Ọmọ bíbí ìlú Ifón ni Abíọ́dún; ó sì fẹ́ràn ìlú rẹ̀ púpọ̀. Ọkàn ò jọ̀kan ẹ̀bùn ni Olódùmarè fi jíǹkí  Abíọdún. Orí rẹ pé púpò; ó ní ìtẹríba; ó ní òtítọ; sọ̀rọsọ̀rọ̀ tó ní àgbékalè sì ni pẹ̀lú. Èyí tó jọjú jù nínú àwọn ẹ̀bùn tí Olódùmarè jogún fún Abíọ́dún ni wípé ó má ń róye ọjọ iwájú. A leè pe Abíọ́dún ni ọmọ ga, ẹsẹ̀ gún-ùn. Ó món lára fò bíi ọ̀lẹ̀lẹ̀ ààwẹ̀. Bí wón bá ní ẹni tí obìnrin kò lọnà tí ó bú sẹkún pé bí eléyìí ò bá jẹ ọkọ ẹni, a sì jẹ àlè ẹni, Abíọ́dún ni wón ń bá wí. Bí ó tilè jẹ wípé àwọn òbí rẹ̀ kò kàwé, inú n wọn a máa dùn wípé àwọn ní ọmọ tí ó gbájú mó ẹ̀kọ. Àríyangàn ni Abíọ́dún jẹ fún àwọn òbí rẹ̀.

Nínú gbogbo àwọn àjọ tí kò rọ̀gbọ̀kú lé ìjọba tí Abíọ́dún ti jẹ ọmọ ẹgbẹ, Yàgò Fún Ìdá ̀mí Ara ni Légbodò ni ààyò rẹ. Kò sí ìdí méjì fún eléyìí ju bí àṣà igbá èmi ara ẹni ti ṣe wọ́pọ̀ láàrin àwọn akẹkọ̀ọ́ àti gbogbo ènìyàn lọ. Abíọdún, bóyá nítorí akitiyan rẹ nínú àjọ náà tàbí nítorí pé Ó mọ ọ̀rọ̀ sọ, ni wón fi jẹ abẹnugan Àj Yàgò Fún Ìdá ̀mí Ara ni Légbodò. Ó ní ìgbàgbọ́ wípé kò sí ìṣòro kankan tí kò ní ojútùú. Fún ìdí èyí, Abíọ́dún má ń gbógun ọ̀rọ̀ ti gbigba èmí ara ẹni nítorí ìṣòro. Bí Abíọ́dún bá rí ẹni tí ó ń ronú àròkàn, ó má ń sọ fún wọn wípé ‘Ojo ni ìṣòro ṣùgbón akoni ni ìwọ. Ìṣòro kò báà ga bíi Òkè Olúmo, kọjú síi kí o sì borí ẹ̀.’ Oríṣiríṣi àmì ẹ̀yẹ ni Abíọ́dún tí gbà fún ìṣe takuntakun tí ó ń ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ wípé ọ̀pọ̀ èmi ni Abíọ́dún tí gbàlà pẹ̀lú gbígbé ogun ti ìṣekú pa ara ẹni.

Ní òwúrò kùtùkùtù Ọjọ́ Ìsinmi kan, aago ìléwọ́ Abíọ́dún dún. Ìyá rẹ lọ́ ń pèé láti sọ fún-un wípé àwọn ti gbé bàbá rẹ dé Ilé Ìwòsàn Ọbáfẹ́mi Awólọ́wò. Láàrin ìṣéjú àáyá, Abíọ́dún ti dé ilé ìwòsàn náà, ó sì béèrè dókítà tí ó ń tọ́jú baba rẹ̀. Dókítà Johnson tí ń dúró de Abíọ́dún láti ṣàlàyé ohun tí ń ṣe baba rẹ̀ fún-un. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹbí ń dúró de Abíọ́dún láti ṣe ògbufọ̀ ohun tí Dókítà Johnson bá sọ fún-un.  Òun nìkan ló kúkú gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì nínú gbogbo wọn. ‘Mr Abbey, your dad’s heart has stopped functioning well and he needs to be operated as a matter of urgency. The only problem now is you have to fly him to India for the surgery and that will cost at least one million Naira.’ Dókítà Johnson sọ fún Abíọ́dún. Dókítà féè má tíì sọ̀rọ̀ tán tí Abíọ́dún fi bú sẹ́kún.

Bí Ìyá Abíọ́dún ṣe rí omijé lójú Abíọ́dún nígbà tí òun jáde kúrò lọ́dọ̀ Dókítà Johnson, ó mò wípé omí ti pọ̀ ju ọkà lọ. ‘Ṣé wón ní ọkọ mi á kú ní?’ Ìyá Abíọ́dún bi Abíọ́dún léèrè. ‘Rárá, ìyá mi. Wọ́n ní a nílò mílíònù mẹ́wàá fún iṣẹ́ abẹ ní òkè òkun.’ Abíọ́dún fèsì. Èsì tí Abíọ́dún fún ìyá rẹ kò yàtọ̀ sí ìtúfọ̀ fún ìyá Abíọ́dún nítorí pé kò sí ibi tí wó n ti máa rí mílíònù kan gan bèlèǹtàsé mílíònù méwàá. Ìbànújẹ́ bá dórí àgbà kodò. Bàbá Abíọ́dún wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn; ìyá reè síì wá nínú Ìbànújẹ́ tóún wa ẹkún mu bíi omi. Kódà, Ìyá Abíọ́dún ti pinu láti jẹ májẹ̀lé tí Bàbá Abíọ́dún bá fi lè kú bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mò wípé Abíọ́dún gbọ́ ìpinu òun níbi tí òun ti ń dáásọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ikú omi ṣe má ń pa àwọn òmùwè tí ikú ogun síì má ń pa àwọn jagunjagun, ikú ìrèwèsì ọkàn ló sáábà má ń pa àwọn asọ̀rọ̀ ìwúrí. Ìrònú àìsówó láti tọ́ju bàbá kò tó ìrònú àìrẹ́ni seni ní pẹ̀lẹ́ tàbí fúnni ní kóríyá fún Abíọ́dún. Ìrèwèsì báa títí tí òun gan pẹ̀lú fi pinu láti jẹ májẹ̀lé. Ó gbàgbọ́ wípé kò sí ohun tí òun ń dúró ṣe láyé tí ìyá àti bàbá òun bá fi le kú. Abíọ́dún gbéra; ó gba ọ̀dọ̀ àwọn tóún ta òògùn ìfínko lọ. Ó béèrè fún sínáípà ike kan. Ẹnikẹ́ni kò bi Abíọ́dún léèrè ohun tí ó fẹ́ fi sínáípà ṣe bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kí ń ṣe àgbẹ̀ nítorí pé kò sí ẹni tí ó leè rò wípé Abíọ́dún, abẹnugan Àjọ Yàgò Fún Ìdá Ẹ̀mí Ara Ẹni Légbodò, leè gbèrò láti pa ara rẹ̀. Bí Abíọ́dún ṣe yọ owó jáde lápó, ìwé pélébé kan jábọ́ sílẹ̀ ṣùgbón Abíọ́dún kò mò rárá. Bí ó ṣe ń lọ́ ní ẹni tí ó ta sínáípà fun-un rí ìwé náà, ó ṣì mú-un. Nígbà tí ó síi wò, ìwé náà káà wípé ‘Mo ko ìwé yìí láti jẹ́ kí gbogbo ayé mò wípé èmi ni mo gba èmí ara mi. Ó wuni ká jẹran pẹ́ lénu ṣùgbón òhùnfà ọ̀fun ò jẹ́. Mó gbìyànjú láti má ro àròkàn ṣùgbón mi ò ní inú à kọ́rọ̀ sí. Bóyá tí mo bá rí ẹni pẹ̀tù sí mi lọ́kàn ni, mi ò bá tí gbẹ̀mí ara mìi. Ó dìgbà!’ Bàbá olóògùn ìfínko fi ariwo ta.  Ó bẹ àwọn ará àdúgbò láti bá òun lé Abíọ́dún mú kí ó má báà gba èmi ara rẹ̀. Kíá, wón ti lé Abíọ́dún mú; wón sì sóó lápá lẹ́sẹ̀ bíi wèrè. Ohun kan soso tí Abíọ́dún ń kígbe ni ‘Ẹ jẹ́ kí n pa ara mi.’

Bí ó tilè jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mo ìrìn àjò Abíọ́dún, Ìyá Abíọ́dún ń retí kí ó dé láti wá gbọ́ ìròyìn ayọ̀ tí àjọ tí kò rọ̀gbọ̀kú lé ìjọba kan, Ìlera Lr̀, mú wá fún Bàbá Abíọ́dún. Ìlera Lr̀ ti san owó ìtọ́jú Bàbá Abíọ́dún àti aláìsàn mésàn-án mìíràn, àjọ náà sì ti ń ṣe àbójútó ìtọ́jú wọn. Inú ìdùnnú yìí ni ìròyìn wípé Abíọ́dún ti fẹ́ pa ara rẹ̀ ti bá Ìyá Abíọ́dún. Ó sáré tẹ̀lé àwọn tí ó wá fún-un ní ìròyìn náà lọ sí ibi tí Abíọ́dún wà, ó sì sọ fún-un wípé ara bàbá reè ti yá. Ìyá Abíọ́dún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tí kò jẹ́ kí òun ṣòfò ọmọ; òun àti Abíọ́dún síì gba ilé lọ. Nígbà tí wón dé ilé, Abíọ́dún ní òun kò gbàgbọ́ wípé ìṣòro kan leè sọ òun di ọ̀daràn tóún ronú ikú àtọwọ́dá. Ó ní òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ni wípé ẹni ìjà ò bá lóún pe ara rẹ̀ l’ókùnrin.

Ó dìde sókè; ó fi ọwọ́ sọ̀yà; ó ní: Àsìkò titó fún mi láti polongo fáyé wípé kò sí ẹni tí ó kọjá àdánwò. Àti pé àdánwò a máa ju agbára ẹni lọ. Fún ìdí èyí, ojúṣe gbogbo wa ni lati jẹ́ alábòójútó àwọn ará àti ọ̀rẹ́ wa. Bí a bá rí ẹni tóún ká gúọ́-gúọ́ kiri, ẹ jẹ́ kí á súnmón irú wọn. Bí a bá rí ẹni tóún kárí bọnú, ẹ jẹ́ ká pẹ̀tù síwọn lọ́kàn. Báyìí ni a ṣe leè dẹ́kún ìwa gbígba èmi ara ẹni.

Nípa Ònkọ̀wé

Akẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Ifásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Gàníyù Saheed Ìṣọ̀lá jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn gbígbé àṣà àti ìṣe Yorùbá lárugẹ. 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *