Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Fi ìtàn sílẹ̀ fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ
Kí wọ́n le máa rántí rẹ nínú ìwé ìtà
n.

Gbogbo ohun tí a bá ṣe lónìí, ọ̀rọ̀ ìtàn ni bó dọ̀la
Gbogbo ayé ló máa tán
Gbogbo wa la máa padà dìtàn.

Nítàn kí o tó tan ọ̀rẹ́ mi
Irú ìtàn wo lo fẹ́ ní?
Kí lo fẹ́ káyé sọ nípa rẹ bí tí tán bá dé?

Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Pàtàkì ni ká nítàn
Pàtàkì ni ká fi ìtàn sílẹ̀ sáyé
Káyé le rántí wa nígbà tí tí tán bá dé bá wa
Tí a padà dìtàn fáyé láti kà.

Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Ìtàn wo lo fẹ́ káyé kà nípa rẹ̀ bí o bá tán
Ǹjẹ́ o ń múra sílẹ̀ fún tí tán?
Ìtàn wo lò ń kọ sílẹ̀ fọ́mọráyé?

Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Fi ìtàn sílẹ̀ fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ
Kí wọ́n le máa rántí rẹ nínú ìwé ìtàn

Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ kí n nítàn
Kí n nítàn
Kí n tó tán
Kí ìtàn mi tàn káyé
Nígbà tí mo bá tán.

*Àwòran tí ó wà nínú ewì jẹ́ ti  Julian Sinzogan tí ó pè ní "Àwọn Ọba Ilẹ Yorùbá"

Malik Adéníyì (RMA) kọ ewì yìí ránṣẹ́ láti ìlú Ìbàdàn.

Ìtọ́ka

  1. Ọ̀rọ̀ Olóòtú: Ìtọ́wò Àkójọpọ̀ Àtẹ́lẹwọ́
  2. Ìlànà fún Ìgbàwọlé: Àtẹ̀jáde Àtẹ́lẹwọ́ Apá kejì
  3. Ẹ̀rọ Ìránsọ | Kọ́lápọ̀ Ọlájùmọ̀kẹ́
  4. Ojúlarí | Rasaq Malik Gbọ́láhàn
  5. Nítàn kí o tó tán | Malik Adéníyì
  6. Lẹ́tà: Ọ̀rọ̀ Kẹ̀kẹ́ | ‘Gbénga Adéọba

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *