Òpóǹló ni mo wà tí mo ti máa ń gbọ́ nípa ìlú Èkó. Oríṣiríṣi ni atilẹ̀ máa ń gbọ́ ni ìgbà náà. Àwọn kan àtilẹ̀ máa sọ pé; àwọn Èèbó ajẹ́lẹ̀ àti àwọn ‘Misannári’ ni ń gbé ní ìlú náà. Ọmọ ọ̀rẹ́ bàbá mi kan tí ó wá sí abàá wa ni, kò sí ènìyàn dúdú ni ìlú Èkó rárá, àtipé, ‘Párádísè’ ni wọ́n wò fi kọ́ àwọn ilé tí ń bẹ ní ibẹ̀. 

Ń kò tilẹ̀ ro inú pé n ó dé ibẹ̀ láyé ni ìgbà náà. Àmọ́ kí n sọ tòótọ́, màá máa gbàá ní àdúrà pé kí àwọn òbí mi ò lówó bíi sẹ̀kẹ̀rẹ̀ kí wọ́n lé rán mi lọ sí ìlú Èkó. Ẹni tí kò ì dé ìlú náà kò tíì lajú rárá ní ilẹ̀ẹ Nàìjíríà. Wọ́n ní, kódà àwọn èèbó Potogí àti Aráàbù gaan a máa wá láti wá gbádùn ayé wọn ni ibẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ sẹ́yìn, ń kò lérò pé mo le dé Èkó arómisá-lẹ̀gbẹlẹ̀gbẹ rárá. Àmọ́, Elédùà gbọ́ àdúrà mi. Ìyá mi ni wọn gbé isẹ asaralóge fún ní bárékè àwọn ológun ni Ajégúnlẹ̀ l’Ékòó. Bàámi sì jẹ́ ènìyàn tí ó jowú púpọ̀ ṣùgbọ́n wọn ò lè tẹ̀lé Máami lọ. Báami bá fi èmi àti Taiwo ṣe alamín tẹ̀lé Maami lọ sí èkó. Ní alẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí a ó lọ, inú mi dùn débi pé nkò leè jẹun. Àlá tí mo lá kò yẹ̀ lọ́rọ̀ọ Èkó rárá. 

Bí a ṣe jí ní àárọ̀ ọjọ́ kejì ni mo ti ń múra. Èmi tó jẹ́ pé àsínìnrín ni Màámi fí í jí mi fún àsùnbáà, n kò tilẹ̀ jẹ́ kí ẹnì kankan jí mi tí mo fi jí, mo ti kí ìrun, mo ti wẹ̀ fún ra mi, bẹ́ẹ̀ni ìkejì mi náà. Àwa méjèèjì ti wọ ìtẹ́lẹ̀ àpótí wa, dàńṣíkí aláwọ̀ọ ewé tí a lò fún ọdún iléyá tó lọ. Ìyá mi tí gbọ́ oúnjẹ, kíá àwa méjèèjì tí parí abọ́ ògì àti Ọ̀ọ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú. Ìyá mi ò tíì múra, bàbá mi ń ro’jú àti fi gbogbo wa sọ́nà. Gbogbo eléyìí, àmọ́ ni kò mọ ara ẹran lọ́dọ̀ èmi àti Táíwò. Ní ṣe ló dàbí ẹni pé ká ti dé òún. 

Nígbà tí Màámi ó fi ṣe tán, oòrùn ti ń yọjú lábẹ́ẹ kúrúkúrú sánmọ̀. Kí á má bópòó lọ ilé olórò, a wọ ọkọ̀ Èkó, à ń lọ. Kò pẹ́, èmi àti Táíwò ti ń fi orí lu ara wa, oorun àìsùn gbé wa lọ. Ní ìgbà tí a ó la ojú, a ti wọ Ẹ̀kó. Ah! Èkó mà dára jù o. Mo kọ́kọ́ ṣe bí ojú àlá ni mo wà ni, àfi bí mo ṣe ríi pé èmi nìkan kọ́ ní mò ń ṣe kàyééfì sí ohun tí mo rí, Táíwò náà ríi bẹ́ẹ̀. 

Ṣé ká má parọ́, ilé àwò-má-leè-lọ wà ní ìlú Èkó o jàre. Mo rí ilé tí ó ga fíofío, tí wọ́n fi gíláàsì dá  bátànì àrà sí lára. Àrà n kò rírí, mo rí orí ológbò l’átẹ, mo rí ibi tí ilé lásán tí ń bá sanmọ dọ́gba. A tilẹ̀ kọjá lára ilé kan. Ìyá mi ní ‘Násáná-tiatà’ ni orúkọ rẹ̀. Mo rántí pé ọ̀rẹ́ mi ti wí fún mi tẹ́lẹ̀ pé ilé kan wà ní ìlú yìí tí àwọn iyemoja kọ fún ìgbádùn ará ayé, kí wọ́n ó má baà máa dí àwọn lọ́wọ́ fàájì létí odò. Lóòótọ́ ni wàyìí, torípé ajé olókùn ni wọ́n fi kọ́ ọ. Èkó laà bá máa pè ní ‘àrà kì í tán nínú alárà’, à ṣé títì a máa k’ọlà! Báyìí araà mi ò gbà á mọ́, ó ń ṣe mi bíi kí n bọ sílẹ̀ nínú ọkọ̀, kí n máa sáré kiri Èkó gẹ́gẹ́ bí a se máa ń ṣe ní abàá wa, ní ọ̀nà oko Kedá.

Èkó arọ̀dẹ̀dẹ̀-májàá tí Bàbá ọ̀rẹ́ẹ̀ mi wí ṣẹ̀ṣẹ̀ yé mi ni wàyí. À ṣé àwọn afárá tí wọ́n nà sí orí omi ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. Ní ṣe l’àyà mí là wàì-wàì bí a ṣe ń kọjá lórí afárá náà, kí ọkọ̀ọ́ má lọ yàbàrà si inú Ọ̀sà. Ní ìgbà tí a rin orí afárá yìí dé ibi kan, a kò rí ǹkankan mọ ju omi tó lọ salalu. Èkó arómisá-lẹ̀gbẹlẹ̀gbẹ ni ọ lóòótọ́. Ni òkè odò lọ́ùn-ún ni a tún rí àwọn ilé orí omi pẹ̀lú. Bóyá, ‘àlùjáńná’ tí Bàbá, Alfa Atòórọ̀mọlá máa ń ṣàlàyé fún wa ni èyí.

Ṣé, a kìí rìn títí kí a má dé ibi à ńlọ́. Ni ìgbà tí a dé bárékè àwọn ológun ní Ajégúnlẹ̀ ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ pe ayé ni wọn ń jẹ ní Èkó. Ìyàwó ọ̀kan nínú àwọn Ọ̀gá ológun ní ó bẹ ìyá mi lọ́wẹ̀ tí a fi wá. Ìjọba ológun ló wà lorí oyè ní ọdún yìí. Àṣẹ ológun kìí ṣe é dá ní ìgbà tí a ń sọ yìí, bí olúwa rẹ kò bá fẹ́ fi imú dán irin. Àmọ́, ọ̀rọ̀ àwọn ológun a máa sú ni sá. Ni ẹnu ‘géètì’ ni a ti rí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dúró wámú. Ojú u wọn dà bí ti ẹkùn tí ebi ń pa. Wọ́n dá wa dúró. Wọ́n bẹ́èrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ìyá mi, Ìyáàmi sì ń dáhùn.  Ìyáàmi fi ìwé pélébé kan hàn-án. Wọ́n sì jẹ́ ká wọlé. Kí á má f’ọ̀tá pè, àwọn Sọ́jà ń jaye púpọ̀. A jẹ búrẹ́dì èèbó kan ní ibẹ̀, ìyun-ùn ni mo fi mọ̀ pé iyàtọ̀ wà láàrin Búrẹ́dì ilẹ̀ yìí ati ‘Pàfun’ tàbí ‘Kúgan’ tí à ń jẹ ní abà wa. Pabambarì ni pé, a ò mọ ọ̀sán sí òru, pẹ̀lú bí iná ṣe ran’ju kalẹ. Yàtò sì iná kuufin àti Jàǹgo tí ará abà a wa máa ń tàn káàkiri.

Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì ni ìyá mi ti gba yàrá ìyàwó Ọ̀gá’gun lọ. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, ìyá mi gb’óge púpọ̀. Wọ́n túnrase fún obìnrin náà, ó sì dá bíi ‘Áńgẹ́lì’. Ní ìgbà tí ọkọ rẹ̀ ẹ́ ríi, ‘tankiu feri mọsi’ ni ó wí fún Ìyáàmi. Èèbó ńlá ní ńjẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé. Ó fún èmi àti Táíwò lówó, orí i Ńkoku kọ̀ọ̀kan, inú wá dùn gaan ni. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni wọ́n lọ sí òde. Mo lérò pé, Ọ̀ga’gun pátápátá ní ó ń bọ̀ wá tí pọ̀pọ̀-ṣìnsìn fi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́. Ṣùgbọ́n àwa kò lọ sá. Inú yàrá àlejò ni a f’ara pamọ́ sí, torí Màmá mí ní  àwọn sọ́jà ní ‘púrótókọ́ọ̀lù’ púpọ̀. Ní àárọ̀ ọjọ́ kẹta ni ìyàwó ọ̀gágun pe màámi pé kí ó kó wa wá. Ọkọ̀ tí dúró sí ìta de wá. Àwọn ọmọ ogún ti tò sí ìta. Wọ́n ṣí ilẹkun ọkọ̀ fún wa. Jíìbù, ọkọ̀ dẹ̀ǹdẹ̀ ni ọkọ̀ náà. Ní ṣe ni ọyẹ́ ń ya ni gbogbo inú ọkọ naa. A kò gbọ́ gbogbo ariwo èrò mọ́, a kàn ń rí ìta ni.

Kò pẹ́, a dé ibì kan. A bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀. Ilé ńlá kan ni tí wọ́n kọ ‘Supa makẹẹti’ sí ni a wọ̀ lọ. Mo rí bèbí tó wọ aṣọ, àwọn nǹkan ọmọdé pọ̀ jantirẹ rẹ. Èmi àti Taiwo tí ń fún ojú wa lóúnjẹ lọ kí ìyàwó ọ̀gágun tó pè wá. Aṣọ tó dáa méjì méjì ni ó rà fún wa. Inú wa dùn dé ìdí. Ìyáàmi dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ rẹ̀. Táíwò ní, ‘Ẹ ó bí ìbejì’, èmi náà sì se Àmín si. Ìyàwó ọ̀gágun rẹ́rìn-ín, ṣùgbọ́n ó ṣe àmín. Àwọn náà ra nǹkan ọkọ̀ kún. A dari sí bárékè

Bí ilẹ̀ ọjọ́ kejì ti mọ́ ni Ìyáàmi ti jí wá. Ìlọ́ yá, oníbodè Apòmù. Bí Ìyáàmi ṣe ń palẹ̀mọ́ ni mo ti mọ̀ pé Ìbàdàn ti súnmọ láti máa lọ. Èmi àti Táíwò, a kò fẹ́ relé mọ́. Èkó dùn púpò jù. Fàájì ní ìran-ǹ-ran ń bẹ l’Ékòó. Èkó wùmí púpọ̀ láti máa gbé. Mo bi Ìyáàmi pé kí wọ́n ó jẹ́ kí á máa gbé Èkó. Èsì i wọn ni pé, Ìbàdàn ni orí dá wa sí. Ibi orí dá’nisí làágbé.

Lanase Hussein jẹ́ ọmọ bibi ilẹ̀ Ìbàdàn, ní agbègbè Aremọ Ọ́ja’agbo. Ó k’ẹ́kọ̀́ èdè gẹ̀ẹ́sì ni ilé ẹ̀kọ́ Fáfitì Ìbàdàn. Ó jẹ́ Òǹkọ̀wé, akéwì àti olùkọ́ni ní gẹ̀ẹ́sì àti lítírésọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ni ilé ẹ̀kọ́ gírámà.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Jonathan Lessor.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *