Èyí ni orin Jòhánù Lẹ́jẹ́ǹdì tí ó pè ní “All of Me”.

Ẹsẹ̀ Kiní

Kíni mofẹ́ ṣe láì sí ẹnu rẹ Nì tí ó jáfáfá
Tí ó ń fà mí mọra, ti ìwọ sì ń tamí sí ta
Orí mi mà ti n yí kẹ̀, láì ṣeré, mi ò lè dè ẹ́ mọ́lẹ̀
Arẹwà, kí ló n gbe ẹ l’ọ́kàn
T’óò bá mọ̀n, mo wà lórí ọwọ́ idán rẹ
Òyì ma ń kọ́ mi, bẹẹni mi ò mọn oun ó bàmí
Ṣùgbọ́n ó dá mi l’ójú pe mo máa wàpa.
***
Àjínkẹ́, lóòtọ́ l'oríì mi ńbẹ l'ábẹ́ omi
Ṣùgbọ́n mò ń mí dáada.
Àjínkẹ́, o ma ti yó’fẹ́ kẹ
Èmi gaan alara ò sì mọ ǹkan t’ó ń ṣe mí mọn o.

Kórọ́ọ̀sì

Nítorí gbogbo ara mi
Ní ìfẹ́ gbogbo ara rẹ
Mo ní’fẹ́ ìbàdí àti gbogbo igun ara à rẹ
Àti gbogbo àwọn àléèbù rẹ tó ṣe rẹ́gí.

Fún mi ní gbogbo ara à rẹ
Emi naa a sì fún ọ ní gbogbo ara à mi
Ìwọ ni òpin àti ibẹ̀ẹ̀rẹ̀ mi
Kódà tí mo bá n f’ìdí rẹmi, ewe olúborí ni mo ń já. Àjínkẹ́

Nítori mo fún ọ ní gbogbo ara mi
Iwọ gan alára sì fún mi ni gbogbo ọ̀kan rẹ.

Ẹsẹ̀ Kejì

Àjínkẹ́, o di ẹ mèèló ti mo fẹ́ sọ fún ẹ
Pé kódà tí o ba ń sunkún, o sì tún r'ẹwà
Bí aráyé bá fẹ́ gbé ẹ ṣubú, mo wà l’ẹ́yìn rẹ bi’ké
Ìwọ ló lẹ̀ ṣe okùnfa ṣíṣubú mi
Ìwọ náà ló sì lè gbémi dìde
Mi ò lẹ̀ dákẹ́ orin kíkọ
Nítorí wípé ò ń gbá l'órí mi bi ata dídin,
Fún ìwọ, àyànfẹ́ mi.
***
Àjínkẹ́, lóòtọ́ l'oríì mi ńbẹ l'ábẹ́ omi
Ṣùgbọ́n mò ń mí dáada.
Àjínkẹ́, o ma ti yó’fẹ́ kẹ
Èmi gaan alara ò sì mọ ǹkan t’ó ń ṣe mí mọn o.

Kórọ́ọ̀sì

Nítorí gbogbo ara mi
Ní ìfẹ́ gbogbo ara rẹ
Mo ní’fẹ́ ìbàdí àti gbogbo igun ara à rẹ
Àti gbogbo àwọn àléèbù rẹ tó ṣe rẹ́gí.

Fún mi ní gbogbo ara à rẹ
Emi naa a sì fún ọ ní gbogbo ara à mi
Ìwọ ni òpin àti ibẹ̀ẹ̀rẹ̀ mi
Kódà tí mo bá n f’ìdí rẹmi, ewe olúborí ni mo ń já. Àjínkẹ́

Nítori mo fún ọ ní gbogbo ara mi
Iwọ gan alára sì fún mi ni gbogbo ọ̀kan rẹ.

Afárá

Fún mi ni gbogbo ara rẹ
Nínú ayò yìí tá ń ta, ọ̀ta ma l'awa méjèèji o
Ewu ń bẹ l'óko lóngẹ́, ṣùgbọ́n a ò mikàn ooo!

Kórọ́ọ̀sì

Nítorí gbogbo ara mi
Ní ìfẹ́ gbogbo ara rẹ
Mo ní’fẹ́ ìbàdí àti gbogbo igun ara à rẹ
Àti gbogbo àwọn àléèbù rẹ tó ṣe rẹ́gí.

Fún mi ní gbogbo ara à rẹ
Emi naa a sì fún ọ ní gbogbo ara à mi
Ìwọ ni òpin àti ibẹ̀ẹ̀rẹ̀ mi
Kódà tí mo bá n f’ìdí rẹmi, ewe olúborí ni mo ń já. Àjínkẹ́

Nítori mo fún ọ ní gbogbo ara mi
Iwọ gan alára sì fún mi ni gbogbo ọ̀kan rẹ.

Ọlátúnjí Haleem jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboye láti ilé ìwé gíga fáfitì Ìbàdàn. Ó jẹ ọmọ bíbí ìlú ọ̀yọ́, o sì fẹ́ràn à ti máa gbé ìṣe àti àṣà Yorùbá l’árugẹ. Ẹ le kàn si ni orí olatunji.haleem@gmail.com tàbí 08182075816.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *