Ènìyàn
Ènìyàn o, Ènìyàn yán
Ènìyàn a b’ìdí yàn àn yán o
Ènìyàn Òṣèlú, Ènìyàn ọ̀jẹ̀lú
Ènìyàn tí ń f’agbáda gba agbada alágbẹ̀dẹ
Ènìyàn tí ń f’ọ́wọ́ ọlá gbanilójú
Ènìyàn a ṣ’enitán, a tẹsẹ̀ mọ́rìn.

Ènìyàn èké, Ènìyàn alábòsí
Ènìyàn lo ni màá jo lọ, mò ń wẹ̀yin rẹ
Boo bá de kòtò, wọn à sì padà
Taló ṣe’lá ti’lá fi kó
Ta ló ṣe’kàn to fi wẹ̀wù ẹ̀jẹ̀
Ta ló ń ta’mọ tiye, Ta ló ń na’mọ na’ye?
Ṣèb’Énìyàn nàá ni.

Ènìyàn lo gbinṣu tó fẹ́ fi k’ágbàdo
Ṣè b’Énìyàn lo gbinlá tó fẹ́ fi j’ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀
Boo r’ẹ́ni o sá,
Boo r’èèyàn, à ní o ná fẹ́lẹ́ ọ̀rẹ́ẹ̀ mi
Ènìyàn ò sunwọ̀n, ọ̀rẹ́ẹ̀ mi
Ènìyàn ṣ’òro.

 


Ọ̀rẹ́dọlá Ibrahim jẹ́ akẹ́kọ́ gboyè ìmọ̀ òfin láti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ìbàdàn. O jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Òmù-Àrán ní ìpínlẹ Kwara nibi tí o ti ni àǹfàní láti kọ́ púpọ̀ nípa iṣe àti àṣà Yorùbá l’ọ́dọ̀ ìyá bàbá rẹ̀ – Alhaja Mọ́ríamọ̀ Ayélàágbe Ọ̀rẹ́dọlá. Ìlú yìí nàá ni o ti lọ ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama níbi tí ó tún ti ní àǹfàní àti kọ́ nípa ẹ̀kọ́ Yorùbá láti ọ̀dọ̀ àwọn òlùkọni tó dágánjíá tí wọ́n sì tún múnádoko pẹ̀lú. Ó k’ẹ́kọ́ jádé ní ilé ẹ̀kọ́ girama Government Secondary School Òmù-Àrán gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ́ tó yege jù lọ ní èdè Yorùbá. Fún ìgbà dìè, Ibrahim ti ṣe ìwọ̀nba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Oníṣòwò kékeré, o sì tún jẹ́ Akéwì, Òǹkọ̀wé, Oníròyìn àti Òṣèré Akẹ́kọ́ ní èdè gẹ̀ẹ̀sì àti ní èdè Yorùbá. Ibrahim jẹ́ ara àwọn òlùdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́, ilé iṣẹ́ SkillNG àti ìwé ìròyìn orí afẹ́fẹ́ ThePageNg. Ìwé lítírésọ̀ Yoruba tí ó fẹ́ràn jùlọ ni Eégún Aláré láti ọwọ́ Láwuyì Ògúnníran. Ibrahim jẹ́ olùkáràmáisìkí ìmọ̀ àti orúkọ rere, o sì ní’gbàgbọ́ pé àpèrè Àtẹ́lẹwọ́ yío ṣe iṣẹ́ takun takun fún ìràpadà ohun to ti sọnù lọ́wọ́ àwọn ọmọ Yorùbá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *