Coro ló pojú kòró jẹ

Ṣebí láti ọjọ́ táláyé ti dáyé L'ayé tí ń yí, tí 
ọmọ adáríhunrun ti ń yí tẹ̀le. Àfìgbà tí
Coro de. Àìsàn burúkú tí ń da dúníyàn ní
ṣìboṣìbo. Òun ló mú ọwọ ago ayé wá sí
ìdádúró. Èèmọ̀ lukutu pẹ́bẹ́

Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ayé ni wà. Coro kówa jọ,
ó ń kó wa ní ẹ̀kọ́ ìmótótó. Bíńtín l'ayé ọ
jàre. Èmi ò mọ pé ká fọṣẹ fọwọ déédéé, ká
fasọ bomú bo'nu tí abá ń sìn tabi wúkọ́ leè
lé àìsàn wọgbó.

Ta ló mọ̀ pé ènìyàn lè dékun òde
àlọ kúdórógbó, láì ṣe pé wọ́n yọ
ọjọ ẹtì ní àwo awọn ọjọ tókù.

Ṣebí wọ́n ní ojú kòró kìí pojú kòró
jẹ? Ní báyìí Coro ti pojú kòró jẹ.
Kódà ó pájẹ torí torí ni. Ara wá ń sá
fára, ìbèrù wá gbàlú kan. Olóko o leè
r'oko, ọlọ́nà ò leè yènà. Ọ̀rọ̀ wá di
bóòlọ yà'mi lọ́nà.

Aha! Coro oò sée re o

Bá ò bá rẹ ni bálà, ọlà kìí yá. 

Ṣebí igi àràbà kò lè dágbó ṣe, 
òṣùṣù ọwọ̀ báyìí ló ń gbálẹ mọ̀;
àgbájọ ọwọ la fi ń sọyà.

Ṣùgbọn báwo ni tì ẹ ṣe jẹ
Ògbẹni Ayélabówó tó gbàgbé
pé ayé la bá owó, o gbàgbé
pé owó a máa wón ni, Ọlà a sì
máa lànìyàn mọlẹ̀.

Ọrẹ́ rẹ ní kí òhun fara nù ọ
bíi tológbò, kí ó lè rí owó mú
lọ sí ẹnu. O kọ̀, o ní rárá,
Kólówó sebí olówò Kólòṣì
sebí olòṣì, Kí tálákà ma sẹ
ẹgbẹ́ ara wọn.

Ṣé ìwọ ti gbàgbé wí pé òkè
òkè lọwọ afúnni ń gbé. Ìwọ ò
ṣe fa ọrẹ́ rẹ lọ́wọ́ sókè, fi ọwọ
ọlá raá lórí Kí irun ọlá leè ṣéyọ
lágbárí rè.

Ó kò mọ̀ pé Awo níí gbé
awo ní gbònwọ́, Àtipé owó la
fi ń wá owó. Wọ́n wípé bí a
ò bá rí ẹni bálà, ọlá kìí yá.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí ìlú Ṣakí ògún ọ̀ rọkin ní Huswat Lawal. Ọ sí jé ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ fàfitì Ládòkè Akíntọ́lá (LAUTECH). Ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ède Yorùbá púpò.

*Àṣẹ lóri àwòrán ojú iwé yìí jẹ tí Laolu Arts.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *