Kí ilẹ̀ tó pa òṣìkà, ohun tí ó dára yóó ti bàjẹ́

Ní ojoojúmọ́ ayé mi ni mo máá ń ronú nípa ayé àwa ẹ̀dá, nípa àditú ayé tí ó ń fi ìgbà gbogbo ṣ’emí ní kàyéfì. Ní ojoojúmọ́ ayé mi ni mo máá ń ronú nípa bí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ṣe ń lo ìṣẹ̀mí ayé tí ó bíńtín, ìṣẹ̀mí ayé tí ó ń fi ojoojúmọ́ kọmí lóminú. Ni igba gbogbo tí mo bá jí ni mo máá ń gbé ọlá àti ògo fún Elédùà Ọba mi, Ọba tí ó mọ mímí ẹja nínú omi, Ọba tí ó mọ rírọ̀ ojo àti ríràn òòrùn. Ọba tí ó fi ayé ṣe ìdánwò fún àwa ẹ̀dá àti ẹranko, Ọba tí ó ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà tí ó bá wù ú, Oba tí ó mọ ìsẹ̀mí àwọn ẹranko inú igbó, Oba tí ó mọ bí ewé sé ń jábọ́ lára igi tí kì í nigi lára, Oba tí ó fi sańmọ̀ se ibùgbé, tí ó fi ilẹ̀ ṣe ìtẹ́ ìgbẹ́sẹ̀lé, tí ó wèwù ọlá àti iyìn, Ọba tí ó lórúkọ àkàmáleèkàtán. Kábíyèsí rẹ Elédùà Ọba mi. Ọba tí ó tí ń bẹ kí àwa tó ma bẹ, Oba tí yóó sì ma bẹ nígbà tí àwa kò bá sí mọ́. Ṣèbí Ọba yíì náà ló mọ ikú tí ó pa Bàbá mi, Àrẹ̀mú ọmọ ọlá, ọmọ atẹ́nígbaṣọ, ọmọ ìràwé kì í dájọ́ ilè kó sùnkè.

Ẹ̀yin ará, ikú á pẹni à ń pè ikú á pẹni tí ń peni. Nítorí rẹ̀ ni mo ṣe máá ń sọ pé kòsí ipò tí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan bá wà láyé, kí á gbìyaǹjú kí á bẹ̀rù ọjọ àtisùn, kí á dúró ti Elédùà, kí á má sáré mọ́tò kọlu kẹ̀kẹ́, kí á má sọ pé sùúrù lérè kò dára ju ọlọ́runṣògo lo. Ní gbogbo ibi tí a bá wà láyé, kí á ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run gidi gan an ni, kí á sí mọ̀ pé oníkúlúkù wa ni yóò padà sí ọ̀dọ̀ Elédùà ní ojọ́ ikú bádé, àtipé ènìyàn ò sunwọ̀n láàyè, ní ojọ́ a bá kú là á dère. E jẹ́ á ma a rántí pé òtítọ́ ni ó ma ń gbéni ga, ìtẹríba sì jẹ́ olórí ohun gbogbo, ìfẹ́ òhun ìrẹ̀lẹ̀ kò gbẹ́yìn níbẹ̀ pẹ̀lú. Gbogbo ohun a bá se ni a ó kẹ́san rẹ̀. Nítorí rẹ̀ ni ó se da kí á mọ̀ dájú pé ènìyàn kò ní gbin àlùbọ́sà kó wu ẹ̀fọ́, ohun ti ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan báṣe ni yóò gbà.

Ní ojọ́ tí Bàbá mi kú ni mo mọ ohun tí wọ́n ń pè ní ayé òfimọlàkà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí mò ń so yì́i, Bàbá mi pèmí sí iyẹ̀wù rẹ̀, ó sàdúrà fúnmi, omijé lé sí ojú rẹ̀ róró, ó ń mí pokanpokan bi o ṣe ń ṣe àdúrà fun mi bi eni ti ìsúkèé mú. Kì í kúkú ṣe pé ọjó àkọ́kọ́ tí Bàbá mi yóò ṣe àdúrà fúnmi rè é, sùgbọ́n omijé tí ó lé s’ójú rẹ̀ kò fi bẹ́ ẹ̀ yé mi. Mo wò wọ́n lójú, omijé sì bẹ̀rè sí kán tó-tó-tó lójú tèmi náà. Lẹ́yìn èyí, mo gbọ̀nà ilé ìwé lọ. Mo fi Bàbá mi sílẹ̀ pẹ̀lú Ìyá mi ati orogún Ìyá mi, Ìyá Morádékẹ́. Pípadà tí ń o padà sílé lọsan ọjọ́ náà, mo bá èrò bìbà ní iwájú ilé wa. Èrò náà pọ̀ tóbẹ̀ gẹ́é tí mo ṣe kọ́kọ́ ṣiyèméjì bóya ilé wa ni èrò pọ̀ sí tàbí ilé wa kọ́. Nígbà tí mo sún mọ́ àwọn èrò náà daada, mo rí Ìyá mi tí ó gbára yílẹ̀, mo sì rí Ìyá Morádéké náà ní orí ìdúró, gbogbo ara rẹ̀ tùtù jingbinni bi ẹni òjò pa, òjò kò kúkú pa a , omi ẹkún ló pọ̀ tó bẹ̀ẹ̀. Bóyá ayé ni mo wà ni, abi ọ̀run ni, ọ̀rọ̀ náà kòyémi àfìgbà tí mo bára mi ní ilé ìwòsàn. Ní òwúrò ọjọ́ kejì tí mo lajú, gbogbo ara mi sí ń gbóná bi irin alágbẹ̀dẹ. Mo gbójú wòkè, mo rí ìyá mi, omijé sì jábọ́ lójú mi pooropo.


Ẹ̀yin ará, ọmọ atàpáta dìde paraku nimí. Bàbá mi kò lówó ko tó kú, bẹ́ ẹ̀ sì ni kò ra mọ́tò kí ó tó papòdà. Ní ìgbà gbogbo ni ó sì máá ń jẹ́ kóyéwa pé àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tannijẹ, àtipé gbogbo iṣẹ́ tí ẹ̀da kọ̀ọ̀kan bá ń ṣe, kí olúwarẹ̀ tẹ’ra mọ́n. Bàbá mi kórira ìmẹ́lẹ́ àti òròjú, ó sì gbìyànjú púpọ̀ láti kìlọ̀ fún wa nípa wíwo aago aláago ṣiṣẹ́. Ní ọ̀dọ̀ Bàbá mi ní mo ti kọ́kọ́ gbọ́ pé àyànmọ́ ẹ̀dá sọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àtipé ènìyàn wáyé ní ibejì kòní kí wọ́n ṣoríire bákan náà. Bàbá mi ní pé gbogbo ibi tí a bá dé láyé, kí á má gbàgbé àtẹ̀yìnwá, kí á sì rántí àwọn tí wọn kò rí ṣe, àwọn ọmọ òrukàn tí wọ́n ń fi ojoojúmọ́ ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, àwọn tí wọ́n ń gbàdúrà kí Elédùà dáwọn lóhùn. Ẹ̀kọ́ pọ̀ tí mo kọ lára Bàbá mi. Ṣé ti bí ó se gbìyànjú láti ránwa lọ sílé ìwé ni, àbí bí ó ṣe ṣé ní pàtàkì fún wa láti mọ iṣẹ́ ilé ní ṣíṣe. Bàbá mi kò fi ọmọ kan kẹ́ kan; gbogbo wa ni ó tọ́ bákan náà. Kódà, àbúrò mi tí ìyá mi bí kẹ́yìn, Fadérẹra, jẹ́ ọmo dáradára. Fadérẹra kí ì rojú, ó sì jẹ ọmọ tó já fáfá.

Lẹ́yìn ikú Bàbá mi ni mo gba ọ̀nà Èkó lọ fun iṣẹ́ ajé, ojú ri to ni ìlú Èkó. Ní ojọ́ tí ń ó sì kúrò ní Ilé, ìyá mi pèmí sí inú iyẹ̀wù rẹ̀ láti sàdúrà fún mi. Ìyá mi wòmí lójú, ẹ̀rù sì kún ọkàn rẹ̀. Ìyá mi kì í fiwá ṣeré rárá. Ó fẹ́ràn láti ma a rí wa ní akàtà rẹ̀. Kò fẹ́ kí ǹǹkan ìjàm̀bá ṣewá. Ìyá mi gbìyànjú púpọ̀ lórí wa. Ìyàwò daada ni ìyá mi jẹ́ lọ́dọ̀ Bàbá mi. Ní gbogbo ìgbà tí ara bàbá mi kò bá yá, ìyá mi á suugba Bàbá mi, yóò ma a sáré lọ sókè sódò, yóò ma a bẹ Elédùà fún ìsẹ́gun lórí àìsàn Bàbá mi. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ènìyàn ní ń bẹ lẹ́yìn orò lórò fí ń ké, àtipé àjejì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù dórí, àgbájọwọ́ lafi ń s’ọ̀yà. Ẹ̀wẹ̀, ojú tí yóò bá báni kalẹ́ kì í tàárọ̀ ṣe ipin. Ìyá mi gbìyànjú fún Bàbá mi púpọ̀. Ó ṣe gudugudu méje yááyá mẹ́fà nínú ayé Bàbá mi kí ó tó kú. Sé ijọ́ tí Bàbá mi kò lówó lọ́wọ́ ni àbí ijọ́ tí Bàbá mi re ìrìn àjò tí owó tán lọ́wó wọn? Nígba náà sì rè é, ayé kò tí di ayé ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ìyá mi ní o gbéra nị́lẹ̀, tí ó lọ bá Bàbá mi níbi tí ó lọ, tí ó sì fun ní owo ní owó láti padà sílé. Mélòó la fẹ́ kà nínú eyín adípèlé? Ṣé ti ọjọ́ tí orogún ìyá mi, Ìyá Mọrádékẹ́ kọ́’lé èébú sí ìyá mi lára ni àbí ọjọ́ tí ìyá mi padà dé làti oko ẹ̀gẹ́ ti kò sí rí owó tí o fi pamọ́ sínú ìgbànú ré mo ní kí n mẹ́nu bà? Sùgbọ́n Ìyá mi ti jẹ́ kò yémi pé nínú òláà nínú òfíì ní ọmọ páńdọrọ n dàgbà si i. Gbogbo bí ó se wù kí ǹǹkan lè tò ní ayé, tí olúwarè kò bá sọ ìrètí nù, gbogbo ǹǹkan n bọ̀wá dára. Ìyá mi sì tún jẹ́ kòyémi pé ilé ayé kò ṣé pọ́nlé, kò sì sé é kó mọ́ra bí ọmọ adìẹ. Gbogbo ohun tí a ní ni a ó dá kalẹ̀ tíkú bádé. Ṣèbí àdúrà wa ni pé kí iwájú wa dárá, kí ẹ̀yin wa sì ma bàjẹ́ pẹ̀lú.

Ìlú Èkó ni mo wà tí ìpè fi wọlé pé ará ọré Bàbá mi, Adéróunmú kò yá. Ìyá mi sì jẹ́ kóyémi pé Bàbá náà sọpé àwọn fẹ rí mi ni kíákíá. Mo wojú aago mi, mo sì ri pé aago mẹ́fà ti lù. N ò ní rí ọkọ ni idikọ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí òwúrọ̀ ọjọ́ kejì se mọ́ ni mo gbéra, ó di ìlú Òkehò, níbi tí ọ̀rẹ́ Bàbá mi kọ́ ilé sí, níbi tí ó tí ń gbádùn ayé rẹ̀ pẹ̀lú àwọ́n ìyàwó àti ọmọ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò mọ Bàbá náà dáradára, sùgbọ́n Bàbá mi sọ díẹ̀ fún wa nípa Bàbá yìí. Bàbá mi jẹ kó yémi pé ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ni àwọn jẹ́, àtipé nígbà tí àwọn wà ní ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ ní ìlú ìwéré-ilé, àwọn méjèèjì a máa jọ kọ́wọ́rìn ni. Kódà, tí ọdún bá dé, aṣọ kan-ná ań ni àwọn yóò wọ̀. Ọ̀rẹ́ àwọn méjèèjì di ìlúmọ̀ọ́ká. Tí ó bá di kí á jó, òkòtó ni àwọn méjéèjì. Bàbá mi a máa bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ da apara nípa bí àwọn méjéèjì ṣe lọ sóde ijó lọ́jọ́ kan tí wọn kò sì rántí láti lọ sí ilé. Nígbà tí ó dalẹ́, Ìyá Bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn méjéèjì kiri. Ìyá Adéróunmú náà kò sùn. Ọ̀rọ̀ di ọlọ́mọ ò mọ mọ, ó di ọmọ ẹni kú ó sàn ju ọmọ ẹni nù lọ. Nígbà tí òwúrò mọ, àwọn méjéèjì padà sí ilé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe wọn kò bá àwọn méjéèjì wí bí ó ṣe yẹ kí wọ́n bá won wí, Bàbá mi sọ fún mi pé láti ọjọ́ yẹn, àwọ̣n kò tún pẹ lóde ijó.


Bí mo ṣe dé ìlú Òkehò ni mo lọ sí ilé ọ̀rẹ́ Bàbá mi. Bí mo sì ti dé bẹ̀ ni mo bá Bàbá yìí lórí ìbùsùn. Mo bá ọ̀kan lára ìyàwó wọn nínú ilé náà pẹ̀lú wọn. Mo súnmọ́ Bàbá yìí, mo sì ri pé ara won gbóná gan an ni. Mo bèèrè ohun tí wọ́n ti lò, ìyàwó yìí sì dámi lóhùn pé àwọn ti lo àgbo fún wọn. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Bàbá yìí fojú pèmí si ọ̀dọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀ àgbà. Bí wọ́n sì ti fẹ́ kẹnu bọ̀rọ̀, omijé bẹ̀rẹ̀ sí kán tó-tó-tó ní ojú wọn. Ẹ̀rù bà mí gidi gan-an. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Bàbá yìí kẹnu bọ̀rọ̀: Èmi àti Bàbá rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. A jọ dàgbà nínú ìlú kan na ni. Ọ̀rọ̀ àwa méjéèjì dàbí ìgbín àti ìkarahun.

Gbogbo ibi tí ó bá ti ń lọ ni èmi náà ń lọ. Mo rántí pé ní ọjọ kan, kí Bàbá rẹ tó fẹ́ ìyá rẹ̀, èmi àti Bàbá rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá onísẹ̀gùn kan ní ìlú Ayétòrò. Ìdí tí a fi lọ sí ìlú yìí ní ọjọ náà ni pé ṣiṣẹ́- ṣiṣẹ́ èmi àti Bàbá rẹ̀ dàbí ọ̀lẹ. A ti gbìnyànjú títí láti rí tajé ṣe, kọ́ lọ́mọ ń sorí lafi gba oko ilé aláwo lọ. kòsì fẹ sí iṣẹ́ tí èmi àti Bàbá rẹ kò se rí. A ti ṣiṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rí. Lẹ́yìn ilé ìwé girama, èmi àti Bàbá rẹ ṣiṣẹ́ káàkiri, sùgbọ́n tàárọ̀ kò bá talẹ́ lọ́wọ́ wa rí. A gbìyànjú láti làlùyọ, láti lówó lọ́wọ́, láti jẹ́ èèyàn pàtàkì ní àwùjọ. Nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ Bàbá oníṣègùn yìí, Bàbá oníṣègùn yíí jẹ́ kó yé wa pẹ́ ọmọ ológo ni Bàbá rẹ, àtipé tí ó bá dọjó alẹ́, Bàbá re yóò lówó lọ́wọ́ ju Abíọ́lá lọ. Kódà, Bàbá rẹ yóò di ìlú mòń-ká ènìyàn. Yóò di ẹni ayé ń fẹ.  Bàbá oníṣègùn jẹ kó yé èmi náà pé èègún ìdílé kan ńbẹ tí ó ń da èmi láàmú láti ọjọ tó ti pẹ́, àtipé tí wọn kò bá ré èègún náà dànù, n ò ní lówó. Bẹ́ẹ̀ sì ni n ò ní ní ìgbéga. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bàbá rẹ dúró tìmí, àti pé kò jẹ́ kí n ronu púpọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, gbogbo ìgbà tí mo bá ti ń rí Bàbá rẹ ní inú mi kì í dùn sí. Mo mọ̀ pé bópẹ́ bóyá Bàbá rẹ yóò lọ́wọ́. Èmi yóò sì wà bákan náà. N ò dúró bí omi adágún.  Ọmọ mi, dákun, tí ẹ̀dá kan bá wà tí ́ó bá ń wùwà ìbàjẹ́ sí ìwọ, jọ̀wọ́ má ṣe wu ìwá ìbàjẹ́ sí onítọ̀hún o. Ọmọ mi, tí ẹ̀dá kan bá wà tí ó ń wa ìfàsẹ́yìn rẹ, dákun má ṣe wá ìṣubú onítòhún. Ìdí tí mo fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni pé bópẹ́ bóyá ẹ̀san á ké lórí ṣèkàṣèkà. Àwọn ọ̀bàyéjé kò sì ní rí ọ̀nà àbáyọ̣. Sì ma rántí pé kò sí bí a se lè pẹ́ láyé tó, a ó kúkú pẹ́ nínú saare jùbẹ́ lọ. Ọmọ mi, Bàbá rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí yóò papòdà. Mo sì rántí pé mo fi májèlé sínú ọtí ẹlérìndòdò tí mo fun mu. Sùgbọ́n n kò rántí pé bógún bá jẹlo ọgbọ̀n á jẹ bọ̀. Mo ti gbàgbé pé Bàbá rẹ kò wùwà ìkà sí mi rí, àtipé pẹ̀lú bí gbogbo ǹǹkan kò ṣe dára tó, Bàbá re á tún ma fún mi nínú owó tí ó bá rí. Ọmọ mi, dákun foríjìmí.

Ẹ̀yin ará, bí Bàbá yìí ṣe sọ̀rò yìí tán ni Bàbá náà jáde láyé. Ẹsẹ̀ mi sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Orí mi bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo. N ò mọ̀ ohun tí mo lè ṣe. Lójijì mo ké tòò bí ẹni tí a nà ní ẹgba, àwọn ìyàwó bàbá náà sáré sí ọkọ wọn, wọ́n ń pè bí i kí ó dìde nílẹ̀ sùgbọ́n ẹran ti lọ kí ọlọ́dẹ kó tó maa ṣe súẹ̀súẹ̀. Kò pẹ́ tí èrò tipé bàbì sínú ilé. Ẹni tí ó ń sunkún ń sunkún, ẹni tí ó ń fò sókè ń fò sókè, èmi náà ń tara ní ẹ̀gbẹ́ kan bí ẹni da omi ata sára. Mo yọ́ gúlọ́gúlọ́ bí ológbò. Mo kúrò ní bi òkú mo jòkó mò ń wo sùn-ùn bí ẹni ọkọ̀ jásílẹ̀. Ohun tó ń pami lẹ́kún pọ̀. Sé ti bàbá mi tí ó kú ikú àítíjọ́ láti ọwọ́ ọ̀dàlẹ̀ ọ̀rẹ́, àbí ti ọ̀rẹ́ bàbá mi tí ó fò sànlẹ́ bí ó ṣe ń ròyìn iṣẹ́ ibi tí ó ṣe. Àṣé lòótò lòwe àwọn àgbà pé kí ilẹ̀ tó pa òṣìkà, ohun tí ó dára yóó ti bàjẹ́. Págà! ǹǹkán ṣe. Mò ń wo òkú ọ̀rẹ́ Bàbá mi ní orí ìbùsùn, àdìtú ayé sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yé mi pé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Láìpẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní palẹ̀ òkú Bàbá náà mọ́. Mo wo ojú ago. Mo rí pé ọjọ́ ti lọ. Mo rìn díẹ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà, mo rí ọlọ́kọ̀ kan. Ilé yá.

Ǹjẹ́ ìwọ ń gbé ní ìlú Ìbàdàn? Ǹjẹ iwọ náà fẹ́ le kọ èdè Yorùbá báyìí? O le darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òǹkàwé Àtẹ́lẹwọ́, wó línkì yìí láti fi orúkọ sílẹ̀

Rasaq Malik Gbọ́láhàn jẹ́ akẹ́kọ̀ gboyè nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ilé ìwé gíga fásitì ilú Ìbàdàn. Ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn àṣà àti ìṣe, àti pé ó ní ìgbàgbọ́ pé èdè abínibí ni ọ̀nà tí a lè fi gbé ìlú lárugẹ. Ó tún jẹ́ ẹni tí ó máá ń kéwì, ó sì tún fẹ́ràn láti ma ka ìwé Yorùbá. Ó ń ṣiṣẹ́ lórí ìtàn àròkọ rẹ̀ lọ́wọ́.

Comments

  1. Akatunka ni itan yii oo…O dun bi oti elerindodo to tutu jojo…O ko ni lopo ogbon, o finimona oye, beeni o si tun n tonisona…Mo ki Onkowe pe o ku ise opolo oo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *