Oore Ló Pé Oore ló pé Ẹ jẹ́ á ṣoore Ìkà ò pé Gbogbo Mùtúnmùwà! Bó o bá ṣe é ree Wà á kẹ́san À’tore à’tìkà Méjèèjì l’ẹ̀sán ń bẹ fún Dúró ná ọ̀rẹ́, Emi la fẹ́ sọ nípa à rẹ bóo bá lọ tán? Ṣèrántí wí pé aríṣe laríkà, Aríkà ni baba ìrègún. Ìwọ ò gbọdọ̀ jùmí, Èmi ò gbọdọ̀ jù ọ́, Ọ̀rẹ́minú rẹ o yà á ní wèrè. Ìyá tó jìyà tó jìṣẹ́, Ẹ fi ṣẹ́gi ọlà, Ìkà á ko níkà bó bá yá, Ọlọ́run àtijọ́ níí pẹ́ ko tó mú ni. Ṣore ṣore! Ìwọ ṣá màa ṣore lọ Ènìyàn le è ṣoore gan k'íbi ó foni dá Oore ló pé Ìkà ò sunwọ̀n Ẹní bá ṣe rere a rí ire mú, Ẹní bá sì ṣ'ebi náà kò ní sàì ríbi bó pẹ́ bó yá. Màá dáa dúró, kò ní le gòkè, Màá b’ògo ayé e rẹ̀ jẹ́, Kí lo fẹ́ gbà níbẹ̀ gan? Rántí pé àtunbọ̀tán ìkà ò da Ìgbẹ̀yìn olubi kìí ṣunwọ̀n rárá. Ẹ̀ bá jía gbé ìwà ore ṣíṣe wọ̀ bí ẹ̀wù. Oore lópé, Ìkà ò dára.
Ọ̀rọ̀ Nípa Òǹkọ̀wé:
Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a bí ní ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.
Àwòrán Ojú ìwé yìí jẹ́ ti Economic times image https://m.economictimes.com/wealth/plan/four-ways-you-can-help-poor-people-around-you-with-financial-planning/articleshow/69278206.cms