Ṣóo wo iwájú tóò r’ẹ́nìkan
O w’ẹ̀yìn wò, óò r’éèyàn
L’ọ́tùn-ún l’ósì, ilẹ̀ tẹ́ lọ bẹẹrẹ
Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, o ní ikú ló kàn
Ọjọ́ a bí ọ sáyé, ta lo bá wá?
Wá ná, ọ̀rẹ́ẹ wa
Bóó kú, tìwọ taani?
Tẹ́tí o gbọ́ nàsíà mi ọ̀rẹ́ẹ wa
Ọba adániwáyé ò gbàgbé ẹnì kọ́ọ̀kan
Àláùràbí ò sì da ẹnìkan nù
Báa ti wáyé páà rí, làá rí
Ǹjẹ́ ohunkóhun tẹ́da bá wá ń dojú kọ
Ìdánwò ni, àdánwò sì ni
Mo ṣe bí Elédùà ló dá kálukú
Ó mọ wá, ó mọ̀ wá
Ó mọ ohun táa tó
Bẹ́ẹ̀ ló mọ ohun táà tó
Àdánwò tó bá wá wù kó mú bá kálukú
Ṣebí ó mọ ohun tóo tó
Ó mọ̀ p’óo tóo gbé ni
Ṣebí aré lásán ni gbogbo wa ń sá
A ti gbọ́wọ́ sókè, tátàdá ti gbẹ, àkọsílẹ ti dúró
Bá ò sì kú, ìṣe ò tán
Omidan Rodiyah Ọmọ́tọ́yọ̀sí Mikail jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onípele kẹta ní Fásitì Usmanu Danfodiyo University, Sokoto.