Ìdùnnú a ṣubú lu ayọ̀ 
Lọ́jọ́ a bá bímọ tuntun sáyé 
Tẹbítará a kí túńfúlù káàbọ̀.    
Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ 
Tóṣù ń gorí oṣù  
Ìrètí bàbá ni kọ́mọ ó dàgbà 
Ìrètí ìyá ni kọ́mọ ó dẹni gíga. 
Àmọ́ ọmọ kọ̀ kò rá 
Túńfúlù ìjọ́sí fárí gá kò rìn. 
Àwọn tí wọn dìjọ dáyé 
Gbogbo wọn ló ti ń sáré kiri 
Àwọn tó dìjọ jẹ́ irọ̀ 
Lòbí ti ń jẹun wọn. 
Ìyá ń tójú bọlé aláàfáà 
Bàbá ń fọ̀rọ̀ lọ aládúrà 
Wọn ò gbẹ́yìn nílé oníṣègùn
Nítorí kọ́mọ ó lé dide nàró 
Ọmọ kọ̀, kò rá kò sì tún rìn. 
Àsẹ̀yìnwá Àsẹ̀yìnbọ̀ ìgbìyànjú 
Wọ́n ní kí wọn ó béèrè lọ́wọ́ ìyá
Wọn ni kí wọn ó tẹ baba nínú. 
Torí ọmọ tó kọ̀ tí kò rìn yín 
Díẹ̀ lọ́wọ́ ìyá díẹ̀ lọ́wọ́ baba. 
Kò pẹ́ kò jẹ́ jìnà 
Ọmọ tí a wí bẹ̀rẹ̀ sí í rìn 
Ọmọ ọ̀hún dàgbà lójú òbí ẹ̀ 
Ọmọ ọ̀hún pọ́dún méjìlélọ́gọ́ta 
Kò ì lè dá bùkátà gbọ́
Ọmọ tọ́jọ́ orí rẹ̀ kìí ṣe kèremí 
Tí ò mọ dàbìdábí 
Kàyéfì ńlá ló jẹ́ fára àdúgbò. 
Ọmọ yìí ó le dóhunkóhun ṣe 
Bọ́mọ ọ̀hún ò bá dọ́dọ̀ ará ilé kejì 
Kò le rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu lójúmọ́ 
Ìkòríta mẹ́ta tó ń dààmú àlejò 
Lọ̀rọ̀ ọmọ kàyéfì tákéwì ń wí. 
Àwọn olóye lọ̀rọ̀ mi le e yé 
Ṣàṣà èèyàn ló le mọ̀dí àṣàmọ̀

Nípa Òǹkọ̀wé:

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.

Àwòrán Ojú Ìwé Yìí Jẹ́ Ti Culture Trip.

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *