̀wù
Ìgbà wo ni aṣọ yóò ṣí lójú eégún o?
Ìgbà wo ni ọwọ́ pálábá alọkólóhunkígbe yóò gbàgbé'ra sí isà ejò?
Nílẹ̀ yí, ìgbà wo ni igbà akọ̀pẹ kò ní di ohun àwátì?
Nílẹ̀ yí, àkókò wo ni ọmọ adìẹ á di àkùkọ?
Ẹ̀yin lọ́balọ́ba, ṣé ó d'ìgbà tí orí adé bá sùn ìta ni?
Ọ̀rọ̀ kan ẹ̀yin ìjòyè, àbí ó d'ìgbà tí ìlẹ̀kẹ̀ bá já s'íta?
Ẹ fún wa ní ìdáhùn ní wàrànsesà, gbogbo ara ìlú ló ń fẹ́ kí omi ìlú tòrò.

Ayọ̀bámi Káyọ̀dé jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ lítírésọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ifáfitì dánfodio ní ìlú Sókótó. Ó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ àti lítírésọ̀.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Vince L. Falcone.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *