Ìyá kogberegbe, ní gbogbo ara àdúgbò mọ ó si, àmọ́ ìyá èkó ni àwọn ẹbí ń pè é. Kii dá rìn lai si ìyá Dupẹ.

Inú ọkọ danfo ni ìyá kogberegbe wà ní ìgbà tí ọmọbirin pupa tá ń wí yìí wọ’nù ọkọ̀̀. Ìbàdí rẹ ń gbọn rìrì nínú ṣòkòtò tí ó wọ̀, bẹ ẹ̀ sini ewu ọrùn rẹ̀ kò ju pépé bíi aṣọ aáyán lọ. Ipenpeju rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fẹ́ ẹ̀ tó dì ní irun aláràmbárà. Àwọn èrò tí wá nínú ọkọ̀ kí ó tó o de, ìyá kogberegbe joko si ẹyin, bẹ́ẹ̀ sì ni ọmọbìnrin yìí joko sì àgá ìlà iwájú ìyá.

Bí ó ti jókòó ní àṣírí tí ń bẹ ní ìdí adie rẹ tí tú. Gbogbo ara inú ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún àwòrán oníhòòhò tí ọmọge ìgbàlódé yìí ń fún wọn wò. Bí ọkọ̀ tí ń já sínu galọọpu ni bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí ìdí rẹ ń hàn sí.

Bí gbogbo ara inú ọkọ̀ tí ń kún, ìyá kogberegbe dakẹ jẹ́ jẹ́ ní, bẹ́ẹ̀ ni ìyá Dúpẹ́ fi ọwọ tọ́ kogberegbe. Inú ìyá ru fún ìbínú, pẹ̀lú bí ọmọbìnrin náà ṣe sí ara  silẹ. Ṣé bí wọn ní tomode òun laafii díwọ̀n tàgbà ni.

A ṣe kìnnìún ìyá ń ṣọdẹ ni. Ọmọbìnrin tí a ń wí yìí tí ń ṣe àkíyèsí pẹ̀lú ikùn sínú àwọn ènìyàn inú ọkọ̀, bẹ́ẹ̀ lọ wun náà ń rún ara. Ó dìde láti fa ṣòkòtò rẹ̀ sókè,  kí ó bo ìdí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò bo ó dáadáa. Kí bá ti wá a mọ̀ kó má fà nkan kan. Bí ó ti tún dìde láti tún fà ni wàhálà bá bẹ silẹ. Ní ìyá kogberegbe bá yari. Mo mọ̀ pé ẹ bèèrè pé kí ni ó fà á? Ìyá kogberegbe lo bínú ó. ‘ó tíó’ ìyá gbá ọwọ ọmọbìnrin náà mú, ‘ó gbudọ faa rárá, mio ni gba ìyẹn rárá!’ ìyá bá yari. ‘Màmá, ẹ fi ṣòkòtò mi silẹ, àbí kí gaan lóde?’ ọmọbìnrin gba ọwọ ìyá mú pẹ̀lú ojú tí ó fi kó ìyá mọ́lẹ̀. Kí bá ti mọ̀ kó bẹ̀bẹ̀ kó tó di yánpọnyánrin máa lọ́wọ́

“Ṣé ojú rẹ ó sọnà fún ọ kí o tó wọ irú aṣọ yìí jáde ní, àbí ó ní gigi tí ó ó fi wo ara rẹ bí? Wá ní láti fii lẹ̀ bí ó ṣe wá, kí a mọ̀ pé ó ti ń fún wa ní ìran wò’. Gbogbo ara inú ọkọ̀ ò lé mú oro yii mọ́ra, nise ni wọ́n sọ erin d’orin ni wọ́n bá ń kọ ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin yìí ṣe fi ìbínú pariwo mo awakọ̀, pé kí ó sọ òun kalẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyá kogberegbe ò fi lọ́run silẹ.

“láró ń rò ja npo ọmú, ọmọ pọ̀, ó kòní ibi í rè’. Bi ìyá ṣé nfa ṣòkòtò náà l’ọmọbirin ọhun náà ń du kí pátá ohun má ja.

“ìyá burúkú lẹ́yìn náà ‘ ọmọbìnrin òun náà ń dáhùn esi ọ̀rọ̀ ìyá. Ọ̀rọ̀ yìí di ìṣù ata yán-án yàn-án. Èrò tí pé bìbà, wọ́n ń patẹ ìran wíwò.

Àwọn ará àdúgbò tí wọ́n mọ ìyá tí súre sì wọn, wọ́n ń bẹ ìyá kògberegbe pé kí ó fi ọmọbìnrin òun láṣọ ọ́ lẹ̀. A se ìyà ò tó ìyà ni kò ní dáa fún ẹni lumi, b’ọ́rọ̀ bá d’oju rẹ tán, yio di kini mo ṣe. Ní gbà tí ayé pé lè lórí, nlo bá fi ikúnlẹ̀ bẹ́ẹ, ló bá ń bẹ ẹ̀bẹ̀. ‘Èṣù fẹ b’ọ́ ọ gbé òní kò saaye, góńgó imú rẹ ńkọ́? Ó kò mọ orúkọ tó ń pè mí na?

“IYA KOGBEREGBE!”, Àwọn ènìyàn pariwo. Ní báyìí ẹ̀rù tí ń bá ọmọbìnrin náà, fún bí àwọn ìyá wọ̀n yìí ṣe múra sì ọ̀rọ̀ tí kò tó oun a á y’ada bẹ́. Èsùó ọ̀rọ̀ tí padida ó ti wà ń lé ajá ọmọbìnrin náà. Ẹ̀kọ́ ńlá ni ìyá kogberegbe kọ ọ́ lọ́jọ́ náà. Mo mọ̀ pé yio sọ fún arọ́mọ́-dọ́mọ́ rẹ̀ nípa ohun tí ojú rẹ rí lesu pé ó wọ́ aṣọ tí ó mú akude bá àṣà ìmura Yorùbá.


‘Lanase Hussein jẹ́ ọmọ bibi ilẹ̀ Ìbàdàn, ní agbègbè Aremọ Ọ́ja’agbo. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ Fáfitì Ìbàdàn níbi tí ó ti ń kọ́ nípa ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì. Ó jẹ́ Òǹkọ̀wé, akéwì àti olùkọ́ ni.

Àwòrán

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *