ỌLÁỌ̀RẸ́ AFỌ̀TẸ̀JOYÈ

Ṣèbí oun tí mo mọ̀n tí wọ́n má ń sọ ni pé òkùnkùn kìí bórí ìmọ́lẹ̀, pé irọ́ kìí jáwé borí òtítọ́, pé rìkíṣí kìí lékè àti pe àgàbàngebè kìí la’ni. Ṣùgbọ́n èyí tí mó rí kà nínú ìwé yìí yàtọ̀ fọ́ọ́. Nínú ìwé yìí, èké jáwé olúbórí o! Bẹ́ẹ̀ni, kèéta là láìsí wàhálà àti pé ọ̀tẹ̀ pàápàá j’oyè. Ìwé tí mo ń sọ yìí náàni ìwé tí Ọ̀gbẹ́ni Afọlábí Ọlábimtán kọ tí o pèé ní ‘Ọláọ̀rẹ́ Afọ̀tẹ̀joyè’. Gẹ́gẹ́ bí o ti pe ìwé náàni o jẹ ní tòótọ́, èèyàn kan fi ọ̀tẹ̀ j’oyè o!

Ìwé náà dá lórí Ọláọ̀rẹ́ gẹ́gẹ́ bí olú ẹ̀dá ìtàn nàá. Ọláọ̀rẹ́ ni Ọ̀túnba ìlú Jòǹtolo, ò sì jẹ́ ọ̀kan l’ára àwọn ìjòyè Ọba Ọbálọ́wọ̀ Ẹni-ọlá-ńpa-lẹ́rù, Ọba ìlú Jòǹtolo. Ìlú Jòǹtolo kìí yé bá ìlú Bọ́tẹ̀ jagun, ṣèbí ìlú Bọ́tẹ̀ gbé wà lábẹ́ Jòǹtolo eléyìí tí kò jẹ kí inú Ọlọ́tẹ̀ ọba ìlú Bọ́tẹ̀ dùn. Gbogbo ìgbà sì ni awọn jagun jagun ìlú Bọ́tẹ̀ maa ń ṣígún sí Jòǹtolo bóyá wọ́n ò ti lẹ̀ bọ́ nínú ìgbèkùn àwọn ará ìlú Jòǹtolo. Ṣùgbọń wọn kìí ṣẹ́gun o. Bí ojú oró tí n lékè omi, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni àwọn jagun jagun ìlú Jòǹtolo maa ń ṣẹ́gun lábẹ́ olùdárí ogun wọn, Ọ̀túnba Jòǹtolo, Ọláọ̀rẹ́ Bàbá ‘Kíndélé.

Lọ́gán tí àwọn ará Jòǹtolo bá ti ṣẹ́gun awọn ará ìlú Bọ́tẹ̀, wọn a maa jó, bẹ̀ẹ̀ni wọn a maa yọ̀, tí wọn yòó sì maa kọrin yin ọba wọn bàyìí:


Ọbálọ́wọ̀ ṣẹ́gun, àbùṣebùṣe
Ẹniọlá ṣẹ́gun, àbùṣebùṣe
Ọgun ò sí mọ́, gìdìgbo ò sí mọ́
Ẹniọlá ṣẹ́gun, àbùṣebùṣe


Ọbálọ́wọ̀ ṣẹ́gun, àbùṣebùṣe

Ṣùgbọ́n bí wọn ṣe ń kọrin yìí kò dùn mọ àwọn ìjòyè nínú pàápàá jùlọ, Ọ̀túnba ìlú Jòǹtolo tó jẹ́ aṣiwajú ogun ìlú nàá. Inú n bí wọn pé Ọbálọ́wọ̀ Ẹni-ọlá-ńpa-lẹ́rù nikan ni ó n gba oríyìn ogun ti awọn kan ń fi orí la’kú fún. Àwọn olóyè sì ń dìtẹ̀ bi wọn yìò ṣe le Ọbálọ́wọ̀ kúrò ni orí àpèrè.

Ṣèbí bí wọn ti n dìí tí wọn tuu, bẹ̀èni Ọbálọ́wọ̀ ọkọ Oyínkán gbọ fìnìfìnì ọ̀rọ̀ nàá. Bó ti n yọ gbọ́ pé àwọn oloye rẹ̀ tí n gbàbọ̀dè bẹ̀ẹ̀ni oun gan alára ń lá’làá pé wọn lé oun kúrò lórí oyè. Èyí ti o fi wa mú ìdí rẹ̀ múlẹ̀ gan ni nígbàtí ìlú jíròrò l’áàfin nipa ǹkan tí ìlú le ṣe ti ogun kò fi ni sí mọ làárin ìlú Bọ́tẹ̀ àti Ìlú Jòǹtolo tí Ọ̀túnba dábàá pé ki ìlú Jòǹtolo gbà láti bọ́ sí abẹ́ ìlú Bọ́tẹ̀, èèmọ̀! Báwo ni odindin Ọ̀túnba ìlú yíò ṣe maa mú irú àbá báyìí wa? Inú bí Ọbálọ́wọ̀, bẹ́ẹ̀ ló gba òpá oyè lọ́wọ́ Ọ̀túnba Baba Akíndélé tó rọ̀ọ́ l’óyè.

Eléyìí bí àwọn ìjòye díẹ̀ nínú. Inú bí Baba Akíndélé pàápàá. Ṣèbí ẹni bá ni ki là ó ṣe náà ni à ń ṣe hàn. Ọ̀túnba Ọláọ̀rẹ́ ba gba ìlú Bọ́tẹ̀ lọ. O lọ pàdí àpòpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́tẹ̀ tí n ṣe Ọba ìlú Bọ́tẹ̀. O sọ fun pé oun yíò fun ni àṣìrí lá ti ṣẹ́gun ìlú Jòǹtolo, ti Ọlọ́tẹ̀ yíò sì bá oun lé Ọbálọ̀wò kúrò l’óyè, ti oun Ọ̀túnba àná yío si di Ọba ìlú Jòǹtolo tuntun. Ọlọ́tẹ̀ ni bí ó bá ti ṣe pé ìlú Jòǹtolo yío wa lábẹ ìlú Bọ́tẹ̀, àbùṣebùṣe. Àwọn méjèèjì sì mulẹ̀, wọn fi ọ̀rọ̀ náà ṣe awo.

Kòpẹ́ kòjìnà, ìlú Bọ́tẹ̀ ṣígún lọ sí ìlú Jòǹtolo, Ọ̀túnba sì ràn wọ́n l’ọ́wọ́ láti ṣẹ́gun. Bi eré bí eré, Baba Akíndele, Ọ̀túnba àná gba ọ̀pá oyè, o sì di Ọba ìlú Jòǹtolo tuntun. Wéré tó j’Ọba tán ni àwọn ara ìlú bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí kọrin yìn ín:

Ọlọ́tẹ̀ ṣẹ́gun àbùṣebùṣe
Ọláọ̀rẹ́ ṣẹ́gun àbùṣebùṣe
Ogun ò sí mọ́, gìdìgbo ò sí mọ́
Baba Dele ṣẹ́gun, àbùṣebùṣe!

Bí ọlọ́tẹ̀ ti borí rèé o. Bi Ọláọ̀rẹ́ ṣe fi ọ̀tẹ̀ j’oyè rèé o! Bótilẹ̀jẹ́pé ibi ti eré oníṣe yìí pari sí nìyìí, mo kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàki kan: pé kí a maa ṣọ́ra ṣe bí ayé baa n y’ẹni nítorí gbogbo ènìyàn kọ́ ni ìlọsíwájú wa yíó dùn mọ́ nínú. O tún kọ wa pé kí a yé fi iná sí orí òrùlé sùn àti pe bí ikú ilé kò pa ni, ti òde kò le rí ní gbé ṣe. Má dá bàá pé kí ẹ̀yin naa ó gbìyànjú láti ka ìwé nàá.

Ayé!
Ayé le ó ju ìdàrọ́,
Aye fẹ́lẹ́ ju awọ inú,
Síbẹ̀síbẹ̀ inú ayé kò ṣe-é rí,
Síbẹ̀síbẹ̀ inú ayé kò ṣe-é rí,
Ni kálukú ba ńfọ̀rọ̀sínú kiri.
Ayé tí n p'olè-é jà, tí ń polóhun ó ṣọ́hun
Ayé tí ń p'Adégún lóòórọ̀, tí p'Adéògún lálẹ́
Aye ti kò gbóná ti kò tutù
T'o fẹ́lẹ́ t'o ju tán-án-ná
T'o tún le ju awọ bàtákoto


 
Ọ̀rẹ́dọlá Ibrahim Àjàtóntìrìàjàbalẹ̀ jẹ́ akẹ́kọ́ gboyè ìmọ̀ òfin láti ilé ẹ̀kọ́ gíga fáfitì Ìbàdàn. O jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Òmù-Àrán ní ìpínlẹ Kwara nibi tí o ti ni àǹfàní láti kọ́ púpọ̀ nípa iṣe àti àṣà Yorùbá l’ọ́dọ̀ ìyá bàbá rẹ̀ – Alhaja Mọ́ríamọ̀ Ayélàágbe Ọ̀rẹ́dọlá. Ìlú yìí nàá ni o ti lọ ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama níbi tí ó tún ti ní àǹfàní àti kọ́ nípa ẹ̀kọ́ Yorùbá láti ọ̀dọ̀ àwọn òlùkọni tó dágánjíá tí wọ́n sì tún múnádoko pẹ̀lú. Ó k’ẹ́kọ́ jádé ní ilé ẹ̀kọ́ girama Government Secondary School Òmù-Àrán gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ́ tó yege jù lọ ní èdè Yorùbá. Fún ìgbà dìè, Ibrahim ti ṣe ìwọ̀nba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Oníṣòwò kékeré, o sì tún jẹ́ Akéwì, Òǹkọ̀wé, Oníròyìn àti Òṣèré Akẹ́kọ́ ní èdè gẹ̀ẹ̀sì àti ní èdè Yorùbá. Ibrahim jẹ́ ara àwọn òlùdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́, ilé iṣẹ́ SkillNG àti ìwé ìròyìn orí afẹ́fẹ́ ThePageNg. Ìwé lítírésọ̀ Yoruba tí ó fẹ́ràn jùlọ ni Eégún Aláré láti ọwọ́ Láwuyì Ògúnníran. Ibrahim jẹ́ olùkáràmáisìkí ìmọ̀ àti orúkọ rere, o sì tún gbàgbọ́ pé owónikókó. Ẹ lè kàn si ni ibrahimoredola@gmail.com tàbi lóri 07061282516.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *