Irú ìbéérè wo ni bàbá yìí ń bi mí? Báwo ni èèyàn tún ṣe ń l’óyún?

Bí mo ṣe gbọ́ ìbéérè tí Dádì béèrè lọ́wọ́ mi, ṣe ni mo fi ẹ̀rín tó fẹ́ wú jáde lẹ́nu mi pamọ́ sí ẹ̀rẹ̀kẹ́. Ṣè bí bẹ̀ẹ̀ náà ni emi gan alára ń béèrè l’ọ́kàn mi pé: Irú ìbéérè wo ni bàbá yìí ń bi mí? Báwo ni èèyàn tún ṣe ń l’óyún? Ká ti lẹ̀ sọ pé lóòótọ́ ni pé olùdárí ìjọ akọrin sọ́ọ́sì Dádì ló fún mi l’óyún. Kátún wá sọ pé lóòótọ́ ni pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni mi, ṣé ìyẹ́n wa sọ́ pé kí Dádì ma béèrè àwọn ìbéérè gọ́tà dọ̀tí lọ́wọ́ mi?

Apanilẹ́rìín gbáà ni Bàbá yìí o! Àwọn ni wọn bí mi, wọ́n bí Tutù, Ìyanu àti Tọ́lá jòjòló, bẹ́ẹ̀ni wọn kò mọ bí oyún ṣe ń dé’nú obìnrin? Amọ̀ràn-bi-ni-Ọ̀yọ́, o rí’yàn lórí Fesibúúkù, o tún ń béèrè lọ́wọ́ ẹni pé báwo lèèyàn ṣe dé bẹ̀…èèyàn a máa wọlé láìsí páásìwọọ̀dù ni?

Ago méjìlá ku tíntiní, tó tùmọ̀ sí pé ebi ọ̀sán ti ń pa mí. Ó wù mí láti gbọ́ gbogbo ẹjọ́ gọ́tà dọ̀tí tí Dádì ń bá mi rò, àmọ́ bí ebi bá ti ń lù mí ní pàṣán, o ma ń ṣòro fún mi láti gbọ́ ẹnikẹ́ni.

“Báwo ni oyún ṣe dénú ẹ́”? Hùn. Àwàdà! 


Kàfí Fáshọlájẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ́ gbòye ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáfitì ìlú Ìbàdàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *