Ẹ Bọ̀wọ̀ F’ágbà

“Ajá tó r’ólówó ẹ̀ rojú, kín ní ó f’ólówó è se kò tié yé mi.”

—Éégunmọgají Àyìnlá Ọmọwúrà.

Ìrírí kí lọmọdé ní, ìmọ̀ kí lọmọdé mọ̀? 

Ẹ bọ̀wọ̀ f’ágbà. Sebí ẹnu àgbà l’obìí gbó sí.

Àgbà níí t’ọgbọ́n láì gba kọ́bọ̀, òun náà ní ta ìrírí

Láì gba aṣọ kànkan lówó ọmọ. Ìwọ ọmọ tóo y’írùn

Pàkà, tóo lẹ́nu àgbà ń rùn, ǹjẹ́ o ti fọ eyín-ìn rẹ mọ́

Tónítóní, torí ìdúró sinsin kò sí fún ìdàgbàsókè.

Ìwọ náà yóò dàgbà, ìwọ náà yóò darúgbó, lónìí kọ́ o,

Sùgbón ní ọjọ́ ọ̀la. Ìwọ ọmọ tóo rí àgbàlagbà rojú,

Ọgbọ́n kí lo tíì f’ojú rẹ rí, èèmọ̀ kí lo ti fi ojú rẹ kàn?

Ǹjẹ́ o ní ànfààní láti fi ojú rẹ gán-ánní ojú àgbà tó jìn?

Ǹjẹ́ o ní ànfààní láti fi ojú rẹ gán-ánní ẹ̀yìn àgbà tó tè?

Mọ̀ rò wípé ìrírí ló jin ojú àgbà. Mọ̀ rò wípé iṣẹ́ ló mú

Èyìn àgbà tẹ̀. Ọmọdé tó gbọ́rọ̀ s’ágbà lẹ́nu

Lónìí, níí di àgbà gidi lọ́la; èyí tí ò gbọ́, á di ẹni ìranù.

Èdè Yorùbá.

Ǹjẹ́ o ti gbọ́ pé ède Yorùbá ti ń di omi à mú sinwọ́?

Ǹjẹ́ o ti gbọ́ pé ède Yorùbá ti ń di omi à mú f’ọsẹ̀?

Lóòótọ́ la rẹwà lásà, lótitọ́ la rẹwà n’íse. Sùgbọ́n

Ǹjẹ́ a rẹwà ní ìsesí sí ède wa bí?

Ǹjẹ́ a rẹwà ní ìsesí sí ède wà, Yorùbá?

Èdè tí a sọnù bí òkò, tí a mú òmíràn gẹ́gẹ́ bíi fàdákà.

Èdè tí a gbé sọnù bí ibi ọmọ, tí ó di ohun àíjírí bíi

Èèpo ẹ̀gúsí. Gẹ̀ẹ́sì, mo kí ọ kú àseyọrí! O kó wa lérù,

O sì tún kó wa lénìyàn pẹ̀lú. Mo kúkú kí ọ kúusé,

Fún èdè rẹ tí ó sọ ẹ̀ẹ̀kẹ́ Yorùbá di iléègbé, tí o sọ ẹnu

Ọmọ Odùduwà di ohun ibùsùn. Mo kí ọ dáradára.

Mo pe gbogbo ọmọ Yorùbá àtàtà tó wà ní àgbáyé

Pátá: mo pè yín nílé Ifẹ̀, ìlú Odùduwà, níbi t’ómi

Yorùbá ti sàn wá. Mo pè yín ní ìlú Ìbàdàn,

Ìlú Àjàyí Ògbórí ẹfòn sá fìlafìla, ní ìlú

Basọ̀run Ògúnmọ́lá, alágbàlá jáyàjayà. Mo pè yín ní

Ìsẹ́yìn, ilú Ẹbẹdí, ilú òkè mẹ́ẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Atamáfọn,

Olúòfì, Ẹyinjùẹ́, àti Ẹbẹdí tó tóbi jù  láàrín wọn.

Mo pè yín l’Ògbómọ̀ṣọ́ níbi wọ́n tíí jẹkà kí wọ́n tó mùkọ

Yangan. Mo pè yín, ẹ̀yin ọmọ Yorùbá ní tilé-toko:

Mo pè yín ní Ìjẹ̀bú. Mo pè yín ní Ìjẹ̀sà. Mo pè yín

L’Èkòó arómi sá lẹ̀gbẹlẹ̀gbẹ. Mo pè yín lókè òkun

Gbogbo: Mo pè yín l’Amẹ́ríkà. Mo pè yín ní ilú ọba

Bìnrin nì, níbi tí èdè Gẹ̀ẹ́sì ti sẹ̀ wá. Mo pè yín ní

Ilẹ̀ asálẹ̀ gbogbo. Mo pè yín ní Índíà. Mo pè yín ní

Gbogbo ilè Faransé kááfàtà, tó fi mọ́ Tógò, àti orílè-èdè

Benin pẹ̀lú. Mo pè yín ní gbogbo ìhà àgbánlá ayé pátápátá,

Tí ẹ wà tí ẹ ti ń ṣe oge, ọ̀ṣọ́, àti gbogbo oríire tí ẹ̀dá

Ọmọ Ádámọ̀ ń se, pé kí ẹ yéé ta èdè Yorùbá dànù

Bíi ọfà, pé kí ó lọ pe ikú ara rẹ̀ wálé. Pé kí ẹ yéé dá iná

Sun igi àràbà Yorùbá tí ẹ̀ ń gbin ti ìrókò òmíràn. Pé

Kí ẹ yéé gba ẹwà Yorùbá kúrò lójú  àwọn ògo wẹẹrẹ

Òla pèlú igi, fún èdè àtọ̀únrìnwá. Mo pè yín, gbogbo

Ọmọ káàárọ̀ oòjíire, pé kí á bẹ̀rẹ̀ láti máa gbé èdè wa

Lárugẹ ní gúsù, àti ní àríwá, ní ìyọ oòrùn, àti ìwọ̀ oòrùn

Gbogbo àgbáyé pátápátá. Kí á kọ́  àwọn ọmọ wa ní

Èkọ́ ède Yorùbá láti oríi ‘a’ dé oríi ‘y’. Ọmọ Yorùbá,

E máse jẹ́ kí èdè wa kó sọnù bí òkò, kó di abẹ́rẹ́ tó kó

Sókun. Kí á sì má gbàgbé òwe àgbà tó sọ pé “Ohun tí a 

Bá fi s’ílẹ̀ lẹnu ewúrẹ́ ń tó”. Ẹ jẹ́ kí á gbé èdè wa lárugẹ.

Nípa Ònkọ̀wé

Àrásí Kamaldeen Moyọ̀sọ́rẹ jẹ́ ọmọ bíbí Òkẹ̀-Ògùn, ní Ìlú Isẹ́yìn. Ó jẹ́ ẹni tó máa ń kọ ewì ní èdè Yorùbá, àti Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ewì rẹ̀ a máa dá lé lórii àsìkò, ìdàgbàsókè, èrè ogun, ìfẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

*Àṣẹ lóri àwòrán ojú iwé yìí jẹ tí ọmọ yoòbá

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *