Lẹ́tà Méjì
***
Mof’Ólúwawò O MojọláOlúwa

MÀÁMI Ọ̀WỌ́N

Màámi ọ̀wọ́n,
Ìdùnú àti àyọ̀ ni mo fi kọ ìwé yìí.
Báwo ni ǹkàn? Gbogbo ilé ńkọ́?
Ṣe ẹ̀ ń tà, ṣ’ájé ń bu igbá jẹ?
Mo lérò pé ohun gbogbo ń lọ déédéé?

Mo bímọ ní ìjẹ́ta,
Ọmọkùnrin làntì lanti
Ṣe l’ọmọ jọ bàbá ẹ́ bi imú!

Àngẹ́lì ni Ọlọ́run fi Akin ṣe fún mi -
Ọkọ nínú àwọn ọkọ.
Pàápàá ní gbogbo ìgbà tí mo l’óyun,
Ṣe ló n kẹ́ mi bíi kílódé,
Ló n gẹ̀ mí bíi kàsínkan.

Ẹ̀rù kan tó ń bà mí ni wípé:
Ṣé báyìí ni yíò maa rí’lọ,
Àbí ìfẹ fẹrẹnjógi ni
Bí mo bátún ránti ẹ̀yin àti bàámi,
Àyà mi a tún já.

O ti fẹ́rẹ̀ẹ̀ pe ọdún kan ta f’ẹ́ra bàyìí,
Àfi bi párádísè lojoojúmọ́.
Ó ń ṣẹ̀tọ́,
O sì ń ṣe ìtọ́jú mi.
Ohun gbogbo ló fi yàtọ̀ sí bàámi,
Bi mo ti wí gẹ́lẹ́ nínu lẹ́tà mi ìjọ́sí.

Ẹ ti ẹ̀ gbọ́ náà,
Bóoni bàámi alára gan?
Ṣé wọ́n ti pa ọwọ́ ọ̀tẹ̀ tì?
Ṣé ilé ti kúrò ní pápá ìjàkadì?

Ka má fi ọ̀rọ̀ sílẹ̀ sọ̀rọ̀:
Kìísu ti yege nínú ìdánwò àwọn oníṣègùn
Ẹbí wa nàà ti di dọ́kítà.

Èsì ìdánwò UTME Kìítán nkọ́?
Akin sọ wípé kó wá ṣe ilé-ìwé gíga fásitì níbí,
Ṣùgbọ́n ẹ ma tìi sọ fún bàámi o!

Ǹ ó maa retí lẹ́ta yín,
Ẹ fi orúkọ ọmọ ránṣẹ.
Ǹbá ti ni kí ẹ maa bọ̀,
Ṣúgbọ́n jagunlabí bàámi ò ní gbà.
Ẹ̀yin méjèèjì kò sì le dìjọ̀ wá,
Ilé a ti gbóná jù.

Emi ọmọ yín ni,
Kìíyẹ̀.

KÌÍYẸ̀ MI Ọ̀WỌ́N

Kìíyẹ̀ mi ọ̀wọ́n,
Inú mi dùn púpọ̀ láti ka létà rẹ,
Emi náà ti d’ọlọ́mọọmọ láyé wàyìí,
Ọpẹ́ ni f’ọ́ba òkè!
Báwo ni Akin ti ṣe?
Àna mi àtàtà,
Okùn ìfẹ́ yín kò ní já
Ònyà ò ní yà yín láṣẹ Èdùmàrè.

Ìkókó náà nkọ́?
Ọmọtuntun àlejò ayé:
Ọmọbóníkẹ̀ẹ́ Ayọ̀tọ̀míwa Àdìgún.
Ọlọrun a wòó, a dáa sí fún wa.
Èdùmàre á bami ṣìkẹ́ ẹ̀.

Ìdùnú gbàà ni ìròyìn àṣeyege Kìísú jẹ́ fún mi,
Ìyẹn ni pé, àwa náà ti ní Dọ́kítà ní ẹbi wa nìyẹn o.
Ọlọ́run kú iṣẹ́ lọ́run.

Àgbò bàbá yín kò tíì p’àwọ̀ ẹ̀sín dà o.
Bí o ti ń bínú ló n sọ ìjà sílẹ̀ nígbàgbogbo.
Ṣe ni ìfúnpa mi ń ga sii.
Dọ́kità ni kin má fi ṣe ìran wò
Pásítọ̀ ni ́kín má d’ákẹ́ àdúrà
Ṣùgbọ́n ohun gbogbo y'Élédùà.

Maa gbádùn ní tirẹ.
Jẹ́ kí Akin tọ́jú ẹ bó bá ṣe fẹ́
Ẹ̀ẹ̀kan làá ṣ’ayé!

Bá mi tọ́jú ẹ̀jẹ̀ ọrun daadaa -
Ayọ̀ọ́tọ̀míwá tèminìkan
Gbogbo yín pátá ni mò ń rántí nínú àdúrà.

A ṣì ń dúro de èsì ìdánwò Kìítán,
Bó dára, bi kò dára
Bàbá rẹ kò ní gbà kó wá s’ọ́ùn-ún.

Títí di kérésì tí gbogbo ojú á pé.
Ẹ máa ṣe jẹ́jẹ́ o!
Kí Ọlọ́run ṣọ wa.


Ní tòótọ́,
Ìyáà rẹ.

Mof’Ólúwawò O MojọláOlúwajẹ́ amòfin àti ònkọ̀wé. O ti ko ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewì àti ìtàn àròsọ ti a ti tẹ̀ jáde lórísirísi ní ilẹ̀ Áfíríkà, ní inú onírúurú ìwé àkójọpọ̀ ewì àti ìtàn pẹlu lori ayélujára. Ó féràn láti máa kọ ìtàn àti ewì, àti láti maa ya àwòrán. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ewì/ìtàn rẹ̀. 

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *