Nípa wíwà àti nínú Òfo

Bó bá pẹ́ títí
Ọmọ ènìyàn á ṣ'àfẹ́rí irẹ rẹ̀ lọ sí ònà jíjìn.
Ó só síni lẹ́nu, mo sí bí'ra mi lérè pé
Ipò kínni ikú jásí?
Ǹjẹ́ a lè f'ikú sílẹ̀ kí ó máa b'áwa y'ọwọ́ òkèlè nínú àwo tánganran?
tàbí kí a gbàgbé eré tí irẹ n sá lọ
Bí ó tilè kúkú tí jẹ́ wípé
Ikú tí sọ wá di yẹpẹrẹ láwùjọ
Wàyí, ǹjẹ́ kí a ṣe àfojúsùn ikú bí?
Ọ̀nà kan tí a lè gbà ṣ'àfẹ́rí ikú
ni fífi ire ẹni sílẹ̀.

Dájúdájú ohun kan tí dì àifojúrí
àmọ́, ikú pọn dandan.

Translated from Òdẹ́yẹmí, Ìdòwú Ebenezer’s BEING AND NOTHINGNESS
=======
BEING & NOTHINGNESS

They said Green pastures are
What we must chase.
So I ask myself:
What about death?
Should we leave it to stay, with us?
Or, we chase it away?
Perhaps, no need for Green pastures,
Since death makes
all synonymous to nothing.
So how do we chase death?

We can only chase death
By leaving Green pastures.

Something is illusion
Death is – reality.

Biography: Idowu Odeyemi is a Nigerian poet and essayist. His poem Love Only Kills A Poor Boy won the Liverpool based Merak Magazine 2019 annual literary recognition Awards for Best Poem of the Year. He was shortlisted for the 2018 Nigerian Students Poetry Prize and the Christopher Okigbo Poetry prize. His poems appeared in the anthology 84 Bottles of Wine dedicated to the Nobel Laureate Wole Soyinka, Constellate Journal, Kalahari review, Praxis magazine, among others.

First published on Kalahari review.

Ikú D’ojúlé, Ojú ọjọ sí n paradà

Ayé n yí,
Ohun gbogbo sì n yìí pẹlú
Ìgbà ń lọ, àkókò sì ń lọ pẹlú.
Ẹni a rí ní a mọ̀, ohun gbogbo d'olúwonkoko.
Eré ayò kò ṣé ta lábẹ́ igi mọ́
Ẹmu ògùrò sì ti tán nínú akèngbè
Ọ̀rọ̀ wá dorí afẹ́fẹ́
Ó dorí ìtàkùn àgbáyé
Ikú ń kan lẹ̀kùn ilé ẹni
Àìsàn tẹ́ bàtà sí etí ọkọ.
Ààrùn wá ń ṣe ge-n-ge láàrin ọmọ Adáríhunrun

Ojú ọjọ ń paradà
Igi igbó sì ń wó lulẹ̀
À ń pàdánù ohun rere tí Elédùà fifún wa.
Òye ọmọ ènìyàn kò tilè yé mi mọ́ rárá
Bí a bá fi ọwọ́ ara wa fa àrùn apani
Àá tún fi ọwọ́ ara wa b'ewéko ìgbé jẹ́

Àfi kí Elédùà yọ ìwà ìkà kúrò nínú wa
Kí a lè gbé ilẹ́ ayé l'ayọ̀
Pẹ̀lú àlàáfíà.

Nípa Òǹkọ̀wé

Awósùsì, Olúwábùkúnmí Abrahamu, jẹ ọmọ ile-ẹkọ gíga tí unifásítì ti ilè ni Ìbàdàn. Ni ipele ìkẹta. Tí ọ sí n ká nípa ìtàn. Oríṣiríṣi ewì ati àpilẹ̀kọ rẹ ní èdè gẹ̀ẹ́sì ní a tí tẹ jade ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ọkẹ òkun. Ọ fẹ láti máa kà D.O Fágúnwà pẹlu iyán gidigidi.

Àṣẹ lórí àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Bogdan SM.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *