Ọ̀RÒ ÌṢÁÁJÚ

“Ìbẹ̀rẹ̀ kìí ṣe oníṣẹ́, èèyàn tó bá fi orí tìí d’ópin ni a ó gbàlà”, jẹ́ oun tí wọ́n maa ń sọ. Inú wá dùn púpọ̀ fún àṣeyọ́rí iṣẹ́ yìí, eléyìí tó jẹ́ àjọṣepọ̀ láàrin ilé iṣẹ́ àṣà ÀTẸ́LẸWỌ́ àti ilé iṣẹ́ òlùṣònà igbàlódé The Artivists NG.

Èróngbà iṣẹ́ náà bẹ́rẹ̀ ni oṣù igbe (oṣù kẹẹ̀rin-in ọdun yìí) nígbà tí olùdásílẹ̀ The Artivists NG tọ ẹgbẹ́ ÀTẸ́LẸWỌ́ wá pẹ̀lú ìròrí iṣẹ́ náà. Gẹ́gẹ́ bó ti ṣepé kókó wíwàawa náà ni pé kí a máa gbé èdè àti àṣà lárugẹ, lọ́gán náà ni a tẹ́wọ́ gbàá.

Ní ṣókí iṣẹ́ yìí jẹ́ iṣẹ́ abd yorùbá eléyìí tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ sínú àwọn àwórán tó rẹwà. Fún lẹ́tà kọ̀ọ̀kan tí ó wà nínù abd yorùbá tí a ṣe, a ríi dájú pé a fi ọ̀rọ̀ yorùbá kan to báa mu si, bákan náà, a tun túmọ̀ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sí èdè gẹ̀ẹ́sì. Kí a báà lè jẹ́ kó tún dùn si, a tún fún àwọn ènìyàn ni àǹfàní láti ṣe ìdáhùn sí àwòrán kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọn tó bá lẹ́tà kọ̀ọ̀kan mu lórí àwọn àpéjọ orí afẹ́fẹ́ bíi Fesibú, Túútà àti IG.

T’ẹ̀gàn kọ́, iṣẹ́ takun takun ni àwọn ọmọ ilé iṣẹ́ méjéèjì yìí ṣe láti rií dájú pé iṣẹ́ náà jẹ àṣeyège. Nítorí èyì, a gbóríyìn fún gbogbo wọn àti gbogbo àwọn olùkópa naa tí kò rẹ̀ wọn láti bi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sẹ́yìn. Láìsí iṣu, kò sí bí a o ti ṣe tàkaàkà ẹsẹ pé a fẹ jẹ àsáró elépó rẹ́dẹ́rẹ́dẹ́.

Fún ìpamọ́ oun ìtànká, ló jẹ́ kí a kúkú f’ẹ̀kan kó gbogbo rẹ̀ jọ sínú ìwé yìí fún àkàgbádùn gbogbo àwọn olólùfẹ́ àti àkẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá. Ẹ dákun ẹ dábọ̀, ẹ bá wa fọn ká sí orí afẹ́fẹ́, ẹ bá wa jẹ́ kí àwọn ará àti ojúlùmọ̀ yín rí akojọpọ̀ yìí!

Ó tún d’ìgbàkan ná. Ire o!

Oṣù Ọwẹ́wẹ̀, Ọdún 2019.

Dahunlóòdì Ìwé ABD Yorùbá

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *