Okùn Ìfẹ́ Yi!
Ìfẹ́ pọ́gbọ̀n, ó jọgbọ̀n Ìfẹ̀ pégba, ó jugba Ìfẹ́ pérínwó, ó jurínwó Ìfẹ́ẹ̀fẹ́ táyé fẹ́lá lóko Kò ju kí wọ́n ríhun filá pa lẹ́nu Ìfẹ́ẹ̀fẹ́ táyé fẹ́kàn lóko Kò ju kí wọ́n ríhun fikàn jẹ létè Ìfẹ́ tÓlú dá sáye Ìfẹ́ tÉdùmàrè dá sí dúnníyàn Àní ìfẹ́ tỌ́lọ́run fi sáàrin ọmọnìyàn Kò kéré rárá, wàláì, kò wínrìn Ìfẹ́ ńlá Ìfẹ́ tó kàsíàrà LOlú wò ṣùn-ùnṣùn Tó fi sáàrin olùfẹ́ méjì bọ́mọọ̀yá Adífá fún Wàhábù ọmọ Bákàrè A bù fún Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín ọmọ Bákàrè Tí àwọ́n méjèèjì dì jọ ń ṣòwò ìfẹ́rìnpọ̀ Wàhábù ò fi Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín pa mìídìn Ó ṣe tán láti fẹ́ ẹ láya Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín náà sì rèé Kò fìgbà kan jẹ́ Wàhábù ní ‘rárá’ Kò pẹ́ Kò jìnnà Wàhábù gboko àdúrà lọ Ni Wáídù bá ń fadùn sífẹ̀ẹ́ àwọn Kò pẹ́ sí i Kò jìnnà púpọ̀ Lòjò oyin bá ń sọlẹ̀ lẹ́ẹ̀dẹ̀ wọn Ẹsẹ̀ tí wọ́n gbé, ijó ni wọ́n ń jó Wọ́n ṣẹnu kótó mórin kọ Ọpẹ́ yẹ wá Àláù a dúúpẹ́ 2x Ẹni tí ò dúúpẹ́, ọwọ́ rẹ̀ ló wà Ọpẹ́ yẹ wá Àláù a dúúpẹ́ Ṣèbí ohun a bá fẹ̀lẹ̀ mú ní í rọ̀! Koko lohun afagbára mú ń le Orin ọpẹ́ ò ní wọ́n lẹ́ẹ̀kẹ́ àwa. Òréré rẹ ló yẹjú, Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín Ẹyẹlé ló yẹlé Alábẹ̀kẹ́-Ọ̀kín tèmí yẹ mí láya Aya bí iyèkan ẹni Ìyàwó bí ọbàkan ẹni Olólùfẹ́ bí olùkù ẹni Aya ẹni ní í fIfá hanni Bàbá ẹni kì í fIfá hanni Ìyá ẹni kì í fIfá hanni Ìyàwó nìkan ló lè fawo hànnìyàn Ohun tí n bá ní N óò máa bólólùfẹ́ mi jẹ… Imú ló ni kóńbó Àgbọ̀n ìsàlẹ̀ ló ni họ́ù-họ́ù Èmí ló ní ọ́, Àbẹ̀kẹ́-Ọ̀kín mi.
Nípa Òǹkọ̀wé:
Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó,ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá.
Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ tí love and culture, painting by Aurthor-Richard Iheanacho image: https://images.app.goo.gl/rPDqtyx73gQn2oui9