Kókó omi ó ṣé ta,
Bẹ́ ẹ̀ ni ọ̀pá tín-ín-rín ọrùn yìí ò ṣé é fà.
Ẹkùn inú aginjù yí wá di aláìléyíń,
Ẹja rẹ̀ di olójú ẹ̀tẹ́ nínú odò ìtìjú.

Ẹni á wí fún, ọba jẹ́ ó gbọ́,
Etí tí à ko iná ọ̀rọ̀ fún, yàrábì jẹ́ ó gbà.
Ọrọ̀ ọ̀rọ̀, owó ọ̀wọ̀,
Gbogbo rẹ wà hàn sí mi kedere, bí oòrùn àárọ̀.

Àgbo ti dànù, àsìkò tí di Júdásì,
Ṣùgbọ́n ìkòkò ó paradà dàkúfọ́.
Igbá ìgbà ṣì ṣé é gbé,
Ìrètí sì ń retí, ìgbàgbọ́ ó sì sọnù.

Èyí ni mo gbé pọn ìrìn àjò yìí,
Wíwà nínú wíwá gbígbé ìgbésí ayé mi.
Mo fi wọ́n ṣe amọ̀nà,
Lórí títì tí mo pé ní, àrà ara à mí.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọdẹ́mákin Táíwò Hassan jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fáfitì Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀ tí ó ń bẹ nílùú Ilé Ifẹ̀. Ìlú Abẹ́òkúta ni wọ́n ti bíi ibẹ̀ ni ó sì dàgbà sí. Ó máa ń kọ àpilẹ̀kọ àti ìtàn ní èdè Yorùbá àti gẹ̀ẹ́sì. Ó féràn láti máa gbọ́ àti kọ orin ó sì nífẹ̀ẹ́ sì eré orí ìtàgé.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti NC Museum of Art.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *